N’Ifẹtẹdo, Princewill fipa ba Esther lo pọ, lo ba foju bale-ẹjọ

Spread the love

Alabi Princewill, ọmọ ọdun mọkandinlogun, lo ti balẹ sile-ẹjọ Majisreeti ipinlẹ Ọṣun kan to kalẹ siluu Ileefẹ lori ẹsun pe o fipa jẹran sunkun-si ọmọbinrin kan ti wọn jọ n gbe adugbo.

Yatọ si Princewill ti ọwọ tẹ, awọn ọlọpaa ṣi n wa afurasi keji, Ṣẹyẹ Akinyọade, ti wọn lo n ya fidio ibi ti Princewill ti n fi tipatipa ba ọmọbinrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Adenda Esther lo pọ.

Sajẹnti Bassey Asukwo, agbefọba to n gbọ ẹjọ naa, sọ nile-ẹjọ pe lọjọ kẹjọ, oṣu kẹjọ, ọdun yii, ni Princewill huwa naa ni nnkan bii aago mọkanla alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun lagbegbe Oke-Alaafia, Ifẹtẹdo, nijọba ibilẹ Guusu Ifẹ.
Asukwo ni niṣe ni Princewill ati Ṣẹyẹ gbimọ-pọ lati huwa idojuti naa, eleyii to lodi, to si nijiya nla, labẹ abala ọtalelọọọdunrun ati ẹẹdẹgbẹta o lẹ merindinlogun iwe ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ọṣun.
Nigba ti akọwe kootu ka awọn ẹsun mejeeji to ni i ṣe pẹlu ifipabanilopọ ati iwa ipa ti wọn fi kan olujẹjọ si i leti, o ni oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Agbẹjọro fun olujẹjọ, Ọgbẹni Ben Adirieje, parọwa sile-ẹjọ lati faaye beeli silẹ fun olujẹjọ. O ni gbogbo igba tile-ẹjọ ba ti ni ko wa ni yoo maa wa, bẹẹ ni yoo fi awọn oniduuro ti wọn lorukọ silẹ.
Ṣugbọn nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ A. A. Olowolagba sọ pe oun ko le faaye beeli silẹ fun olujẹjọ latari bi ẹṣẹ to ṣẹ ṣe wuwo to.
O waa sun igbẹjọ siwaju lati le dajọ lori boya olujẹjọ lanfaani si beeli tabi ko ni.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.