Nibo ni Jagaban ti rowo naa, owo ta ni o!

Spread the love

Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti sọrọ kan ti yoo ya gbogbo eeyan lẹnu lọsẹ to kọja yii. Igba to n mu Alaaji Oyetọla kaakiri gẹgẹ bii ẹni ti yoo gba ipo lọwọ Gomina Raufu Arẹgbẹṣọla lorukọ ẹgbẹ wọn lo sọ awọn ọrọ kan niwaju awọn ọba, ọrọ naa si ti di ohun to n ja ran-in ran-in kaakiri ilu. Tinubu ni wọn n pariwo pe oun fẹẹ ko owo jẹ ni, oun fẹẹ fi eeyan si Ọṣun lati le maa ko owo wọn wa foun l’Ekoo ni. O ni bo ba jẹ owo ni, Eko ni Oyetọla yoo wa, nitori Eko ni owo wa, ko si si iye ti wọn n wa l’Ekoo ti awọn ko ni i ri. Ati pe lọna keji, o ni Ọṣun lapapọ ko ni owo to wa lọwọ oun. “Kabiyesi, ẹ jẹ ki n sọ fun yin, to ba jẹ ti owo ni, ẹ ko lowo temi lọwọ o!” Ohun ti eyi tumọ si ni pe ko si owo kan ti awọn ara Ọṣun ni to to ti oun Jagaban, oun lowo ju gbogbo apapọ Ọṣun lọ. Loootọ awọn ti wọn wa nibẹ patẹwọ popo, ṣugbọn nigba ti ọrọ yii jade, ọtọ ni ohun ti awọn araalu n sọ. Wọn ni bi Jagaban ba fi le lowo lọwọ ju odidi ipinlẹ kan lọ, iṣẹ wo ni Jagaban ṣe ko too di olowo to bẹẹ, ọpọ awọn eeyan ti wọn mọ ọn ni ọdun 1999 ko too ṣe gomina Eko mọ pe ko ni owo kan ti yoo fi yangan, wọn mọ pe ki i ṣe olowo rẹpẹtẹ kan nigba to waa gba iṣẹ oṣelu nilẹ Yoruba nibi. Ati pe awọn ti wọn wa ni Ọṣun ti wọn mọ bi Arẹgbẹṣọla funra rẹ ti ṣe ijọba rẹ si mọ pe ọkunrin naa ki i ṣe angẹli bi ọrọ ba di ọrọ owo, wọn mọ pe owo n sonu loorekoore ni. Ṣebi Aṣiro-owo agba ipinlẹ naa ṣẹṣẹ kọwe fi iṣẹ rẹ silẹ bayii nitori ọrọ owo kan ni, owo nla ti iye rẹ to biliọnu mẹrindinlogun, ibẹru pe bi owo naa ṣe poora le jẹ ki awọn EFCC maa wa oun kiri lo jẹ ko sa lọ bẹẹ. Eyi fihan pe ki i ṣe pe ọwọ awọn ti wọn n ṣejọba yii mọ to bẹẹ ju bẹẹ lọ, gbogbo wa lole bi ilẹ ba da ni wọn n ba kiri. Ṣugbọn pẹlu bi iṣẹ ati oṣi ṣe pọ to kaakiri ipinlẹ yii, ti gbese nla naa si pọ, bii ẹni to n ba awọn eeyan naa ninu jẹ ni bi Tinubu ba jade wa, to si n sọ pe oun lowo ju apapọ gbogbo ipinlẹ Ọṣun lọ. Iṣẹ ki loun naa ṣe, nibo lowo bẹẹ ti wa, ki lo ta, igba wo lo si di olowo? Ṣebi iṣẹ oṣelu yii naa ni, ko si si iṣẹ mi-in ti a mọ aṣiwaju oloṣelu yii mọ. Ko si ohun to buru bi eeyan ba ṣiṣẹ rẹ to ba lowo lọwọ, ohun ti ko dara ni ki eeyan sin araalu ki owo rẹ waa ya mura, ko si maa fi owo naa ṣakọ si wọn. Ọlọrun nikan ni yoo gba wa lọwọ awọn oloṣelu Naijiria, awọn ti wọn n rẹ wa jẹ ti wọn fi n han wa, awọn ti wọn n sọ fun wa pe a gọ, a ko lọgbọn lori, awọn ti wọn n sọ fun wa pe ko si ohun ti a le ṣe fun awọn. Ọlọrun o, waa gba wa lọwọ wọn.

(102)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.