Nigba tawọn eeyan nla nla bayii ba n jade laye

Spread the love

Ara mi ko balẹ rara lati igba ti mo ti gbọ iku Sophie

Oluwọle. Obinrinọmọwe to n kọ ni lẹkọọ nipa imọ ijinlẹ ni Yunifasiti Eko ni mo n sọ o. Anti lo jẹ fun iru wa, ṣugbọn ọrẹ wa naa ni. Obinrin loun, ọkunrin lawa, sibẹ, ọrẹ ni wa nidii imọ, ẹnikan ti Ọlọrun fun ni imọ ati  ọpọlọ pipe ni. Ede oyinbo lo fi kọ gbogbo ẹkọ imọ to ni, amọ ẹni ti yoo pa a layo nidii aṣa ati iṣe Yoruba, tọhun yoo mura gidi ni. Latigba to ti fẹyinti bii olukọni Yunifasiti Eko, ko si ohun meji to n gbe larugẹ ju aṣa Yoruba lọ, o fẹki kinni naa dagba, o fẹ kawọn ọmọ Yoruba kari aye mọ ohun t’Ọlọrun fun wọn, ki wọn si maa tọju rẹ. Ṣugbọn o pariwo titi to fi ku ni, ko jọ peẹnikan gbohun ẹ ninu awọn to le mu ọgbọn ori ẹ lo, wọn kan n wo o bii oniranu to n sọ ọrọ ti ko wulo ni. Bẹẹ Sophie Oluwọle ki i ṣeeyan bẹẹ,ọkan ninu awọn ọlọgbọn ori t’Ọlọrun fun Naijiria ni.

Awaye-i-ku kan ko si , ko si bi a o ti ṣe pẹ laye to, a o lọ sọrun gbẹyin naa ni. Ṣugbọn ẹni to ba n gbọ ọrọ ati ohun Ọjọgbọn Oluwọle, yoo rope ko ti i dagba bẹẹ, ko ti i yẹ ko ku, bẹẹ ọmọ ọdun mẹtalelọgọrin ni. Ni Naijiria ti a wa yii, nibi ti iku ti di meji eepinni to n pa awọn ọmọkeekeekee, ẹni ba jaja lo ọgọrin ọdun laye ko ṣanku, ẹni to yẹ kayeṣeranti ẹ ni. Sophie ki i ṣe ọmọde. Ṣugbọn ohun aburu to wa laarintiwa nibi, paapaa laarin awọn ti wọn n ṣe olori wa, awọn oloṣelu to nṣejọba, ni pe ko si bẹnikan ṣe le daa to, to le wulo fun ilu to, wọn ko ni i wo ọdọ ẹ nigba to ba wa laye, gbogbo ohun to ba sọ ko jẹ nnkan kan leti wọn. Nigba tobinrin yii ku, gbogbo awọn alagbara Naijiria yii ni wọn bẹrẹ apọnle buruku fun un, paapaa awọn ti Yoruba wa nibi. Ẹ beere lọwọ wọn pe meloo lo mu ọrọ to sọ nigba aye ẹ lo ninu wọn.

Sophie ti ku bayii, oun ti gbe ọpọlọ ẹ lọ, o gbe imọ ẹ lọ, o si gbe gbogbo awọn eto to wu u ko ṣe fun awọn Yoruba lọ. Ohun to maa ndun mi ninu ọrọ awọn oloṣelu ti wọn n ṣejọba wa ree, awọn ti wọn jẹọmọ Yoruba gidi. Awọn eeyan kan wa ti wọn wulo fun ilu yii, ti wọn wulo fun Yoruba daadaa, nitori awọn ohun to wa ninu ọpọlọ wọn, ko siọmọwe tuntun ti yoo mọ ọn, bẹẹ ni ko si awọn ọmọde ode-oni to le ri i tu palẹ, awọn nikan ni wọn le ṣe alaye rẹ ko ye ni. Awọn eeyan yii mọaṣa, wọn mọ iṣe, wọn si mọ ohun to n yọ orilẹ-ede Yoruba lẹnu. Amọkaka ki awọn ti wọn n ṣejọba yii ri wọn ki wọn si pọn wọn le, ki wọn beere awọn ohun ti wọn fẹ ati ọna ti wọn fi le kọ awọn ọgbọn ori wọn yii silẹ, bi wọn ko ba mu wọn lọtaa, wọn yoo maa sa fun wọn. Wọn le ni wahala tiwọn ti pọ ju, tabi ki wọn ni ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa.

Ṣe gbogbo eeyan naa lo fẹ owo ni! Ṣe gbogbo eeyan naa lo jẹ ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa. Awọn agbalagba kan wa to jẹ ati ohun ti wọn yoo jẹ, ati eyi ti wọn yoo lo titi ti wọn yoo fi ku, Ọlọrun ti ṣe e fun wọn, ilu tabi orilẹ-ede ko le ṣe oore kan fun wọn mọ, awọn lo ku ti wọn ni oore nla ti wọn le ṣe fun orilẹ-ede wọn, oore naa ko si ju imọ ti wọn ni lọ. Imọ yii a maa wulo fun ilu, a si maa ṣe anfaani gidi fawọn eeyan. Koda, nigba ti ẹni to ni imọ naa ba ku tan, awọn ti wọn ba wa laye yoo mu un lo daadaa.  Ko si ohun ti awọn eeyan fẹ ju ki ijọba pese aaye atiọna to dara lati ṣe iṣẹ naa lọ, bẹẹ ni ko si na wọn lowo kankan rara. Amọ awọn eeyan wa ki i ṣe bẹẹ nitori wọn ko fẹ ootọ ọrọ, wọn ko fẹẹni ti yoo sọ ootọ fun wọn, afi ẹni ti yoo purọ fun wọn. Igba tẹni naa ba ku ni wọn yoo maa sọ pe ko siru ẹ ni gbogbo agbaye.  Sophie ti lọbayii, oju ti mọ, ki kaluku mura ko maa pariwo ẹnu ẹ kaakiri.

Nibi ti mo ti n ronu iku tirẹ yii ni mo ti gbọ iku Alaaji Shehu Shagari, baba kan to ṣejọba ilẹ yii laarin ọdun 1979 si 1983. Kinni kan dun mọmi ninu nipa iku baba yii, iyẹn naa ni pe ẹni to fibọn gbajọba lọwọ rẹnaa lo n ṣejọba Naijiria bayii, awọn eeyan si ti gbọ gbogbo ohun to sọnipa ọkunrin yii, ọrọ to si sọ nipa rẹ lọdun 1984 yatọ si ohun to n sọbayii, nitori o sọ pe; eeyan gidi ni, oloootọ ni, olori ijọba ti ko si iru rẹ ni. Buhari ko sọ gbogbo eleyii ni 1984, ohun to sọ fun wa ni pe ole ati onijẹkujẹ  eeyan ni Shagari, pe awọn ẹṣẹ ati idi ti awọn fi gbajọba lọwọrẹ niyẹn, nitori ko mọ ohun n to n ṣe rara, abẹ rẹ ni jibiti ati iwa ibajẹpin si. Buhari ko le sọ bẹẹ yẹn mọ bayii, o ti sọ pe ko si ọmọluabi nile ijọba to tun ju Shagari yii lọ.

O wu mi lati sọ ọrọ Shagari, nitori bo ba jẹ bi oun ti ri ni awọn Fulani to ku ri ni, gbogbo ariwo ta a n pa loni-in yii ko ni i waye rara. Bo tilẹ jẹ pe Shagari ki i ṣe ọmọ ale ni Sokoto, to jẹ ojulowo Fulani  ni, sibẹ, ijọba toṣe fun Naijiria lasiko tirẹ ko ni kinni kan ti eeyan le pe ni ẹlẹyamẹya ninu rara. Bawọn kan ti wọn yi i ka ba  si n ṣe ẹlẹyamẹya, tabi ti wọn ba fẹẹ fi ọla ati ipo pe awọn lawọn wa nijọba rẹ awọn to ku jẹ, kia ni Shagari yoo yanju ọrọ naa, ko si ni i fẹ ki ẹnikẹni jẹ oogun olooogun mọ tirẹ, ẹnikan to yatọ si bi awọn Fulani ti i ṣe ni. Ṣebi nigba to di olori Naijiria, ohun akọkọ to kọkọ ṣe ni lati fi Ọbafẹmi Awolọwọ jẹ oye to ga julọ ni Naijiria nigba naa, bẹẹ bo ba jẹ iru asiko yii ni, tabi to ba jẹ awọnFulani ti a ni lasiko yii ni, ko ni i fi iru oye bẹẹ fun Awolọwọ laye, nitoriawọn Fulani ode oni ri awọn eeyan to ku ni Naijiria bii ẹru wọn ni.

Shagari ko ṣe bẹẹ, ọgbọn ori ti fi han an pe ko si ijọba kan ti yoo waye lorilẹ-ede Naijiria ti yoo gbe ẹya tirẹ lori awọn ẹya to ku ti ijọba bẹẹ yooniyanju. Bi ijọba bẹẹ ba ṣe daadaa fun igba diẹ, to ba ya, yoo di ijọbaburuku ni, ko si ni i wulo fẹnikan. Bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan bii Umaru Dikko ati awọn mi-in lẹyin Shagari gbiyanju lati fi ọrọ awa la ni Naijiriaṣejọba wọn, bi ọrọ naa ba ti de etigbọọ  Shagari, yoo pana ẹ kia ni. Gbogbo wọn pata lo si yatọ si Buhari ti a ni loni-in yii, gbogbo ọna pata lo fi jinna si i. Awọn Buhari yii fẹẹ fi ipa gba ilẹ onilẹ, wọn fẹẹ fi ipa gba ohun-ini ẹlomi-in fawọn Fulani, bẹẹ iyẹn ko si ninu ọrọ tabi iṣe Shagari, bo ṣe fẹ kawọn Fulani jẹ ki wọn yo, bẹẹ naa lo fẹ ki gbogbo Naijiria jẹki wọn yo, nitori ọrọ ilẹ baba wọn ni. Lasiko ti Shagari fi n ṣejọba, bi iya ba jẹ iran kan tabi ẹya kan ni Naijiria, awọn eeyan iran naa lo ko o ba wọn.

Lasiko ti Shagari n ṣejọba yii, asiko naa ni wọn da ileeṣẹ tẹlifisan Eko silẹ, ijọba Jakande lo gbe e jade. LTV Channel Five (Channnel 5), ni wọn n jẹ nigba naa, lẹsẹkẹsẹ ti Jakande si ti ṣeto naa ni ileeṣẹ naa ti bẹrẹ iṣẹ. Ki lo bẹrẹ iṣẹ si ni, bi awọn ọmọ Yoruba ti wọn wa ninu ẹgbẹNPN igba naa ṣe gbogun ti Jakande ree. Olu Adebanjọ (Ki i ṣe Baba Ayọ Adebanjọ o) ni oludamọran pataki fun Shagari lori ọrọ igbohun-safẹfẹ nigba naa, Olu lo si ko awọn eeyan rẹ jade pe ki wọn gbegi dina fun LTV, ki wọn ma gbọ ọrọ rẹ mọ lae. Bẹẹ lo jẹ bi redio naa ba ti bẹrẹiṣẹ bayii, wọn yoo da a ru ni, ẹnikẹni ko si ni i gbohun wọn mọ, nitori gbogbo agbara igbohun-safẹfẹ lori tẹlifisan, NTA to jẹ ti ijọba apapọ lo ni in. Kia ni wọn ti gbe NTA 2 Channel Five jade, wọn si n lo aaye LTV to jẹ tẹlifisan Eko, ọmọ Yoruba yii lo si wa nidii eto gbogbo.

Jakande ko ba ọmọ Yoruba naa sọrọ, o wa aaye lati ri Shagari funra rẹ, koda, ko sọ fun Awolọwọ to fi lọ. Lọjọ to ri Shagari, to si ba a sọrọ, to ṣalaye ohun ti awọn eeyan rẹ ṣe foun, lọjọ naa ni wọn da ileeṣẹtẹlifisan yii pada. Shagari paṣẹ pe ki wọn fun Jakande ni Channel mi-in, iyẹn ni wọn fi fun wọn ni Channel 8 ti wọn n lo titi doni yii. Igba kanwa ti awọn eeyan fẹẹ ro pe Jakande n ṣiṣẹ fun Shagari ni, nitori ọrẹ to wa laarin wọn, bo tilẹ jẹ pe ọmọ Awolọwọ ni Jakande, UPN ni, NPN si ni Shagari i ṣe. Sibẹ, wọn mọ ọwọ ara wọn, ko si di eto oṣelu wọn lọwọ. Iru olori bẹẹ la fẹ ni Naijiria, olori to le ṣejọba ilẹ yii i ti ko ni i fi tiẹya rẹ ṣe. A ko fẹ olori bii iru awọn Buhari yii, ẹni ti ko ronu ohun meji ju Fulani lọ, bẹẹ ki i ṣe ọmọ Sokoto o. Ki Ọlọrun tẹ Shagari si afẹfẹrere, olori Naijiria to ṣe daadaa niwọnba  to le ṣe ni.

 

(82)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.