Nibo ni iku Baba yeye paapaa wa?

Spread the love

Asiko yii ki i ṣe asiko ti Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, Alaafin Ọyọ, gbọdọ dakẹ. Bo ba ṣe pe ija kan ṣoṣo yii ni Alaafin ja fun wọn ni ipinlẹ Ọyọ, titi aye ni wọn yoo maa ranti rẹ. Bi Alaafin ko ba ja ija naa, nigba ti wahala ọrọ yii ba de lọjọ iwaju, wọn yoo maa sọrọ Alaafin, wọn yoo ni baba naa wa nibẹ ti awọn Fulani fi waa gba ilẹ, wọn yoo ni ko sọrọ nitori oun naa lọwọ si i. Ẹni to ba fẹ oore fun ipinlẹ Ọyọ, ti ko fẹ wahala kan fun awọn eeyan ibẹ, ko ni i sọ pe ki wọn da Abule Onimaaluu, nibi ti awọn Fulani yoo ti maa sin maaluu silẹ nibẹ. Kinni naa ko daa ni, ko ba ofin mu, bẹẹ ni awọn eeyan naa ki i ṣe ẹni ti ilu kan gbọdọ faaye gba ki wọn mule ti awọn. Wọn yoo da wahala silẹ gbẹyin ni, wọn yoo mura lati pa awọn eeyan ibẹ ki wọn si sọ ibẹ di tiwọn ni. Wọn ko ni i ṣiṣẹ, wọn ko ni i ṣe nnkan mi-in, ko si sowo ti ijọba apapọ yoo fun wọn, afi ti wọn ba fi maaluu wọn jẹ oko oloko. Bi ẹnikẹni ba si sọ pe oun ko mọ pe gbogbo ohun ti wọn n ṣe yii, wọn n ṣe e nitori pe Buhari to jẹ Fulani lo wa lori ijọba ni, a jẹ pe tọhun ko ni i gbọn laelae. Bi ọrọ ba ti waa da bayii, gbogbo agbara ti eeyan ba ni loun naa yoo lo, lati ri i pe awọn abatẹnijẹ kan ko mu ile ti oun. Iyẹn ni Alaafin ṣe gbọdọ jade o, ki wọn ri gomina, ki wọn si pariwo ọrọ naa saye pe awọn ko fẹ abule onimaaluu lọdọ awọn, bi a ba fẹẹ da abule maaluu silẹ, ijọba ati awọn eeyan ipinlẹ naa yoo ṣe e funra wọn, a ko fẹ ti ijọba apapọ, nitori oore to mu wahala dani ni. Ki Alaafin pe gbogbo awọn ọba ipinlẹ Ọyọ jọ, ẹnikẹni ko gbọdọ fun ijọba Buhari ni ilẹ lati waa fi da abule maaluu silẹ. Tabi kin ni wahala to wa ninu ọrọ yii, kin ni wọn n fi ilẹ to wa ni Sokoto, Zamfara ati awọn agbegbe ilẹ Hausa to ku ti ko si eeyan nibẹ ṣe. Bo ba mu wọn lara, ki wọn lọọ da ilu maaluu silẹ lawọn ibi wọnyi, ki wọn si maa fi reluwee ko wọn wa si ọdọ tiwa lati ta wọn, abi iṣoro tun wa ninu iyẹn ni. Ṣugbọn wọn ko ni i ṣe bẹẹ, nitori ki i ṣe maaluu gan-an ni wọn fẹẹ waa ta, wọn fẹẹ gba ilẹ wa fun Fulani ni. Alaafin, dide! Iṣẹ nla kan lo delẹ yii o, ipa ti kaluku ba si ko nibẹ, titi aye la oo maa sọ ọ o.

(148)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.