N’Ipetumodu, Azeez kọju ija sọlọpaa, lo ba foju bale-ẹjọ

Spread the love

Ọmọ ogun ọdun kan, Rasaki Azeez, lo ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo lọsẹ to kọja lori ẹsun pe o ba awọn agbofinro ja.

 

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, la gbọ pe Azeez gbena woju awọn ọlọpaa ti wọn wa lẹnu iṣẹ wọn lagbegbe Saw Mill, niluu Ipetumodu.

 

Nnkan bii aago mẹwaa aarọ kọja diẹ lọjọ naa ni Azeez da wahala silẹ, to si yari mọ Inspẹkitọ Saladin Ayọdeji, Sajẹnti Irewọle Jimoh, Kọpura Ogundare Aliyu ati Kọpura Oguntayọ Joseph lọwọ.

 

Agbefọba to n ṣiṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Azeez, Irewọle Jimoh, ṣalaye funle-ẹjọ pe ọrọ naa le lọjọ yii debii pe Azeez ba aago ti Kọpura Oguntayọ Joseph de sọwọ jẹ.

 

Ẹsun marun-un ọtọọtọ ni wọn ka si olujẹjọ lẹsẹ, lara rẹ si ni dida omi alaafia agbegbe ru, didoju ija kọ awọn eeyan, mimọ-ọn-mọ ba nnkan jẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, Azeez si sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.

 

Irewọle sọ pe awọn ẹsun naa lodi si abala ọtalelọọọdunrun o din mẹrin (356), bẹẹ ni wọn si nijiya labẹ abala ọtalelugba o din mọkanla (246), ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.

 

Ninu idajọ rẹ, Adajọ Majisreeti naa, A. Sanomi, faaye beeli silẹ fun Azeez pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati oniduuro meji ni iye kan naa.

 

O ni awọn oniduuro naa gbọdọ ni ilẹ (landed property), ki wọn si ko iwe ilẹ naa wa sile-ẹjọ fun akọsilẹ to muna doko.

 

Lẹyin naa lo sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu kin-in-ni ọdun yii.

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.