Nitori afikun owo ileewe won, awọn akẹkọọ ti sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ pa.

Spread the love

Fun bii wakati mẹrin gbako lawọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni sẹkiteriati ijọba naa ko fi le wọle taabi jade kuro nibẹ pẹlu bi awọn akẹkọọ ileewe giga gbogbo to jẹ tijọba ipinlẹ naa ṣe ti ilẹkun gbogbo to wọle si sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ pa l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja.
Igbesẹ ọhun ko ṣẹyin ifẹhonuhan ti wọn ṣe lati tako afikun ti awọn alaṣẹ ileewe fasiti LAUTECH to jẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun pinnu lati mu ba owo ileewe naa. Bẹẹ ni wọn n binu nitori pe ijọba ti awọn ile ẹkọ giga to jẹ tiẹ pa.
Awọn akẹkọọ ọhun ti wọn to aadọjọ (150) niye ni wọn wa lati awọn ile ẹkọ to jẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si gbe paali ti wọn kọ oriṣiiriṣii ọrọ ti wọn fi sọko eebu si ijọba ati Gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnitọ Abiọla Ajimọbi, lọwọ, ti wọn si fi pupọ ninu awọn iwe naa ha irin abawọle sẹkiteriati ijọba ipinlẹ naa. Lati ileewe fasiti imọ ẹrọ (LAUTECH) to wa niluu Ogbomọṣọ, Ileewe gbogboniṣe ipinlẹ Ọyọ to wa ni Ṣaki, Ibarapa Polytechnic, niluu Eruwa, atawọn ileewe giga mi-in to jẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ lawọn akẹkọọ to fẹhonu han naa ti wa.
Wọn ko gba ọkọ atawọn ohun irinsẹ yooku laaye lati wọle tabi jade kuro ninu sẹkitẹriati pẹlu bi wọn ṣe gbakoso abawọle nla ọhun, ti wọn si ti i pa gbọin gbọin.
Akitiyan awọn agbofinro lati pa wọn lẹnu mọ ko seso rere nitori awọn ọmọ wọnyi ko bẹru ọlọpaa rara, wọn ni bi wọn ba le mu awọn, ki wọn mu awọn sọ satimọle, ti wọn si n kọrin bu awọn agbofinro paapaa. Nigba ti ọrọ naa toju su awọn ọlọpaa ni wọn sinmi agbaja, ti wọn si n fi awọn olufẹhonuhan yii ṣeran wo.
Bẹẹ ni wọn n kọ oriṣii orin ọtẹ bu Gomina Ajimọbi ati ijọba rẹ, wọn loun lo ba eto ẹkọ ipinlẹ naa jẹ pẹlu bo ṣe sọ eto ẹkọ giga di ọwọngogo, to si tun maa n ti awọn ileewe naa pa bo ba ṣe wu u.
Bii mẹta ninu awọn oludamọran fun gomina ipinlẹ naa lo yọju si awọn olufẹhonuhan yii lati pẹtu si wọn ninu, ṣugbọn ti wọn ko gba, wọn ni gomina funra ẹ lawọn fẹẹ ri, orin ọtẹ ni wọn si fi le awọn aṣoju ijọba naa pada si ọfiisi kaluku wọn.
Nigba to n sọrọ lorukọ awọn akẹkọọ yooku, Alaga ẹgbẹ awọn akẹkọọ nilẹ yii, Moronkọla Teslim, bu ẹnu atẹ lu ọwọ yẹpẹrẹ ti ijọba fi mu eto ẹkọ, eyi to fa a ti meji ninu awọn ileewe giga ijọba ipinlẹ naa fi wa lẹnu iyanṣẹlodi bayii nitori bi ijọba ko ṣe tọju wọn gẹgẹ bo ṣe yẹ, ati pe o ti su awọn akẹkọọ ileewe ti ọrọ yii kan lati maa jokoo sile.
Oludamọran fun ijọba Gomina Ajimọbi lori eto ẹkọ, Ọmọwe Bisi Akin-Alabi rọ awọn olufẹhonuhan yii lati yan awọn aṣoju bii meloo kan laarin ara wọn ti yoo lọọ ṣepade pẹlu gomina lọfiisi, ṣugbọn awọn akẹkọọ tinu n bi wọnyi yari, wọn ni gomina funra ẹ lawọn fẹẹ ri.
Nigba ti wọn ko ri gomina lẹyin bii wakati mẹrin ti wọn ti jokoo pa sibẹ ni wọn kuro nibẹ. Ṣugbọn ki wọn too lọ, wọn fi ohùn silẹ, wọn ni awọn n lọ pẹlu ireti pe ijọba yoo da awọn olukọ to wa lẹnu iyanṣẹlodi lohun, ti eto ẹkọ yoo si bẹrẹ pada nibẹ, ati pe ẹdinwo yoo ba owo ileewe fasiti LAUTECH ti wọn ti sọ di ọwọngogo si iye ti wọn ti n san tẹlẹ. Ṣugbọn bi ijọba ko ba ṣe iwọnyi laarin ọsẹ kan, ohun ti awọn yoo ba wọn fa ko ni i mọ ni kekere, nitori nigba ti awọn ba pada wa, dipo ti awọn fi jokoo si ẹnu ọna sẹkiteriati yii, niṣe lawọn yoo kuku wọnu ile lọ, ti awọn yoo si gbakoso ibujokoo ijọba Ọyọ pata.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.