Nigba ti Fẹranmi n tibi iṣẹ bọ ni ọkọ tẹ ẹ pa l’Abẹokuta Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Spread the love

Gende-kunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Fẹranmi Abii, pade iku ojiji lalẹ ọjọ Iṣẹgun to kọja yii, nigba ti mọto kan tẹ ẹ pa lasiko to n bọ lati ibiiṣẹ oojọ rẹ niluu Abẹokuta.

 

Ọmọ ọdun mẹrinlelogun pere ni Fẹranmi gẹgẹ bi wọn ṣe fi to wa leti, iṣẹ telọ lo n ṣe. Sutana, iyẹn aṣọ ṣọọṣi ti awọn ṣọọṣi alaṣọ funfun maa n wọ la gbọ pe o maa n ran, o si jẹ ọkan pataki ninu ṣọọṣi alaṣọ funfun to n lọ laduugbo Kutọ, l’Abẹokuta.

 

Lalẹ ọjọ tiṣẹlẹ yii ṣẹlẹ si Fẹranmi, baba agbalagba kan la gbọ pe o n wa mọto rẹ bọ ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ naa. Nigba to de ikorita kootu giga ati ti Majisireeti to wa n’Iṣabọ, ni Ijamba ṣẹlẹ, ti baba naa fi mọto rẹ kọlu Fẹranmi to n dari lọ sile lati ibiiṣẹ.

 

Ẹsekẹsẹ ti mọto naa tẹ ọmọkunrin naa mọlẹ lo ku, ko si ohun ti ẹnikẹkẹni le ṣe si i lati ra ẹmi rẹ pada mọ.

Baba to fi mọto pa a yii ko sa lọ, niṣe lo n pariwo pe oun ti daran, ko si pẹ sigba naa ti wọn fi ba a wa nọmba ẹrọ ibanisọrọ awọn obi ọmọ to ku naa, nitori ibi iṣẹlẹ naa ko jinna sile awọn Fẹranmi. Funra awakọ yii lo pe awọn obi ọmọ naa, to sọ ọran toun da fun wọn.

Ibanujẹ dori awọn obi Fẹranmi kodo, ṣugbọn wọn lawọn gba f’Ọlọrun. Wọn ni ẹni to pa a ko mọ-ọn-mọ, o ṣeeṣi ni.

Ikore ọlọdọọdun ti wọn maa n ṣe ni ṣọọṣi wọn to wa ni Kutọ ni wọn n palẹmọ lọwọ, wọn si royin bo ṣe jẹ ipa pataki ni oloogbe yii ti mura silẹ lati ko nibẹ.

Ọjọ Sannde ijẹta yii ni wọn ṣe ikore ọhun, wọn kan ṣe e bo ṣe gba ni. Koda, wọn ko ba yẹ ẹ gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ṣugbọn nitori awọn eto kan ti wọn ti ṣe silẹ, nigba ti ẹnikẹni ko mọ pe Fẹranmi to n ranṣọ ọpọ eeyan ninu ṣọọṣi naa yoo ku lojiji, ni wọn ṣe rọju ṣe e bo se gba, ti kaluku pada sile rẹ lai si ayọ ikore gidi bo ṣe maa n ri tẹlẹ.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.