Ninu oṣu karun-un, 1964, Nnamdi Azikiwe ṣekilọ, o ni, “Awọn oloṣelu ni yoo ba Naijiria yii jẹ!”

Spread the love

Nigba ti awọn ọmọde ba n gegi nigbo, awọn agbaagba ti wọn ba wa nitosi ni wọn mọ ibi ti igi naa yoo wo si, nitori wọn yoo ti ri ohun ti awọn ọmọde ti wọn n gegi naa ko ri rara. Bo ṣe ṣẹlẹ lọdun 1964 niyi o, nigba ti ọrọ oṣelu orilẹ-ede Naijiria bẹrẹ si i mi dugbẹdugbẹ, ti awọn oloṣelu igba naa ko si ṣe bii ẹni pe awọn ri i, tabi ti wọn n ro pe ko si ohun kan ti yoo ṣẹlẹ, pe ohun ti awọn ba ṣe, aṣegbe ni. Nigba naa ni ẹni to jẹ bii olori ilu funra rẹ, Dokita Nnamdi Azikiwe, jade, o jade lai fi ọrọ si abẹ ahọn sọ, o si sọ ọ si eti gbogbo eeyan pe, “Mo ri ajalu aburu to fẹẹ ja sori Naijiria o; ẹ tete, ẹ ma jẹ ko ja lu wa lori o, nitori bo ba ja, nnkan yoo bajẹ kọja atunṣe!” Bẹẹ ni Azikiwe wi lọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun naa, ti gbogbo awọn iwe iroyin si gbe e jade lọjọ keje, ti gbogbo ọlọgbọn si n ronu lori ọrọ ti olori ilẹ Naijiria naa sọ.

Bo ba ṣe pe ipo alagbara kan ni Azikiwe wa ni, o daju pe awọn aṣẹ kan ni yoo pa, aṣẹ naa yoo si le debii pe ko ni i si ẹni ti yoo le da a kọja ninu gbogbo awọn ti wọn n ṣejọba naa. Ṣugbọn ipo ti Azikiwe wa, ipo oludamọran lasan ni. Ẹni ti yoo kan fun ijọba nimọran ni, ko le paṣẹ, bo tilẹ jẹ pe oun ni wọn n pe ni olori ilu, Purẹsidẹnti. Lara eto ijọba ti wọn ṣe nigba naa niyẹn, pe ẹni kan yoo wa ti yoo maa jẹ Purẹsidẹnti, oun ni yoo jẹ bii ẹni to rọpo ọba ilu oyinbo, ti yoo si jẹ oun lo ni orilẹ-ede rẹ, ṣugbọn to jẹ pe o ti gbe agbara ijọba ilẹ naa fun awọn oloṣelu. Nidii eyi, ko le paṣẹ kankan, bi awọn oloṣelu ba ṣe fẹ ni wọn yoo ṣe ijọba naa, amọran nikan lo le fun wọn. Olori oloṣelu yii, to si jẹ alagbara ju, to jẹ oun gan-an lo n ṣejọba ni wọn n pe ni Prime Minister, Tafawa Balewa lo si di ipo yii mu nigba naa.

Ṣugbọn ibi ti wahala ti wa ni pe Tafawa Balewa yii naa, o ni awọn nnkan to le ṣe, nitori oun kọ ni olori ẹgbẹ oṣelu to gbe e de ipo to wa yii. Olori ẹgbẹ oṣelu rẹ ni Sardauna ilẹ Sokoto, Ahmadu Bello, oun gan-an la si le sọ pe o n paṣẹ ijọba Naijiria, nitori ohun yoowu to ba wi fun Balewa ni Balewa yoo ṣe, aṣẹ to ba si pa fun un ni yoo tẹle, nitori bi ko ba ṣe ohun to fẹ ko ṣe, ẹgbẹ oṣelu rẹ yoo yọ ọ kuro nipo igbakeji olori ẹgbẹ wọn, ati aṣoju wọn, ti wọn ba si ti yọ ọ bẹẹ, ko ni i le ṣe olori Naijiria mọ, nitori gbogbo ipo to ba di mu yoo bọ lọwọ rẹ lẹsẹkẹsẹ ni. Eyi lo fa a to fi jẹ pe Sardauna lo lagbara ju ni Naijiria, niṣe lo da bii igba to kan fi Balewa di gẹrẹwu lasan. Ṣugbọn ọkunrin naa n ṣi agbara yii lo, oun pẹlu awọn ti wọn ba sun mọ ọn, aṣilo agbara yii naa lo si fẹẹ da wahala silẹ, nitori lasiko naa, bii igba pe ilẹ Naijiria ko fara rọ ni.

Lasiko ti Azikiwe sọrọ yii, nnkan mẹta lo n daamu Naijiria, ọrọ naa si ti da nnkan silẹ rẹpẹtẹ. Akọkọ ni ti eto ikaniyan ti wọn ṣe lọ, iyẹn sẹnsọ (Census). Ọrọ naa ti da ija olori ijọba ilẹ Ibo (East), Michael Okpara, ati gbogbo awọn eeyan nla nla ti wọn jẹ ọmọ Ibo silẹ. Ohun to si jẹ ki ọrọ naa le ni pe ẹgbẹ oṣelu awọn Hausa ti Sardauna jẹ olori rẹ, iyẹn NPC ati ẹgbẹ NCNC ti Okpara jẹ olori rẹ ni wọn jọ n ṣejọba Naijiria, awọn mejeeji lo si yẹ ki wọn jọ maa paṣẹ ohun ti yoo ṣẹlẹ laarin ara wọn, ati ọna ti wọn yoo gba lati maa ṣejọba Naijiria nigba naa. Ṣugbọn ọrọ yii ko ri bẹẹ, awọn mejeeji ni wọn n ba ara wọn ja ija gidi. Ohun to si fa ija naa ni pe Sardauna ko ṣe bii ẹni pe ẹgbẹ oṣelu meji lo n ṣejọba, oun n ṣe bii ẹni pe ẹgbẹ tiẹ nikan lo n ṣejọba, nigba to jẹ ninu ẹgbẹ rẹ ni Tafawa Balewa to jẹ aarẹ Naijiria ti jade.

Yatọ si iyẹn, awọn ipo to ṣe pataki, paapaa ipo olori awọn ologun ati tawọn ọlọpaa, awọn eeyan Sardauna lẹ o ri i ninu wọn, ọmọ ẹyin rẹ lo fi ṣe minista fun Eko, iyẹn ni pe ikawọ rẹ ni Eko paapaa wa, ohun yoowu to ba fẹẹ ṣe ni yoo ṣe, nitori ofin sọ pe ile ijọba apapọ ni Eko, nigba to jẹ olu ilu Naijiria ni. Ṣugbọn pẹlu eleyii, Sardauna ṣi n fẹ ki awọn eeyan rẹ ni agbara, ki wọn si ni ipo to tubọ ju eyi ti wọn ni lọ. Yatọ si pe wọn ti gba ẹgbẹ NCNC ti wọn jọ n ṣe aṣepọ ijọba yii danu, Sardauna fẹ ko jẹ ti wọn ba ti n ka awọn ọmọ Naijiria, wọn yoo maa sọ pe idaji gbogbo Naijiria lawọn Hausa nikan i ṣe, ati pe wọn ju apapọ Ibo ati Yoruba lọ. Eleyii mu eru gidi waye lasiko ti wọn ṣe sẹnsọ yii, nitori nigba ti wọn kọkọ ṣe sẹnsọ lakọọkọ ti ilẹ Ibo ati Yoruba pọ ju awọn Hausa lọ, Sardauna ni awọn ko gba esi sẹnsọ naa.

O mura lati sọ ọrọ naa dija nla, nitori o ni bo ba le di ogun ko dogun, awọn ti ṣetan lati ja a bii ogun ni. Afi igba ti wọn tun sẹnsọ naa ṣe o, nigba ti wọn si ṣe e tan, awọn Hausa ni wọn sọ pe wọn pọ ju apapọ Yoruba ati Ibo lọ. Eleyii lo bi Ibo bii Okpara ninu, o si bi ọpọ awọn ọmọ Ibo naa ninu, wọn lawọn ko ni i gba rara. Ni ti Yoruba, ki Ọbafẹmi Awolọwọ to jẹ olori ẹgbẹ Ọlọpẹ too lọ sẹwọn ni wọn ti kọkọ ṣe sẹnsọ akọkọ ti wọn fi sọ pe Yoruba ati Ibo pọ ju Hausa lọ, ori ọrọ naa lo si duro le, o sọ fawọn eeyan rẹ pe wọn ko gbọdọ gba laelae ki awọn aṣaaju Hausa yi esi ikaniyan naa pada, ohun to ba gba ni ki wọn jọ fun un. Ladoke Akintọla to jẹ olori ijọba naa gba si i lẹnu nigba naa, ṣugbọn lẹyin ti ija de laarin wọn, to si sa lọ sẹyin Sardauna, ohun ti Sardauna kọkọ gba lọwọ rẹ lọrọ sẹnsọ yii, Akintọla bẹrẹ si i sọ pe esi sẹnsọ naa dara.

Ohun to waa mu ọrọ naa fọ loju ni pe Akintọla yii ati awọn ẹgbẹ NCNC naa ni wọn jọ n ṣejọba ilẹ Yoruba, nitori nigba ti Akintọla ri i pe awọn ọmọ ẹgbẹ Ọlọpẹ ti wọn jẹ ọmọlẹyin Awolọwọ yoo fi ibo didi le oun danu, wọn yoo si yọ oun nipo ti awọn ba lọ si ile-igbimọ, awọn NCNC lo lọọ sa ba pe ki wọn gba oun, awọn naa si duro ti i, wọn si jọ fi ibo gbe e wọle, o si di olori ijọba. Nitori adehun aarin wọn yii ni wọn ṣe fi Fani-Kayọde ṣe igbakeji, nigba to jẹ NCNC loun. Iyẹn naa lo jẹ ki wọn fi Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi ṣe gomina West, nitori ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ naa loun paapaa. Amọ nigba ti Akintọla ri i pe oore to wa lọdọ Sardauna ju eyi ti oun yoo ri lọdọ awọn Okpara ati NCNC lọ, o ja wọn si kolombo, wọn si fọ ẹgbẹ wọn si wẹwẹ ni West, ẹgbẹ naa ku toritori. Oun ati Fani-Kayọde da ẹgbẹ tiwọn silẹ, wọn pe e ni Dẹmọ.

Eleyii naa tun sọ Akintọla ati Okpara di ọta ara wọn, nitori Okpara koriira Akintọla de gongo. O ni oun tilẹ le foriji Sardauna nigba to ṣe pe oun n ja fun awọn eeyan tirẹ ni, ṣugbọn oun ko le mọ idi ti Akintọla ṣe n ta awọn eeyan tirẹ fun awọn iran mi-in nitori oṣelu, o ni iyẹn loun ko ṣe le ba a ṣe. Bo tilẹ jẹ pe awọn kan sọ pe irọ ni Okpara n pa, nitori pe Akintọla kọyin si i lo ṣe n sọ bẹẹ, tabi ko mọ pe awọn eeyan rẹ lo n ta nigba to fi duro ti i ti wọn fi jọ fọ ẹgbẹ Ọlọpẹ, ti wọn si fọwọ si i ki wọn sọ Awolọwọ sẹwọn, sibẹ awọn mi-in ni ọrọ ti ọkunrin naa sọ to apero, o kan jẹ ko si ohun ti wọn le ṣe ni. Nitori pe ọrọ naa ti waa fọ pẹkẹpẹkẹ, ti Okpara loun ko gba, to si ti gba ile-ẹjọ lọ, ti Sardauna ni ko si ohun to le ṣe, to ba dan idankudan-an kan wo, awọn yoo gbe e, eleyii ko mu ọkan ilu balẹ rara.

Ni ti Akintọla funra rẹ, agbara to ṣẹṣẹ ri gba lati ọdọ Sardauna n pa oun naa bii ọti ni, eyi si ni nnkan keji to n fa wahala nigba naa. Akintọla ti di ajagbe-mọ-mẹmba, iyẹn ni pe gbogbo awọn oloṣelu Western Region ti ko ba ti ṣe tirẹ, wọn yoo mọ bi wọn yoo ṣe ṣe akoba fun un tabi ki wọn gba gbogbo ohun to ni lọwọ rẹ, kinni naa si ti n mu inira ba awọn eeyan. Ṣugbọn nitori pe o ti fi Sardauna lọkan balẹ, iyẹn naa si ti ri ara rẹ bii alagbara nla to fi ọmọọṣẹ rẹ si ilẹ Yoruba, ko si ohun ti Akintọla ṣe ti wọn yoo yẹ ẹ lọwọ wo. Pẹlu gbogbo bi wọn ti n lo agbara to yii ṣaa, awọn eeyan ti wọn jẹ pa-mi-n-ku ko tori rẹ bọ sinu ẹgbẹ oṣelu rẹ, bẹẹ ni wọn ko si tori rẹ gbọran si i lẹnu, kaka bẹẹ, bi wọn yoo ti da nnkan rẹ ru ni wọn n wa, lojoojumọ si ni wọn n ba orukọ rẹ jẹ si i. Ki i ṣe laarin awọn Yoruba nikan paapaa, kari Naijiria ni.

Ọna kẹta ti wahala fi wa ni pe ibo n bọ, ọjọ idibo mi-in ti sun mọle. Wọn fẹẹ dibo lati yan awọn aṣoju-ṣofin apapọ. Ibo naa ni wọn yoo fi gbe Balewa wọle lẹẹkeji to ba jẹ wọn fẹ ẹ, bi wọn ko ba si fẹ ẹ, ti wọn yoo le fi ibo gbe ẹlomiiran wọle. Ṣe bi wọn ti n ṣeto idibo igba naa ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba ni ọmọ ile-igbimọ aṣofin apapọ to ba pọ julọ ni yoo fa olori ijọba kalẹ, awọn ni wọn yoo yan Prime Minister, ẹni ti yoo maa ṣejọba lọ. O ti han si Sardauna yii pe ko si ohun to le ṣe, ẹgbẹ NCNC ko ni i ba wọn ṣejọba lẹẹkeji mọ. Bẹẹ ni Sardauna mọ pe koda ki awọn wọle ni ilẹ Hausa, ki awọn ko gbogbo awọn aṣofin to wa nibẹ, oun ko ni i le ṣejọba afi ti awọn ba ri ẹgbẹ oṣelu kan fara mọ nilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo, ti ẹgbẹ oṣelu naa yoo si ni awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin to pọ diẹ ti awọn yoo fi kun tawọn.

Ohun to ṣe mu Akintọla lọrẹẹ ree, to si n ṣe atilẹyin fun un. O fẹ ki ẹgbẹ toun ati ti Akintọla yii jọ maa ṣe ajọṣe, bi awọn ba ti le mu ibo ilẹ Hausa, ti awọn Akintọla naa mu ibo ilẹ Yoruba, o ti pari, ko si ohun ti yoo di ijọba rẹ lọwọ, wọn yoo maa ṣe kinni naa lọ titi di igba ti wọn ba fẹ ni. Ṣugbọn awọn ọmọ Awolọwọ ko fi ọkan Akintọla balẹ nilẹ Yoruba, ko si jọ pe wọn yoo wọle lasiko ti ibo yii ba de, nitori awọn naa mọ pe ti a ba ti yọwọ eru kuro, awọn mẹkunnu ilu ko fẹran ẹgbẹ Dẹmọ. Awọn ọmọlẹyin Awolọwọ ti ba orukọ wọn jẹ jinna, awọn araalu funra wọn ko si fẹran Akintọla, tabi Fani-Kayọde. Ohun to jẹ ki wọn maa gbe awọn oloṣelu tabi awọn oniroyin nigba mi-in ree, nitori wọn ṣi n wa ọpọ awọn alagbara laarin ilu si i ninu ẹgbẹ wọn. Ọrọ yii n fa rogbodiyan gan-an ni, ko si sohun ti ko le da, o le koba ijọba dẹmokiresi ti wọn n ṣe.

Nigba ti ibo waa n bọ yii, ti ọrọ ija sẹnsọ yii ko yanju, ti ikunsinu wa laarin Okpara ati Sardauna, ti ikoriira gidi si wa laarin Akintọla ati Okpara, ko jọ pe aarẹ Naijiria le bọ ninu rogbodiyan ti yoo ṣẹlẹ, bi ija awọn olori mẹtẹẹta yii ba le ju bẹẹ lọ. O tun gbebẹ, asiko ti wọn n ṣe gbogbo eleyii naa ni idajọ n lọ lọwọ lori ẹjọ kotẹmilọrun ti Awolọwọ pe, iyẹn lẹyin ti wọn ti dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa fun un. Awọn araalu ti ko ọkan soke, wọn n fi ọkan ba ẹjọ naa lọ lojoojumọ. Loootọ awọn lọọya oyinbo wa, atawọn lọọya nla ni Naijiria, ṣugbọn awọn ti wọn mọ nipa eto ijọba mọ pe bi wọn ju abẹbẹ soke nigba aimoye, ibi pẹlẹbẹ ni yoo maa fi lelẹ. Awọn yii mọ pe ko si iru ẹjọ ti Awolọwọ le ro ti wọn yoo tori rẹ da a silẹ, nitori awọn Sardauna ti ṣe iwe rẹ pa pe ohun to le mu alaafia ba Naijiria ni ki Awolọwọ wa lẹwọn.

Akintọla ati awọn eeyan tirẹ naa ti fọwọ si eleyii, ṣe awọn naa mọ pe bi Awolọwọ ba le pada siluu, ko si bi awọn yoo ṣe wọle lasiko ibo to n kanlẹkun, oun naa si ti sọ fun Sardauna pe ti awọn ba fẹẹ ri ibo kankan mu nilẹ Yoruba o, afi ki Awolọwọ wa lẹwọn ti awọn yoo fi yanju ọrọ naa. Loootọ lọrọ naa dara loju awọn oloṣelu wọnyi, awọn kan wa ninu wọn ti wọn n ro o ni arojinlẹ pe ọrọ to n lọ naa le da wahala silẹ, ati pe bi ko ba da a silẹ lẹsẹkẹsẹ bi wọn ti n ṣe e naa, yoo pada da a silẹ lẹyin ọla kan ni. Awọn yii mọ pe giragira ti Sardauna n ṣe yii, to fẹẹ fi ipa gba ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo, nipa sisọ ara rẹ di olori ijọba apapọ nigba ti ki i ṣe bẹẹ, yoo pada mu aburu dani, yoo si ko iṣoro ti awọn eeyan naa ko ni i gbagbe sọrun wọn. Iru awọn eeyan bayii ni aarẹ Naijiria yii, iyẹn Azikiwe. Ko sẹni to gbọrọ rẹ ti ko kora duro sii nigba to pariwo.

Azikiwe sọrọ bayii pe, Ojue mi ni gg bii aar oril-ede yii lati sr, nitori bi n ko ba sr, emi naa aa da bii bayej, nitori mo rohun to n lọ, n ko wi nnkan kan. Ohun to n l nil yii bayii ko dara o, mo si foju ara mi ri i. Bi awn aaaju il yii e n ba ara wn ja, ti wn n fi ojoojum tut si ara wn loju yii, ati bi awn ti wn j n ejba naa ti n r ara wn j, ti wn n fgbn w gba nnkan oni-nnkan lw r, ti wn si n fi lpaa ati ṣọja hal m awn ti wn ba fẹẹ gbo wn lnu, ohun ti yoo fa wahala gidi fun wa ni, iyẹn ni mo e n sr bayii pe mo ri aburu to n fi dugbdugb lori Naijiria, ka j tete le aburu naa kuro lori wa. O dun mi pe ipo ti mo wa ko ṣe oelu, nitori baba gbogbo moril-ede yii ni mi. Bo ba j mo le da si r oṣelu ni, mo m bi n ba e da si i. ugbn sib naa, mo n kil fawn oloṣelu yii ki wọn e jj, wahala n b o.

Ohun ti ofin oril-ede yii s ni pe gbogbo wa ni a oo wa ni iṣọkan, ti a oo si j maae lati mu iduroinin ati idagbasoke ba il wa. Bẹẹ lofin wi, ofin ti awọn ti wn n e oṣelu si bura le lori ree. Ṣugbọn ohun ti awn eeyan yii n e lnu j meloo kan syin ko j pe wn ranti ofin yii m, ko til j pe wn fẹẹ mu un lo rara, wn ko f iṣọkan wa pẹẹpẹẹ. Iwa ti wn n hu yii ti mu ki awn ti wn f daadaa fun Naijiria br si i ronu pe nj nnkan ko ni i daru bayii lai ti i debi kan. Abi j wo ni oyinbo gbe ijọba fun wa pe ki a maa e e funra wa ti a si ti da bayii laarin ara wa. r ti awn oloṣelu til n s lnu ko dara rara, bii igba pe wn fẹẹ mn-m ba oril-ede yii j ni. Mo f ki wn m a o, pe ko si ere kan ti wn yoo ri gba ninu ki orilede yii f m gbogbo wa lori. Bẹẹ o fẹẹ f o, oril-ede yii fẹẹ f o, ki awn oloṣelu il yii rra!

Bẹẹ ni Nnamdi Azikiwe, aarẹ Naijiria wi, to si pariwo sita. Ohun to jẹ ko pariwo bẹẹ ni pe ipade awọn olori ijọba West, East, North ati Mid-West fẹẹ waye l’Ekoo, o si ni oun fẹ ki wọn lo akoko naa lati ronu ara wọn wo, ki wọn si jọ jiroro lori ohun ti yoo tubọ mu wa wa niṣọkan, ko ma jẹ lori ohun ti yoo mu iyapa ati idarudapọ ba wa. Awọn olowe paapaa mọ owe naa, ṣugbọn ko jọ pe wọn ṣetan lati dahun tabi lati ronu, loju tiwọn, wọn ni Azikiwe n sọ tẹnu rẹ ni, ko si ewu kankan nibi kan, ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ, ohun to le fa wahala ni ki awọn kan ni ki ẹgbẹ NPC ma ṣejọba Naijiria mọ, tabi ki awọn kan maa ba awọn ti wọn ba fẹran awọn ni ilẹ Yoruba tabi ilẹ Ibo ja, ohun to le mu wahala wa niyẹn.

Bẹẹ awọn ti wọn ri oye ọrọ mọ pe wahala n bọ, koda, awọn oloṣelu funra wọn mọ. Awọn ti wọn ba n Balewa ṣe mọ pe inu ọkunrin naa ko dun si gbogbo ohun ti Sardauna n ṣe, ati ọna to n gba gbe ijọba rẹ gba, bẹẹ ni ko si fẹ ọrẹ ojiji ti ọga oun naa n ba Akintọla ṣe. Ṣugbọn nnkan ti kọja gbogbo ibi ti oun ro o si, nitori o jọ pe orin ibi to ba fẹẹ ja si ko ja si lawọn oloṣelu to ku n kọ. Ibo to n bọ yii ni yoo fi oju ọrọ gbogbo han, nitori ẹ naa si ni kaluku ṣe mura si i. Ati Sardauna o, ati Balewa funra rẹ, ati Akintọla ni o, abi Okpara, ati iyawo Awolọwọ, ibo ti wọn fẹẹ di yii ni kaluku fọkan si, wọn ni ibo naa ni yoo sọ boya Naijiria yoo wa ni o, abi boya Naijiria yoo parẹ lori ilẹ, ti kaluku yoo si fọnkan sibi to ba ri.

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.