Nibo ni Saraki fẹẹ gbe eleyii gba

Spread the love

Awọn ti wọn sọ pe ki Bukọla Saraki sare jade waa du ipo aarẹ ko ran an lọwọ rara. Boya oun funra rẹ lo si ro pe okiki oun ti to bẹẹ ni, oun nikan lo ye. Ni bayii, owo ti jona, okiki naa ti lọ silẹ, oun naa yoo si ri i pe apọnle ati iyi ti oun ni laarin awọn aṣofin yoo dinku jọjọ. Ọpọ awọn aṣofin yii ni wọn n tẹle e nitori ipo to wa, ati aibaaamọ boya yoo di ondupo aarẹ lorukọ PDP loootọ, ṣugbọn nigba ti ohun gbogbo ti bọ ralẹ bayii, ohun ti awọn EFCC ati awọn agbofinro to ba ku yoo ba a po ko ni i jẹ kekere rara, bi wọn ba si n ba a po o bẹẹ, yoo ṣoro ko too rẹni ti yoo waa gbeja oun. Bẹẹ bo ba ṣe pe ile-igbimọ aṣofin rẹ lo jokoo si jẹẹjẹ, to mu un girigiri, to duro pe ipo olori awọn aṣofin ti oun wa yii, oun yoo fi yi nnkan pada, gbogbo ilu ni yoo wa lẹyin rẹ, bi awọn Buhari ba si yọ ọwọ kan si i, awọn araalu ni yoo pariwo le wọn lori pe ki wọn fi Saraki silẹ, ki wọn jẹ ko ṣe iṣẹ rẹ to n ṣe. Ṣugbọn ni bayii, Saraki ti fi ara rẹ han bii ẹni to n wa gbogbo ọna lati wa nile ijọba, ati pe tara tirẹ lo n ja fun ki i ṣe ti ilu, bẹẹ ni ko si ohun to wa lọkan rẹ bii ko di olori Naijiria, ko le maa ri nnkan mu jẹ. Kwara to ti wa paapaa yoo le diẹ fun un, nitori niṣe ni inu awọn eeyan bii Lai Muhammed yoo maa dun bayii, wọn mọ pe agbara gidi kan ko si lọwọ rẹ mọ, nitori ko si ohun to sọ pe ki EFCC tabi ọlọpaa ma halẹ mọ ọn mọ. Afi ki ọkunrin naa tun ara mu gidigidi bayii, bi bẹẹ kọ, awọn ajalu kan yoo sare re lati oke lẹnu ọjọ mẹta yii, ko yaa ṣọra ko ma jẹ ko re lu oun ni o, nitori bo ba fi le re lu u pẹnrẹn, ibi ti yoo ti ba ara rẹ ko ni i dara. Ba a kuku tiẹ ti n wi yii, awọn kan ti n sọ pe ori awọn ara Kwara lo mu un, wọn ni owo awọn to ko jẹ lo n fiya jẹ ẹ, bo ba jẹ bẹẹ, ko sẹni to le sọ, ṣugbọn oun ni ko ṣọra rẹ, ko ma jẹ ki epe aye kan moun o.

(76)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.