“Ninu firisa ni mo sa si lọjọ ti wọn dana sun ile Fẹla, nibẹ ni ṣọja kan ti la igo ṣinaapu mọ mi lori” Laide, ọkan ninu awọn ọmọ Fẹla, lo sọ bẹẹ

Spread the love

Fẹla ati aburo rẹ, Dokita Beko Ransome Kuti, pẹlu iya wọn, Arabinrin Funmilayọ Ransome Kuti, ti mura lati ba ijọba awọn Oluṣẹgun Ọbasanjọ fa kuraaku ti ko ni i tan nilẹ titi aye nitori ti wọn dana sun ile wọn. Ile nikan kọ ni wọn dana sun, wọn tun dana sun mọto, bẹẹ ni wọn dana sun irinṣẹ ti Fẹla fi n ṣere kiri, wọn si tun paṣẹ pe ijọba ologun ti gba ile naa kuro lọwọ wọn, wọn ko gbọdọ debẹ mọ. Ohun to gbe Fẹla de ile-ẹjọ niyi, to ni oun yoo gba miliọnu mẹẹẹdọgbọn lọwọ ijọba awọn ṣọja yii, bi wọn gbọn bii Ifa, ti wọn mọran bii Ọpẹlẹ, wọn yoo sanwo naa fawọn dandan. Ẹjọ ti bẹrẹ ni ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 1977, niwaju Adajọ Dosunmu, bo si tilẹ jẹ pe awọn ṣọja ti halẹ mọ awọn ẹlẹrii ti awọn eeyan yii fẹẹ lo, ti wọn sọ pe wọn ko gbọdọ waa jẹrii, sibẹ, nigba ti ẹjọ bẹrẹ, awọn Fẹla sẹẹti awọn ẹlẹrii jọ ni o.

Awọn ti ija tori wọn bẹrẹ ti kọkọ rojọ, Ṣẹgun Demọla ti wọn n pe ni Ṣẹgun Alagbara ati Ṣẹgun Adams ti ṣalaye ohun to fa ija laarin awọn ati awọn ṣọja yii, pe ọrọ pileeti-nọmba lasan ti wọn ni awọn ko de daadaa lo pada waa di ogun yii. Bakan naa ni ọkunrin to n ranṣọ fun Fẹla, Lamidi Alade Ojo, ti sọ tẹnu ẹ, to ni loju oun bayii lawọn ṣọja naa ṣe bẹrẹ si i sọ ina sile Fẹla, oun si ri oun ko ri, oun ri mọto bii mẹrin ti wọn dana sun lau lẹẹkan naa, bẹẹ ni oun si gbọ nigba ti awọn ṣọja n sọ laarin ara wọn pe ‘Tode na tode’, ti wọn ni awọn yoo ri i pe Fẹla jo ijo Zombie fawọn ni baraaki awọn. Ọrọ tawọn ẹlẹrii mejeeji sọ bi ẹjọ ti bẹrẹ yii jẹ kawọn eeyan nigbagbọ pe ko si bi ijọba awọn Ọbasanjọ yoo ti ṣe, wọn ti jẹ gbese, wọn yoo si san gbese naa dandan ni. Nitori eyi, awọn ti wọn wa si kootu lọjọ keji pọ ju awọn ti wọn wa tẹlẹ lọ.

Bi wọn ti de ile-ẹjọ ni ẹjọ tun bẹrẹ, Adajọ Dosumu ko fi akoko ṣofo rara ni. Ẹni akọkọ to jade lati rojọ lọjọ yii ni Iya Fẹla funra rẹ. Awọn eeyan ti mọ pe ara rẹ ko ya, wọn si ti ro pe ko ni i wa si kootu, wọn ro pe yoo fi ohun ranṣẹ, tabi ko kọwe si adajọ ni, ṣugbọn nigba ti wọn ri i to tẹ yẹkẹyẹkẹ dide, gbogbo kootu kun lọ gbunn, akọwe kootu si sare pariwo, “Ọọọdaaa!” Ṣugbọn pẹlu ẹ naa, o pẹ ki ariwo yii too lọ silẹ rara. Ọpọ awọn eeyan ni wọn wa ni kootu to jẹ wọn n gbọ orukọ Iya Fẹla ni, wọn ko mọ ọn, igba akọkọ ti wọn yoo si ri i niyẹn. Ṣe gbogbo aye lo kuku ti gbọ orukọ obinrin naa, ati ijangbọn to ti n ba ijọba oriṣiiriṣii fa lati kekere rẹ wa, awọn eeyan mi-in si ti fun un lorukọ ti ki i ṣe tirẹ rara. Fẹla funra rẹ ti sọ pe “Ọmọ Iya Ajẹ” loun, eyi si ti jẹ ki awọn eeyan maa foju ajẹ tabi anjannu wo obinrin agbalagba yii.

Ohun to fa ariwo rẹpẹtẹ nigba to dide niyẹn, bo si ṣe n rin lọ sinu igi ti yoo ti rojọ lawọn eeyan n wo o lọ, “Ṣe Iya Fẹla niyi!”, ohun to n tẹnu ọpọlọpọ awọn eeyan naa jade niyẹn. Wọn n wo obinrin naa bii ẹni to ri eegun ni, nitori orukọ rẹ ti wọn ti gbọ ati ohun to ti gbe ṣe, ṣe laye igba naa, ko ti i wọpọ ki obinrin maa ṣe iṣẹ ajijagbara, tabi ko maa duro niwaju awọn ọkunrin lati ba wọn fa wahala. Ni Naijiria yii, iya awọn Fẹla lo bẹrẹ iyẹn, oun lo bẹrẹ ariwo pe ko si ohun ti ọkunrin le ṣe ti obinrin naa ko le ṣe, nitori ẹ lo ṣe jẹ oun ni obinrin akọkọ ti yoo wa mọto ni gbogbo Naijiria yii, bẹẹ naa lo si jẹ oun ni obinrin akọkọ ti yoo kọkọ saaju awọn oluwọde ti wọn da rogbodiyan silẹ, ti wọn si le odidi ọba ilu kuro lori oye fun igba diẹ. Ko sobinrin to ṣe iru rẹ ri, afi Iya Fẹla, ohun ti wọn ṣe n wo o niyẹn

.

Adajọ paapaa rẹrin-in muṣẹ nigba ti Iya Fẹla de iwaju rẹ, ṣe oun naa mọ pe obinrin bii ọkunrin ni. Lẹyin ti Akọwe Kootu ti kigbe “Ọọdaa!”, ti ariwo si ti lọ silẹ diẹ, wọn ṣe ibura fun alagbara obinrin yii ko too bẹrẹ ọrọ rẹ ni sisọ. Lẹyin naa ni awọn agbẹjọro doju kọ ọ, wọn si ni ko sọ ohun to mọ nipa iṣẹlẹ to ṣẹlẹ lọjọ kejidinlogun, oṣu keji, ọdun 1977, ni ile rẹ to wa ni ojule kẹrinla, Agege Motor Road, ni Mọṣalaṣi Idi-Oro, ni Muṣin. Nigba naa ni obinrin naa sọrọ, o ni ọjọ buruku ni wọn jẹ koun ranti yii, ọjọ ti ko si bi oun yoo ti ṣe le gbagbe laye oun ni, nitori oun ko ri iru rẹ ri lati ọjọ ti oun ti dele aye. O ni bii igba ti oun wa loju ogun ni gbogbo kinni naa ri, iyatọ to si wa nibẹ ni pe oun ko gbe ibọn dani ni toun, bẹẹ ni oun ko ni ohun ija lọwọ, awọn ti wọn waa kọlu awọn ni wọn mura ogun waa ba awọn.

Iya Fẹla ni ni faranda loun wa, oun n gbatẹgun gẹgẹ bii iṣe oun ni, oun ko si mọ pe nnkan kan n ṣẹlẹ nita. Afi lojiji ti oun ri awọn ṣọja ti wọn bẹrẹ si i sare de, nigba ti oun yoo si fi ṣẹju, wọn ti pọ bii esu. Ohun to waa ya oun lẹnu ni pe wọn ko duro, wọn bẹrẹ si i ju okuta lu ibi ti oun wa ni. Loootọ gbogbo ile ni wọn n ju okuta si, ṣugbọn apa ibi ti oun wa gan-an ni ọpọ awọn okuta naa n balẹ si. Ohun to jẹ ki oun sare wọle niyẹn, ti oun si lọ si yara oun lati maa ba oju windo wo wọn, ki oun le mọ ohun ti wọn fẹ tabi ohun to n ṣẹlẹ gan-an. Ṣugbọn aaye iyẹn naa ko tun si, nitori okuta naa n ba gbogbo ara ile, bii eeyan si yọju loju windo kankan ninu ile naa, wọn yoo fi okuta fọ ọ lori ni. Amọ pẹlu bi oun ti ṣe ti windo yii to, oun ṣi n ri wọn, oun n ri i bi wọn ti n gbiyanju lati gun oke ile naa, wọn fẹẹ wọle.

Iya ni nigba to ya, oun ko le wo wọn mọ, nitori okuta ati igi pẹlu awọn oko ribitiribiti ti wọn n ju n ba gilaasi windo, oun si mọ pe bi ọkan ninu wọn ba fọ gilaasi naa, o ṣee ṣe ko jẹ kongẹ ori oun ni yoo ṣe. Eyi loun ṣe kuku kuro nibẹ ti oun jokoo silẹẹlẹ, nitori ọrọ naa ko ye oun, oun ko si mọ ohun to ṣẹlẹ ti awọn ṣọja fi fẹẹ ba ile awọn jẹ. Igba to ya loun n gbọ ariwo, oun si mọ pe awọn ṣọja naa ti wọle, bẹẹ ni eefin ina gbalẹ kan. O ni nibi ti oun jokoo si naa ni ṣọja naa ti ja ilẹkun wọle, bi wọn si ṣe ri oun ni wọn gbe oun janto, wọn si ju oun lati oju windo, wọn sọ oun silẹ bii apo ẹwa, wọn ko si kọ ki oun ku rara. Iya naa ni wọn tilẹ fẹẹ pa oun ni, nitori nigba ti wọn kọkọ wọle, niṣe ni ọkan ninu awọn ṣọja meji ti wọn wọle naa bẹrẹ si i da bẹntiroolu silẹ, to n da a si gbogbo ilẹ inu yara oun, oun si mọ pe o fẹẹ ṣana si i ni

.

Iya Fẹla ni ẹni keji ẹ ti wọn jọ wọle lo ni ko ma ti i ṣana, ko jẹ ki awọn ju iya yii sita ni. O ni ṣugbọn ṣọja to n tu bẹntiroolu silẹ yẹn ni rara, ki awọn kuku dana sun obinrin naa mọle ni yoo daa ju, ki Iya Fẹla jona mọ inu ile, wọn ni iyẹn lo le jẹ ki ọrọ naa dun Fẹla daadaa. Ṣugbọn ṣọja keji taku, o ni ki wọn ma sun Iya Fẹla mọle, ki wọn jẹ ki awọn ju u sita. Ohun ti iya naa sọ pe o ko oun yọ niyẹn, pe bi ko ba jẹ ṣọja keji to taku mọ ẹni ti wọn jọ wa lọwọ ni, niṣe ni wọn iba sun oun mọ inu ile ọmọ oun. O ni ṣugbọn oun n wo wọn, oun si ri i pe gbogbo awọn goolu oun, ati awọn ohun-ini oun to jẹ olowo iyebiye to wa ninu yara oun nibẹ ni wọn ji ko pata. Iya Fẹla ni nigba ti wọn ju oun lulẹ gbẹẹ bẹẹ, niṣe ni ẹsẹ oun da gbau! Yatọ si ẹsẹ oun to kan yii, gbogbo ara oun lo da wokowoko, oun ko si gbadun lati igba naa.

Iya yii ni gbogbo bi wọn ti n lọ ti wọn n bọ, niṣe ni wọn foun silẹ nibi ti oun ṣubu si, kawọn ọmọọṣẹ Fẹla kan too ri oun ti wọn wọ oun si ẹgbẹ kan ki awọn ṣọja naa ma fi bata tẹ oun pa mọlẹ. Nibẹ ni oun wa titi ti wọn fi ru awọn lọ si baraaki Albati, ti iya tun jẹ awọn nibẹ ko too waa di pe wọn gbe oun lọ si ọsibitu LUTH ni Idi-Araba. O ni ni ọsibitu yii loun wa titi o, nitori ara oun ko ya, bi ọkan ṣe n lọ ni omi-in n de, oriṣiiriṣii arun lo si n yọ oun lẹnu lati igba naa, nitori awọn ṣọja yii sọ oun mọlẹ ni isọkusọ pẹlu agbalagba ara. Iya Fẹla ni bi oun ti wa yii, oun ko i ti i gbadun, awọn kinni naa ṣi n ba oun ja, eleyii si han ninu ohun to ṣẹlẹ ni kootu naa, nitori wọn gba a laaye ko jokoo sọrọ ni, nitori wọn ni ko le duro pẹ rara lati rojọ, bo ba duro ju, yoo kan tun ṣubu ni. Ṣugbọn iyẹn ko debi ohun rẹ o, ketekete lawọn eeyan n gbọ ọrọ to n sọ lẹnu.

Lẹyin ti wọn ti beere ohun gbogbo ti wọn yoo beere lọwọ iya yii ni wọn ni ki iya naa pada sori aga awọn ẹlẹrii, ko lọọ jokoo pada, bi awọn ba tun fẹẹ gbọ ọrọ lẹnu rẹ, awọn yoo tun pe e ko wa. Adajọ tilẹ sọ pe bo ba fẹẹ lọ sile ko maa lọ, ṣugbọn iya ni oun ko ni ibi kan ti oun yoo lọ, oju oun ti ẹjọ naa bẹrẹ ni yoo ti pari, oun fẹẹ wa nibẹ ki oun gbọ ohun ti awọn ṣọja fẹẹ sọ fawọn, ohun fẹẹ mọ alaye ti wọn yoo ṣe lori ohun to fa a ti wọn fi dana sun ile awọn ọmọ oun, ati bi wọn ti sọ oun loko lati ori pẹtẹẹsi sisalẹ, nigba ti oun ko ṣe kinni kan fun wọn, ti awọn ko si ni ija ara wọn. Adajọ ko le wi kinni kan mọ, o ni ki iya naa lọọ jokoo ni, nitori oun naa kuku ti mọ itan obinrin naa pe ko ni i gba bo ṣe wi yẹn, ohun to ba ti ni oun ko ni i ṣe, ko sẹni to le sọ pe ko ṣe e, bo si ni oun yoo ṣe kinni kan, ko sẹni ti yoo da a duro

.

Bi iya ti rojọ rẹ tan ni wọn ba tun pe ọmọbinrin kan jade. Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ Fẹla loun, oun lo si ti sọ fawọn ọlọpaa tẹlẹ pe oun mọ bi ina ṣe bẹrẹ nile Fẹla, oju oun lo ṣe nigba ti ina naa bẹrẹ, oun si mọ bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ ni ṣisẹ-n-tẹle. Laide Babayade lorukọ ọmọbinrin naa, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin Fẹla ti wọn fẹran ọga wọn doju iku ni. Oun lo kọ la orukọ ṣọja to dana sun ile Fẹla mọlẹ, o ni oun mọ ọn daadaa, oun ti ri i nigba ti awọn jokoo nibi igbimọ Anya to waa wolẹ wo, ṣọja olokun kan ni, Lance Copral Agwu ni wọn n pe e, oun mọ ọn daadaa. O ni ọkunrin ṣọja naa lo gbe bẹntiroolu to si bẹrẹ si i tu u silẹ kaakiri ile naa, bi ko ba si jẹ tirẹ ni, ko si bi ile wọn iba ti jona. Laide ni nigba ti Agwu tu bẹntiroolu rẹ kaakiri tan, ṣọja mi-in ti wọn jọ wa lẹgbẹẹ ara wọn lo ṣa iṣana ọwọ ẹ, ni ina ba sọ lojiji.

Ọmọbinrin naa ni oun n sun ni, jẹẹjẹ oun loun n sun. Afi lojiji ti oun gbọ ariwo nla, ariwo naa lo si ji oun lati oju oorun. Nigba naa ni oun yọju lati oju windo yara ti oun sun, oun si ri awọn ẹlẹgbẹ oun ti wọn n sa sagbasula, wọn n sare kaakiri inu ile, wọn si n sa lọ si ẹyin ile naa. Nigba ti oun ri wọn loun naa sare girigiri jade, loun naa ba sare lọ si ẹyin ile ti wọn n sa lọ. Laide ni nibẹ ni oun ti ba Ṣẹgun Alagbara ti ẹjẹ bo o lati ori delẹ, to si wa ninu irora gidi, awọn ọmọ ẹgbẹ Fẹla to gbọ ariwo naa si ti yi i ka. O ni ṣugbọn oun Laide ni oun lọ si oju windo yara Fẹla ti oun gba a, nitori Fẹla naa n sun nibi kan lọwọ ni, n loun ba sọ fun un pe o jọ pe awọn ṣọja ti lu Ṣẹgun Alagbara ṣe leṣe o, afi ko tete jade ko waa ṣeto bi wọn yoo ṣe gbe e lọ si ọsibitu, nitori ọwọ to wa yẹn, nnkan buruku le ṣẹlẹ si i.

Laide ni eto bi wọn yoo ṣe gbe Ṣẹgun Alagbara lọ si ọsibitu lawọn n ṣe lọwọ nigba ti awọn ṣọja kan de iwaju ile awọn. O ni awọn kan de pẹlu lanrofa, bẹẹ ni ẹni kan to da bii ọga de ninu mọto mẹsidiisi. O ni ọga naa lo sọ fun Fẹla pe ko bọ silẹ waa ba awọn lati ori oke ile rẹ, ko si ṣi geeti rẹ, bi bẹẹ kọ, awọn yoo yinbọn fun un ni. O ni nigba to sọ bẹẹ, Fẹla ni ohun ti oun fẹ ko ṣe ni ko paṣẹ ki gbogbo awọn ṣọja ti wọn tẹle e wa yii maa lọ, ki wọn gbe mọto wọn, ki wọn pada sibi ti wọn ti wa, nigba naa ni oun yoo ṣi geeti fun un, ti awọn yoo si jọ sọrọ bii ọmọluabi. Ṣugbọn oun ko le waa ṣi geeti fun un nigba ti awọn ṣọja to gbebọn dani ti oju wọn dẹ le koko yii wa lẹgbẹẹ rẹ, o ni oun naa mọ pe ẹmi oun ko de, bii pe oun n fi iku ṣere ni. Ọga awọn ṣọja naa ni ko sohun to jọ ọ, ko ṣa bọ silẹ ni, bi bẹẹ kọ, wọn yoo ta a nibọn.

Ibi yii ni Fẹla ti yari pe oun ko ni i ṣilẹkun gẹgẹ bi Laide ti wi, to si ni ki awọn ọmọọṣẹ oun to ku ti gbogbo geeti pa, ki wọn ri i pe ko si bi ẹnikẹni ṣe le wọle mọ. Bayii ni wọn ti gbogbo geeti pa, Fẹla si ti kuro niwaju ọga ṣọja yii, o ti wọ inu ile rẹ lọ. Ṣugbọn ọga ṣọja naa duro sibẹ, ko si pẹ rara ti awọn ṣọja fi n de logunlogun, ti wọn n de lọgbọnlọgbọn, ti wọn n yan bii ẹni to wa loju ogun, ti wọn si n duro nikọọkan lẹgbẹẹ ara wọn ati lẹyin ara wọn, titi ti wọn fi to yi iwaju ile Fẹla po, Laide ni awọn ṣọja naa le ni ọgọrun-un meji lẹẹkan. O ni ẹni to ba ti ri wọn bi wọn ṣe to, yoo ti mọ pe wọn ko ba ti ere wa rara, nitori niṣe ni wọn peṣẹ funra wọn bii ologun, ti wọn si mu awọn ohun ija oriṣiiriṣii lọwọ. O ni bi oun ṣe ri wọn lẹru ba oun, paapaa nigba ti oun ri i ti wọn n gun fẹnsi, ti wọn si n mura lati wọ inu ile awọn.

O ni nigba naa ni oun sa wọ inu firisa nla to wa ninu ile awọn nibẹ lọ, oun ko wọ inu firisa naa, oun si pa a de mọ ara oun nibẹ, oun ko si mọ ohun to n lọ mọ. O ni ṣugbọn nibi ti oun ṣa fi ara oun pamọ si ni ṣọja kan, boya o n wa ọti ti yoo mu ni o, o kan ṣi firisa naa piri lẹẹkan naa ni, lo ba kan oun nibẹ. O ni ko tilẹ sopo fa oun jade, niṣe lo mu igo ṣinaapu kan to wa nibẹ, nigba to si la a mọ oun lori gbau lẹẹkan naa, ori oun bẹjẹ ni, ni ipọn ba tọ, ẹjẹ si n da ṣuruṣuru lara oun. O ni diẹ bayii lo ku ki oun daku nitori nigba ti ṣọja naa tun wọ oun jade tan, niṣe ni awọn ti wọn jọ wọle da bẹntiroolu si gbogbo ara oun, ti wọn si n sọ pe ki awọn kuku dana sun eleyii ki oju mọ. O ni oun ko mọ bi wọn ṣe ronu piwada, ti wọn ko tun ṣana si oun lara mọ, oun si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe wọn ko dana sun oun.

Laide ni nigba ti wọn ko awọn jade ti wọn n wọ oun lọ si baraaki Abalti, o ni awọn tun pade awọn ṣọja kan lọna, ọkan ninu wọn si fi ori ibọn rẹ soun labẹ, o bẹrẹ si i fi i gun oun ni oju ara bii pe o fẹẹ fa oun labẹ ya. O ni nigba ti awọn yoo fi de Abalti Barracks, oun ko gbadun mọ rara, nibẹ naa ni wọn si ti gbe oun lọ si ọsibitu LUTH fun itọju. Agbẹjọro ijọba dide, o jọ pe ọrọ naa n jo o lara. O ni bawo ni Laide ṣe mọ pe Agwu ni ṣọja to dana sunle n jẹ, ṣe o ti pade ẹ nibi kan tẹlẹ ni. Laide loun ko mọ ọn ri, ọjọ to gbe bẹntiroolu to n wọn ọn silẹ loun kọkọ ri i, oun si ri i lẹẹkeji nigba ti awọn n ṣe ẹjọ niwaju Adajọ Anya. O ni awọn to bii ogoji ti awọn n gbe ile Fẹla, ko si si ọmọọta ninu awọn, nitori gbogbo awọn ni awọn niṣẹ ti awọn n ṣe fun ileeṣẹ ikọrin Fẹla, ti awọn si n gba owo oṣu awọn.

Nibi yii ni Adajọ Lateef Dosumu ti ni ki kaluku sinmi, o ni ki wọn maa waa lọ sile nitori ilẹ n ṣu. O ni oun sun ẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, yẹn kan naa, ọjọ naa lawọn yoo tun maa ba ẹjọ naa lọ. N ni ọlọpaa kootu ba tun pariwo “Kọọọtu!” Onikaluku dide naro, l’Adajọ Dosunmu ba jade ni tiẹ, ni kaluku ba gba ile rẹ lọ.

 

(31)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.