N’Ileefẹ, Stephen atawọn ọrẹ rẹ ji kaadi ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu miliiki, ẹwọn ni wọn wa bayii

Spread the love

Ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Ileefẹ ti sọ pe ki wọn lọọ fi awọn afurasi adigunjale mẹfa pamọ sọgba ẹwọn titi imọran lati ileeṣẹ eto idajọ lori ẹsun idigunjale ati kiko awọn nnkan ija oloro kaakiri ti wọn fi kan wọn.

 

Awọm mẹfẹẹfa ọhun ni Stephen James, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Abayọmi Baba-Samson, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Samuel Egbe, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Monday John, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, John Daniel, ẹni ọdun mẹtadinlọgbon ati Emmanuel Irem, toun jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.

 

Ṣugbọn gbogbo ẹbẹ awọn afurasi adigunjale ọhun ni adajọ Majisreeti naa, Muhibah Ọlatunji, ko kọbiara si, o ni kootu oun ko ni aṣẹ ati agbara lati gbọ ẹsun idigunjale.

 

Ọlatunji sọ fun agbefọba to n gbọ ẹjọ naa, Inspẹkitọ Adebayọ Joseph, lati gbe ẹda iwe ipẹjọ naa lọ sọdọ ọga agba nileeṣẹ to n gbọ ẹsun araalu lori eto idajọ, iyẹn Director of Public Prosecution (DPP) fun imọran.

 

O waa paṣẹ pe ki awọn afurasi adigunjale naa lọọ maa ṣe faaji lọgba ẹwọn ilu Ileefẹ titi ti imọran yoo fi wa lori ile-ẹjọ ti ọrọ wọn tọ si, o si sun igbẹjọ wọn siwaju di ọjọ karun-un, oṣu kẹta, ọdun yii.

 

Ṣaaju ni agbefọba, Adebayọ Joseph, ti ṣalaye funle-ẹjọ pe ọjọ keje, oṣu kin-in ni, ọdun to kọja, lawọn olujẹjọ ọhun huwa naa ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ loju-ọna Ileefẹ si Ileṣa.

 

O ni awọn mẹfẹẹfa digun ja Oluwajuyigbe Oludare lole pẹlu ibọn, wọn si gba mọto Toyota Corolla rẹ to ni nọmba  EPE 267 FH, awọn nnkan ẹṣọ ara foonu, bata, owo to le ni miliọnu kan ati igba Naira.

 

Apapọ owo nnkan ti wọn gba lọwọ Oludare gẹgẹ bi Adebayọ ṣe wi le ni miliọnu mẹrin ataabọ Naira (#4,693,000).

 

Bakan naa ni wọn gba bọọsi Toyota Sienna to jẹ ti Adeshina Adeṣọla, wọn gba foonu rẹ, bẹẹ ni wọn gba owo lọwọ ẹ. Tibọntibọn ni wọn gba foonu ati owo lọwọ ọkunrin kan to n jẹ Joshua Sunday.

 

Kaadi iforukọsilẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ ti Ọlaitan Gbọlagade, kaadi idibo rẹ, aago ọwọ, foonu ati owo ni wọn gba lọwọ ọkunrin naa.

 

Nigba ti awọn ikọ ẹlẹni mẹfa naa gba Agbaje Ọdunayọ mu ni tiẹ, agbefọba ṣalaye pe wọn gba paali miliki olomi mẹfa, paali ọṣẹ ifọyin kan, foonu atawọn nnkan mi-in lọwọ ẹ.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.