Nigba ti awọn oṣiṣẹ Naijiria Daṣẹ silẹ ni 1964, ẹni ti ko ra paapaa san (2)

Spread the love

Nigba ti iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ yii bẹrẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun 1964, ti gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ taku pe awọn ko ṣiṣẹ mọ, afi awọn kọọkan ninu wọn, Bauchi ni Tafawa Balewa, olori ijọba Naijiria nigba naa wa to ti n sinmi. Ohun to ro nibẹrẹ ni pe bi awọn oṣiṣẹ ṣe maa n halẹ wọn naa niyẹn, ko si le pẹ ti wọn yoo fi pada sẹnu iṣẹ nigba ti wọn ko ba ri ohun ti wọn n beere, ti ko si sẹni to da wọn lohun ariwo ti wọn ba n pa. Ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ, kaka ko si rọlẹ, niṣe lo n le si i. Nigba ti ọrọ naa fẹẹ kọja atunṣe, to si bẹrẹ si i mu adanu nla wa fun ijọba ni Balewa pa isinmi rẹ ti, olori ijọba naa si balẹ si Eko ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa naa, o ni kawọn minisita oun ati awọn oludamọran gbogbo bẹrẹ eto lati ri awọn olori ẹgbẹ oṣelu yii, ki wọn yanju ọrọ naa, nitori ariwo to n lọ niluu yii ko ba oun lara mu.

Ki Balewa tilẹ too de, awọn olori awọn oṣiṣẹ funra wọn ti ṣepade lọjọ Tọsidee, Ọjọbọ, ọjọ kẹrin, oṣu kẹfa naa. Ohun ti wọn pinnu nipade wọn gẹgẹ bi Aṣaaju ẹgbẹ yii, Alaaji Haruna Adebọla, ṣe wi ni pe awọn ko ni i duro de ki ijọba pe awọn rara ki awọn too wa wọn lọ, awọn yoo wa wọn lọ si ọfiisi wọn, awọn yoo si mura ipade dani lati sọ fun wọn pe ija ti awọn n ja ki i ṣe ija ajadiju, ija ontaja ati onraja ni, ohun ti awọn n fẹ ni ẹkunwo owo-oṣu lọwọ ijọba to gba awọn siṣẹ, bi wọn ba ti fowo kun owo awọn, ko si ija mọ rara. Adebọla sọ fawọn olori ẹgbẹ naa to ku ki wọn sọ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ pata pe wọn ko gbọdọ pada sẹnu iṣẹ o, afi nigba ti awọn ba too ṣepade pẹlu awọn eeyan ijọba, ti wọn si gba ohun ti awọn n sọ. O ni ṣugbọn awọn ko ni i duro ko jẹ awọn ni wọn pe awọn, awọn n lọọ ba wọn lọjọ Mọnde.

Ọkunrin naa ni ohun ti awọn n lọọ sọ fun wọn naa ni pe awọn ko ni i pada sẹnu iṣẹ, awọn ko si gba iye ti ijọba wọn sọ pe wọn fẹẹ fi kun owo-oṣu awọn, ohun ti awọn faramọ ni iwe ti Morgan gbe jade, to si ṣalaye iye ti wọn yoo fun awọn sibẹ, bẹẹ lawọn yoo tun ri awọn ọlọpaa lati ṣalaye fun wọn pe ki wọn yee daamu awọn, ọrọ ti ko kan wọn rara ni wọn n tori rẹ ti oko wa sile si, ki wọn fi awọn ati awọn eeyan ijọba silẹ, onibaara meji lo n ja, awọn yoo si yanju ọrọ naa laarin ara awọn. Ohun ti wọn sọ pe wọn n ba lọ si ile iṣẹ ijọba ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun 1964 niyẹn, gbogbo awọn oṣiṣẹ, atawọn oniṣẹ adani, si ti fọkan si i pe ijọba naa yoo ri wọn, wọn yoo le jọ sọ ọrọ naa ni asọyanju, debii pe awọn oṣiṣẹ yoo le pada sẹnu iṣẹ wọn, paapaa nigba ti olori ijọba funra rẹ, Balewa ti de ni Satide.

Michael Imoudu naa sọrọ nibi ipade yii, o ni ki awọn oṣiṣẹ mọ pe ija ti awọn n ja, ija ominira awọn ni, ki wọn ma jẹ ki awọn oloṣelu tabi ijọba kankan mu wọn lẹru. O ni ki wọn ma kaaanu oun bi awọn ọlọpaa ba mu oun, ti wọn ni wọn ti oun mọle, nitori o da oun loju pe bi wọn ba ti mu oun naa ni wọn yoo fi oun silẹ, nigba ti oun ko ṣe nnkan kan fun wọn ju pe oun n ja fun ẹtọ awọn oṣiṣẹ reluwee ti wọn wa labẹ oun lọ. O loun lolori awọn oṣiṣẹ reluwee, oun ko si le maa wo kiya maa jẹ awọn oṣiṣẹ abẹ oun, bi awọn ba si ti ba ijọba sọ ọ lẹrọ ti wọn ko gbọ, to jẹ ede kan naa ti yoo tete ye wọn ni ki awọn da iṣẹ silẹ, ko si laifi nibẹ, awọn yoo maa daṣẹ silẹ lọ naa ni. O ni awọn oloṣelu n bọ waa halẹ mọ wọn, ṣugbọn ọna kan ṣoṣo ti wọn fi le bọ lọwọ wọn naa ni ki wọn ma bẹru wọn, ko sohun ti wọn le ṣe.

Gbogbo bi awọn oṣiṣe ti n ṣepade wọn naa ni awọn eeyan ijọba naa n gbọ, wọn si mọ gbogbo ohun ti wọn sọ pe wọn n bọ waa ba awọn fun. Awọn naa ko waa duro o, wọn ni ẹni ti awọn oṣiṣẹ yii yoo sọ lẹnu ni wọn n wa. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹka to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ti ranṣẹ si wọn pe awọn yoo ba wọn ṣepade, awọn fẹ ki awọn jọ jokoo, ki awọn si sọ ohun to wa nidii ọrọ naa gan-an fun wọn. Ọkan ninu awọn akọwe agba ileeṣẹ naa lo kọwe si Alaaji Adebọla, to si sọ fun un pe ijọba naa ti n mura ipade de wọn, ki wọn maa bọ ki awọn jọ fikunlukun, ki ọrọ naa si pari sibẹ pata. Adebọla ba awọn oniroyin sọrọ nigba ti iwe naa tẹ ẹ lọwọ lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, o si sọ pe awọn yoo mura lati de ọdọ wọn laaarọ kutu, ki awọn le fi aarọ sọ ohun ti awọn ba fẹẹ sọ. Inu awọn oṣiṣẹ to ku paapaa dun, kaluku si ti fọkan si i pe ipade naa yoo so eso rere.

Ṣugbọn ipade naa ko waye. Wọn o ṣepade kankan lọjọ Mọnde ti wọn ti mura naa mọ, awọn olori awọn oṣiṣẹ yii kan lọ sọhun-un ni, wọn ko rẹni kan da wọn lohun, nigba ti wọn si pooyi titi, ti wọn n sọ fun wọn pe awọn ti wọn fẹẹ ri ti lọ sipade kan tabi wọn ti jade, awọn naa pada si ile, wọn n reti ohun ti ijọba Balewa yoo tun sọ. Ohun ti ko jẹ ki ipade yii waye ni pe Tafawa Balewa funra rẹ ti pe awọn minisita rẹ jọ, o si ti ṣepade pẹlu wọn ni alẹ ọjọ Sannde, iyẹn ọjọ Aiku, lọjọ to ku ọla ki wọn ba awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ yii ṣepade, nibẹ lo jọ pe wọn ti fẹnu ko pe ko si ipade kankan ti awọn fẹẹ ba awọn olori ẹgbẹ oṣelu naa ṣe, awọn yoo wa ọna mi-in lati fi sọ fun wọn pe wọn ko le maa halẹ mọ awọn, ijọba lagbara ju gbogbo eeyan lọ, o lagbara ju awọn oṣiṣẹ lọ, ohun ti ijọba ba si fẹẹ ṣe naa ni yoo ṣe, ẹnikan ki i dijọba lọwọ.

Iyẹn ni ko ṣe sẹni to pe wọn sipade mọ, nitori wọn ti fa iṣẹ naa le awọn meji lọwọ pe ki wọn mọ bi wọn yoo ṣe mu awọn ọga ileeṣẹ ijọba koko, ti wọn yoo fi pe awọn oṣiṣẹ wọn to n daṣẹ silẹ yii pada sẹnu iṣẹ, ti wọn yoo si doju ti awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ to n ko wọn jade. Jacob Obande ti i ṣe minisita fun ọrọ awọn oṣiṣẹ ati Johnson Modupe Johnson (JMJ), ti i ṣe minisita fun eto iṣẹ ṣiṣe ni wọn jọ ni ki wọn wa nidii ọrọ naa, Balewa ni oun funra oun yoo si ba gbogbo ilu sọrọ lọjọ Mọnde yii, nitori bẹẹ, ki wọn ma jẹ ki awọn olori ẹgbẹ oṣelu yii da wọn girigiri, ki wọn pa wọn ti sẹgbẹẹ kan, awọn oṣiṣẹ wọn ni ki wọn maa ba ṣe. Nibi ti wọn pari ọrọ wọn naa si ree ti wọn fi tuka ni alẹ ọjọ Sannde yii, inu awọn minisita yii si dun pe Balewa funra rẹ yoo yanju ọrọ, ko si ipade kan ti awọn tun fẹẹ ba awọn olori awọn oṣiṣẹ wọnyi ṣe.

Nigba ti awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ yii ti lọ si ileeṣẹ ijọba ti wọn ko ri ẹnkẹni ba ṣepade ni wọn ti pada sibudo wọn, ti wọn jokoo papọ, wọn ko si tuka, wọn n reti igba ti awọn yoo gbọ kinni kan lẹnu ijọba. Ṣe wọn ko kuku mọ pe ipade ti lọ, ati pe Balewa yoo sọrọ lọjo naa. Amọ ko pẹ ti awọn oniroyin fi gbe e si wọn leti pe olori ijọba Naijiria naa yoo ba gbogbo ilu sọrọ lori ọrọ awọn oṣiṣẹ to n daṣẹ silẹ yii, o si ya wọn lẹnu pe Balewa ko ba awọn ti ọrọ kan sọrọ, gbogbo ilu lo fẹẹ ba sọrọ, iyẹn ni wọn ṣe fẹẹ mọ ohun to fẹẹ sọ gan-an. Wọn jokoo sidii redio wọn n reti asiko ti Balewa yoo sọrọ, wọn ko si kuro nibẹ titi di aago mẹrin irọlẹ, nigba ti ẹni ti wọn n reti naa de ori afẹfẹ, ti gbogbo wọn si bẹrẹ si i gbọ ohun ti Balewa ni fun wọn. Ṣugbọn o, ọtọ ni ohun ti wọn n reti, ọtọ ni ohun ti Balewa gbe yọ si wọn.

Ija ni ọkunrin olori ijọba Naijiria naa gbe jade ni, ija gidi paapaa. O ni oun ko raaye gbogbo ohun ti wọn n ṣe yẹn o, oun si paṣẹ bayii pe ki gbogbo oṣiṣẹ pada sẹnu iṣẹ wọn, eyi to ba kọ ti ko pada sẹnu iṣẹ yoo ri oju pipọn ijọba. Balewa ni, “Ẹyin lgb mi m Naijiria, mo fẹẹ ba yin sr loni-in lori r nla kan to le. Lati ibr s to kja lawn oiṣẹ ijba kan ti n daṣẹ sil, plu awn oiṣẹ ileeṣẹ aladaani kan tawn naa darap m wn. Ohun ti wn lo fa a ti awn fi n daṣẹ sil ni pe ka gbe ipinnu wa lori iwadii ti igbim Morgan e jade, nigba ti a si gbe ipinnu wa jade tan, wn tun ni ohun ti a s sibko t awn lrun, iyẹn ni we n daṣẹ sil o. Awọn to y ki wọn ba awn olori gb awọn oiṣẹ yii sr ti ba wn sr pe ki wn ni suuru, ka e ohun gbogbo ni ibamu plu ofin.

Am gbogbo r ti a s ati b ti a b awọn oiṣẹ yii ko iṣẹ ld wn, nie ni wn n ba iyanṣẹlodi naa l, bo til j pe awn naa ri i pe iwa wn yii n ba eto r-aje il wa j gidigidi. Mo waa n lo asiko yii lati gba awn oiṣẹ wnyi nimran pe ki wn pada snu iṣẹ fun anfaani ara wn, nitori bi wn ko ba pada, ijọba yoo yiju pada si wn. Bẹẹ naa ni mo n lo akoko yii lati s fawn olori gb oelu yii pe ki wọn m gbogbo na ti wn yoo gbe e gba ti awọn oiṣẹ yii yoo fi pada snu iṣẹ wn ni kiakia. Ijba mi ti s ohun ti wn le e nipa aba ti igbim Morgan da fun wa lori r owoou awn oiṣẹ, a ko le e ju bẹẹ l ni. Ijọba ti alaye pe lati san owo gbi iru eyi ti awọn oiṣẹ n reti yn ko ni i j ki eto r aje il wa l siwaju, a oo kan wa loju kan ni. A ko aa gbd tori pe awn oiṣẹ yoo gbowo, ki Naijiria baj.

Ju gbogbo l, ohun yoowu ti a ba fẹẹ e, awọn oiṣẹ yii kk gbd pada snu iṣẹ wn na, bi bẹẹ k, wn yoo ri pipn oju ijba. Balewa sọ ọrọ to ju bayii lọ, amo koko ibẹ naa ni pe ijọba oun ko ni i gba gbẹrẹ fawọn olori awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ yii, oṣiṣẹ to ba si tẹle wọn yoo ri ija ijọba oun. Ọrọ naa ya awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ lẹnu, o ya awọn olori wọn naa lẹnu, koda, o ya awọn minisita ati awọn aṣofin paapaa lẹnu. Ohun to si fa iyanilẹnu yii ni pe oniwa tutu eeyan ni wọn mọ Balewa si, ko si bi ọrọ yoo ti ṣe le to ti yoo fa ibinu yọ. Ohun to waa le fa ibinu niru asiko yii, paapaa ọrọ to yẹ ki awọn olori ẹgbẹ oṣelu ati awọn minisita jọ jokoo sọ, ki wọn si yanju rẹ, ko ye awọn eeyan naa, wọn ni Balewa kọ lo n sọrọ, o ṣee ṣe ko jẹ ọrọ to wa lẹnu Ahmadu Bello ati awọn onimọran rẹ bii Ladoke Akintọla lọkunrin Prime Minister yii n sọ.

Ohun to si fa ija ati ibinu naa niyẹn o, nitori lẹsẹkẹsẹ lẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti yari, alẹ ọjọ naa gan-an ni wọn ti sọrọ, wọn ni ọrọ ti Balewa sọ ya awọn lẹnu. Wọn ni Balewa ti awọn mọ kọ lo n sọrọ yii, ohun to si n dun awọn ni pe awọn ti wọn n ti i lati sọ iru ọrọ bayii si awọn oṣiṣẹ kan fẹẹ sọ ijọba rẹ lẹnu loju gbogbo aye ni. Alaaji Adebọla sọrọ lẹyin ti oun ati awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ to ku ti ṣepade, ohun ti wọn si sọ jade fawọn eeyan ni pe awọn ti ri i pe ijọba apapọ ko ṣetan lati ba awọn oṣiṣẹ sọrọ tabi lati ṣe ohun ti wọn fẹ fun wọn, kaka bẹẹ, agbara ni wọn fẹẹ lo, wọn fẹẹ lo ṣọja ati ọlọpaa lati maa fi halẹ mọ awọn kiri, ati lati maa fi wọn le awọn oṣiṣẹ pada sẹnu iṣẹ, koda ki owo-oṣu wọn ma to wọn i jẹun. Wọn ni awọn naa ti mura silẹ dejọba yii, ohun to ba wu Balewa ko wi, awọn oṣiṣẹ ko ni i pada sẹnu iṣẹ wọn.

O tilẹ jọ pe ọrọ ti Balewa sọ yii dija awọn mi-in naa, awọn oṣiṣẹ ti ko si lọwọ ninu ọrọ naa tẹlẹ jade pe awọn naa ko ṣiṣẹ mọ. Gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba to ku pata, iyẹn awọn Civil Servants, awọn ti wọn ti ni awọn ko ni i fi iṣẹ awọn silẹ lori ọrọ naa, gbogbo wọn lo daṣẹ silẹ lọwọ kan, lati ọjọ Mọnde ti Balewa ti sọrọ ni wọn ti ni awọn ko ṣiṣẹ mọ. Awọn banki kọọkan ti wọn ti n yọ iṣẹ ṣe, ti awọn eeyan si n lo anfaani naa lati ri owo wọn gba ni awọn naa ko ni i ṣiṣẹ mọ o, lawọn naa ba da iṣẹ silẹ bẹẹ. Bayii lo di pe wọn ti gbogbo ilẹkun ileeṣẹ ijọba gbogbo pa, ti awọn banki naa ko si da ẹnikẹni lohun mọ, wọn ti geeti banki wọn. Ohun ti wọn sọ ni pe bi oṣiṣẹ ko ba ri owo-oṣu to dara gba, ko sẹni ti yoo ko owo si banki, bi banki ko ba si ri owo gba lọwọ awọn eeyan, oun naa ko ni i gba oṣiṣẹ siṣẹ wọn.

Nigba naa ni ọrọ naa le koko pada, o si le ju bi awọn eeyan ti ro o lọ. Nnkan daru fun wọn ni West, o daru fun wọn ni East, o daru fun wọn ni Federal, ilẹ Hausa nikan lọrọ naa ko ti ba wọn fina pupọ, nitori awọn oṣiṣẹ ijọba tiwọn n ṣiṣẹ. Ṣugbọn meloo ni wọn ninu ọrọ ilẹ yii. Ladoke Akintọla sare wa si Eko, ṣugbọn ko ri kinni kan yanju ninu ọrọ naa, o si pada s’Ibadan pe boya oun yoo ri awọn oṣiṣẹ yii yi lọkan pada ki wọn fi pada sẹnu iṣẹ, amọ pabo ni awọn irin-ajo ati ilakaka naa bọ si, n loun naa ba yaa gbe jẹẹ. Iroyin jade lati ọdọ Ahmadu Bello pe ohun ti Balewa sọ yẹn lo dara, o ni awọn oṣiṣẹ yẹn ko mọ ohun to n ṣe wọn ni, bo ba jẹ wọn mọ ni, wọn yoo tẹle aṣẹ ijọba. O ni ni toun, gbọn-in loun wa lẹyin Balewa ati ijọba rẹ, ki wọn maa ba iṣẹ wọn lọ. Ṣugbọn iṣẹ wo ni wọn fẹẹ ba lọ!

Michael Okpara lati ilẹ Ibo lọhun-un naa da si ọrọ yii, o ni ki Balewa yaa pa isinmi rẹ ti, ko gbọdọ kuro l’Ekoo bi ko ba yanju ọrọ awọn oṣiṣẹ naa, o si kọyin si i pẹlu ọrọ to sọ si awọn olori wọn. O ni bi ijọba Balewa ba mọ pe ọrọ awọn oṣiṣẹ yii jẹ oun lọkan, oun si fẹẹ mu idẹrun ba wọn loootọ, ki i ṣe bo ṣe n sọrọ yii ni yoo maa sọrọ, bẹẹ ni ko ni i mura ija pẹlu wọn. O ni bo ti n mura ija yii, bi awọn oṣiṣẹ naa ba yiju pada si i tan ni Naijiria, ko sibi ti yoo gba, tabi ọna ti yoo fi ṣejọba rara. Prẹmia, olori ijọba Eastern Region, naa ni ni toun atawọn minisita oun, awọn wa lẹyin awọn oṣiṣẹ yii, nitori ohun ti wọn n beere lọwọ ijọba ko pọ ju, bi Balewa yoo ba si ṣe daadaa, ko ma gbọ ọrọ awọn to jẹ ẹru ni wọn n lo latilẹ, ẹru naa ni wọn si ka awọn oṣiṣẹ si, ko jokoo ba awọn oṣiṣẹ ṣepade funra ẹ, ko le mọ ohun ti wọn fẹ gan-an.

Nigba naa ni ijọba Balewa gba ọna ẹyin yọ si awọn oṣiṣẹ yii, o ni awọn ti wọn fẹẹ ba ọna ipa gba ijọba lọwọ awọn ni wọn wa nidii ọrọ awọn oṣiṣẹ yii, awọn ti wọn fẹẹ doju ijọba apapọ bolẹ ni wọn, awọn agbofinro yoo si ri si ọrọ wọn. Ọrọ naa bi awọn oṣiṣẹ atawọn olori wọn ninu, wọn fibinu sọrọ, wọn ni Ladoke Akintọla ati Ahmadu Bello ni yoo ti ijọba Balewa pa. Ẹgbẹ Action Group naa fibinu gbe iwe jade. Amọ bi gbogbo ọrọ naa ti n ho yeeyee lọtun-un ati losi yii, iṣoro wa fun Akintọla lati sọrọ, bo tilẹ jẹ pe oun naa mọ pe ohun to n ṣẹlẹ yii ko dara. Ṣugbọn awọn ọmọ Balewa ti mura ija ni tiwọn o, awọn olori ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ yii naa si ti ni awọn ko ni i gba fun wọn, ni gbogbo ọrọ naa ba kuku waa fọ loju patapata.

 

 

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.