Ninu oṣelu APC, olowo lalagbara

Spread the love

Beeyan ba lowo gidi lọwọ, to si wa ninu ẹgbẹ APC, yoo lagbara gidi. Bo ba si ti waa lagbara yii tan o, ko si ara ti ko le da, ko si ohun ti ko le ṣe, aṣegbe si ni pẹlu. O kan jẹ pe ninu ẹgbẹ naa, agbara ju agbara lọ. Oshiomhole, alaga ẹgbẹ naa n kuru, o n ga, o n fo soke bii ẹni ti wọn rọ ina si lara, nitori ohun to sọ pe Gomina Ibikunle Amosun ṣe. O ni ki i ṣe ibo ti awọn eeyan oun jẹrii si ni Amosun gbe jade, ohun to si fa wahala niyẹn. Ṣugbọn ọkunrin yii mọ pe ko si oṣiṣẹ tabi ọmọ igbimọ awọn kan to jẹrii si ibo ti wọn di l’Ekoo, ati pe olu ileeṣẹ ẹgbẹ wọn naa ti jade to sọ pe awọn ko ti i dibo l’Ekoo, bi awọn ba dibo, gbogbo aye yoo mọ. Ṣugbọn lẹyin ọjọ keji, kia ni wọn ko ọrọ naa jẹ, wọn ni awọn ti ṣeto ibo, ibo ti wọn si mu wa lati Eko lo dara julọ. O ṣee ṣe ki ibo ti wọn di ni Eko daa loootọ, ṣugbọn kọkọrọ kan to ba eyin aja jẹ nibẹ ni pe ko si awọn oṣiṣẹ olu ileeṣẹ ẹgbẹ APC, tabi igbimọ ti wọn yan lati ṣeto idibo naa nibẹ, kinni naa ko ṣoju wọn. Gẹgẹ bi ofin ẹgbẹ wọn si ti sọ, bi ibo kan ko ba ti ṣoju wọn, wọn ko ni i gba ibo naa wọle. Iyẹn ni wọn o ṣe gba ibo yii wọle lakọọkọ, ko too di pe wọn tun sare yipada nigba ti agbara ju agbara lọ, ti wọn si n sọ pe ibo Eko daa, awọn si ti gba a wọle. Nitori pe wọn gba a wọle yii ni awọn gomina to ku ṣe bẹrẹ wahala, ti wọn si n sọ pe ofin ti Oshiomhole lo fun Tinubu l’Ekoo, ko waa lo iru rẹ naa lọdọ tawọn. Ṣugbọn Oshiomhole kọ, o ni oun ko le ṣe ohun ti wọn ni ki oun ṣe. Ninu ẹgbẹ ti wọn ba ti n lo ofin meji, ti wọn n lo ọkan fun awọn olowo, ti wọn n lo ọkan fun awọn mẹkunnu tabi awọn ti ko lowo, iru ẹgbẹ bẹẹ ki i toro, koda ko jẹ orilẹ-ede, wahala ti yoo maa ṣẹlẹ nibẹ niyi. Ohun to n ba wọn ja ninu APC ree, iyẹn naa lo si n ba wa ja ni Naijiria, ki Oluwa gbe wa bori awọn ẹlẹnu-meji bii ọbẹ ni.

(15)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.