Nitori agunbaniro to ku, Saraki ṣabẹwo si ipagọ wọn ni Kwara

Spread the love

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ti ṣabẹwo ibanikẹdun si ipagọ awọn agunbanirọ nipinlẹ Kwara, o si ba wọn ṣedaro iku Hilda, ọkan ninu awọn akẹkọọ-jade to padanu ẹmi rẹ.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii ni Saraki yọju si ipagọ naa. Lasiko abẹwo ọhun, o ṣapejuwe awọn ọdọ Naijiria gẹgẹ bii akinkanju, o ni ipa pataki ni wọn n ko lori idagbasoke Naijiria.
O pe akiyesi wọn si idi to fi ṣe pataki ki ijọba mojuto ẹka ilera nipagọ agunbanirọ kọọkan lorileede yii, ki wọn si pese awọn ohun to yẹ fun wọn, ki wọn baa le doola ọpọ ẹmi wọn lasiko ti wahala ba wa nipagọ wọn. Lẹyin eyi loun ati akekoo-jade naa duro iṣẹju kan ni idaro Hilda, ọkan ninu wọn to ku.
Omidan Hilda Eva Amadi lo ku lasiko ti awọn oṣiṣẹ ‘Man O war’ n pe iṣẹ fun wọn ni ipagọ yii. Ori okun ti wọn ti n peṣẹ fun wọn ni wọn lo ti re bọ.
Fasiti ilu Portharcourt la gbọ pe Amadi ti kẹkọọ gboye ninu imọ epo rọbi (Oil and Gas). ALAROYE gbọ pe ko si nnkan to ṣe ọmọbinrin naa titi di asiko to fi lọọ sinruulu ni ipagọ awọn agunbanirọ to wa ni Yikpata, nijọba ibilẹ Edu, nipinlẹ Kwara.
Niṣe ni wọn lo re bọ lori okun ti awọn oṣiṣẹ ‘Man O War’ fi n peṣẹ fun wọn nipagọ naa. Wọn ni bi Amadi ṣe ṣubu lo farapa, eyi to si fa a ti wọn fi gbe e digbadigba lọ si ọsibitu, ṣugbọn ibẹ lo pada dakẹ si.

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.