Niluu Oro, iyawo ile ni oogun ni ale fi n ṣe ‘kinni’ foun, nile-ẹjọ ba ju awọn mejeeji sẹwọn

Spread the love

Iyawo ile kan, Ige Ibrahim, ti wọn fẹsun kan pe o n ṣe agbere, ati pe o tun mọ si bi ọkọ rẹ ṣe dawati, ni ki i ṣe ẹbi oun o. O ni ki i ṣe ifẹ inu oun lati lọwọ ninu iwa naa, ṣugbọn oogun ni Nasiru Tanko to jẹ ale oun, lo foun.

Obinrin naa ṣalaye yii lasiko ti wọn wọ oun ati ale rẹ, Tanko, lọ sile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Ilọrin, lọsẹ to kọja.

 

Ilu Oro, nijọba ibilẹ Irẹ̣pọdun, nipinlẹ Kwara, niṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ. Iwadii fi han pe lati bii ọdun meji lawọn mejeeji ti n ba ara wọn lajọṣepọ ko too di pe ọwọ palaba wọn ṣegi. Ẹnikan to jẹ aburo ọkọ obinrin naa lo fi ọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Oro leti.

Ninu alaye onitọhun, o ni ẹgbọn oun, Danladi Abubakar, to jẹ ọkọ obinrin naa lo ka awọn mejeeji mọ ibi ti wọn ti n ṣe ‘kinni’ fun ara wọn.

Akọsilẹ fi han pe latigba ti Abubakar ti pe Tanko nija lori bo ṣe n yan iyawo rẹ lale lọkunrin naa ti dawati. Titi di akoko yii, ko sẹni to mọ pato ibi to wọlẹ si.

Iyalẹnu ni pe pẹlu bi Abubakar ṣe poora labaadi yii, awọn afurasi mejeeji ti wọn n yan ara wọn lale naa ko ṣiwọ iṣẹ, ṣe ni wọn tun n lo anfaani naa lati tẹsiwaju ninu biba ara wọn sun lọ rai. Eyi gan-an lo mu ki wọn lọọ fi pampẹ ọba gbe Tanko ati obinrin naa.

Lasiko iwadii, abilekọ ọhun jẹwọ pe loootọ loun lọwọ ninu iwa agbere naa, ṣugbọn oogun ni Tanko lo foun lati ma jẹ koun mọ nnkan toun n ṣe mọ, ko le baa maa ri oun ba sun.

Agbẹjọro ijọba, Yusuf Nasir, rọ ile-ẹjọ lati fi awọn afurasi mejeeji sahaamọ ọgba ẹwọn titi tiwadii to n lọ yoo fi pari.

Adajọ Muhammed Dangana ni ki wọn maa ko wọn lọ ṣewọn, ki wọn si wa nibẹ titi di ọjọ keje, oṣu kẹjọ, ọdun 2019 ti ẹjọ naa yoo tun tẹsiwaju.

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.