Nibo lẹyin n gbe, nibo lẹyin wa: Nigba ti wọn sọ pe awọn ṣọja tẹni kan ko mọ (Unknown Soldiers) ni wọn dana sun ile Fẹla

Spread the love

Meji ni ọrọ naa pin si. Awọn kan n beere pe ki lawọn ṣọja fẹẹ ṣe fun Fẹla Anikulapo Kuti gan-an. Wọn ti sun ile rẹ, wọn si ti sun irin-iṣẹ to fi n ṣere, lati igba ti ọrọ naa si ti ṣẹlẹ, ọkunrin naa ko ti i raaye lọọ ṣere nibikibi. Ṣebi ẹni to ba tilẹ gbadun ni yoo lọọ ṣere, tabi ẹni to ba ni irinṣẹ ti yoo fi ṣe iṣẹ aje rẹ ni yoo ni oun n lọọ ṣiṣẹ nibi kan. Ko si irinṣẹ, ko si owo, ko si alaafia, Fẹla ko le de ibikan kọrin. Yatọ si eleyii, gbogbo ilẹkun ile Fẹla naa ni wọn ti ti pa, wọn ni wọn ko ni i ṣi i titi ti wọn yoo fi pari iwadii wọn tan. Ohun tawọn kan ro ni pe ọjọ ti igbimọ to n wadii ọrọ yii wa sile Fẹla ni wọn yoo ṣi ile naa silẹ fun wọn, ṣugbọn wọn o ṣe bẹẹ. Iyẹn lawọn ti wọn yi i ka ṣe n beere pe kin ni wọn fẹẹ ṣe fun Fẹla, tabi iran Fẹla ti ṣẹ Ọgagun Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni ẹṣẹ kan tẹlẹ ni, nigba to jẹ ọmọ ilu Abẹokuta kan naa ni wọn jọ n ṣe.

Ohun ti awọn mi-in n beere yatọ siyẹn, awọn n beere pe kin ni Fẹla yoo ṣe fun awọn ijọba yii, kin ni Fẹla yoo ṣe fun Oluṣẹgun Ọbasanjọ ati awọn ṣọja ti wọn yi i ka gbogbo. Awọn wọnyi mọ Fẹla, wọn si mọ pe ki i gbọ, ki i gba loun naa, pe alagidi kan ti ko kọ ko ku sidii ohun to ba ti mọ pe ẹtọ ni. Awọn ti wọn mọ ọn ni wọn n sọ bẹẹ, wọn ni awọn mọ pe bo ba jẹ ti ka ja fun ẹtọ awọn eniyan, tabi ka ba ijọba fa wahala nitori mẹkunnu, wọn ni ọkunrin Fẹla yii ko ni i gba, ko si ni i kọ ohun yoowu to ba ṣẹlẹ soun. Wọn ni Fẹla yoo ba ijọba awọn ṣọja yii fa wahala ti ko ni i tan, ohun toju awọn naa yoo si ri, wọn ko ni i le sọ. Ṣugbọn ko sẹni to mọ ọna ti Fẹla yoo gba ṣe gbogbo ohun to ba fẹẹ ṣe fun wọn ati bi yoo ti ṣe e, nigba ti oun naa ko ni ṣọja, ti ko si lọlọpaa, orin nikan lo mọ ọn kọ.

Ko si ohun ti awọn araalu yoo ṣe, ati awọn araalẹ okeere to n fọkan ba ọrọ yii lọ paapaa, ju ki kaluku kawọ gbera lati maa reti ohun ti yoo ṣẹlẹ gan-an lọ, nitori onikaluku lo mọ pe nnkan kan yoo ṣẹlẹ. Awọn igbimọ ti wọn lọọ wadii ọrọ yii, iyẹn igbimọ ti Kalu Anya ṣe olori rẹ, ti lọ si ile Fẹla, wọn ti ṣa gbogbo ẹri ti wọn fẹẹ lo nibẹ jọ, wọn ti ba gbogbo awọn ti wọn fẹẹ ba sọrọ sọrọ, wọn si ti pada si ibujokoo wọn ni National Theatre, Iganmu, wọn tubọ gbọ ọrọ lẹnu awọn bii meji mẹta mi-in si i. Lẹyin ti wọn ti gbọ ọrọ lẹnu awọn eeyan naa tan, wọn ka ijokoo wọn nilẹ, wọn ni awọn ko fẹ araata mọ, ko si sẹni to ri wọn. Ohun to ku ti gbogbo aye si n reti ni esi ti igbimọ naa yoo mu jade wa, iyẹn abajade gbogbo iwadii wọn. Abajade iwadii yii ni wọn yoo gbe fun ijọba, iyẹn naa ni ijọba yoo si ṣiṣẹ le lori.

Bi ko ba si abajade yii, ko si ohun ti ẹnikẹni le ṣe, ati ijọba, ati awọn Fẹla. Loootọ ọrọ naa ti wa nile-ẹjọ lọtun-un losi, ṣugbọn awọn adajọ paapaa n fẹsẹ kan duro de ohun ti awọn ti wọn wadii ọrọ naa yoo gbe jade. Iwadii ti wọn ṣe yii ati ọrọ ti wọn ba gbe jade sita ni awọn adajọ naa yoo fi mọ awọn ti wọn dana sun ile Fẹla loootọ, nitori awọn mi-in ti wọn lọ siwaju igbimọ yii lati sọrọ le sọ pe awọn ko ni i de iwaju awọn adajọ tabi lọọya kan, awọn ko ni ẹjọ ti awọn fẹẹ ba wọn ro, awọn ko si ṣetan lati ṣe ẹlẹrii ijọba. Nipa bẹẹ, ẹri to peye le ma to niwaju awọn adajọ yii, awọn naa yoo si maa fi atamọ mọ atamọ lasan, ojulowo ẹjọ ati ọpọ irọ tawọn lọọya ba kọ kalẹ nikan ni wọn yoo gbọ. Iyẹn lawọn naa ṣe n duro. Ka ṣa sọ pe lori ọrọ Fẹla yii, gbogbo aye lo n duro de igbimọ Anya, wọn fẹẹ mọ ohun ti wọn ri gan-an.

Kinni kan tilẹ waa wa, iyẹn ni pe awọn eeyan ti mọ ibi ti igbimọ Anya yii fi si, kaluku ti n fọkan ronu ohun ti igbimọ naa le ṣe, tabi ti wọn le sọ jade. Idi ni pe ni gbogbo igba ti igbimọ naa fi n ṣiṣẹ wọn, niṣe lo da bii pe ija Fẹla ni Adajọ Anya n gbe, yatọ si igbakeji rẹ to jẹ Hausa ti iyẹn ko mọ ọrọ kan lo le ti a ki i sọ. Adajọ Anya ko ni i binu, bẹẹ ni ko ni i pariwo, ko si si bi ọrọ ti le le to ti ko ni i fi suuru sọ ọ, ti yoo si pẹtu si gbogbo ẹni to ba n binu ninu. Ko si ohun ti Fẹla ati awọn eeyan rẹ fẹ ti ko ni i ṣe, bi wọn ba si ti sọrọ kan ni yoo gba a wọle, ti yoo ni oun ti gbọ. Awọn ọlọpaa ati awọn eeyan ti wọn jẹ ti ijọba lo maa n kanra mọ julọ, agaga awọn ọlọpaa ti wọn ba fẹẹ maa tako Fẹla. Bo ṣe n ṣe yii ti jẹ kawọn ti wọn fẹran Fẹla ro pe ti Fẹla lo n ṣe, afaimọ ko ma si jẹ bẹẹ naa gan-an ni Fẹla ṣe n ronu.

Ni ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹrin, 1977, ni gudugbẹ ja o. Ọjọ ti Anya gbe iwadii rẹ jade. Asiko ti wọn gbe iwadii yii kalẹ, wọn ti kuro nibi ti ọwọ ẹnikẹni ti le to wọn mọ, wọn ko si nibi ijokoo kan ti ẹnikan le ti lọọ halẹ mọ wọn, ọna wọn ti jinna si aarin ilu, ẹni ti yoo ba si de ibi ti awọn ọmọ igbimọ naa wa yoo ṣe ko too jẹ, awọn ọlọpaa ati ṣọja lo ku to n ṣọ wọn kiri. Wọn n ṣọ wọn ko ma di pe ẹnikẹni yoo ṣe wọn ni ṣuta ni, nitori ohun ti wọn ju lulẹ ko dara, ko si si ohun ti awọn ti wọn fẹran Fẹla ko le ṣe fun wọn bi wọn ba ri wọn lasiko ti inu n bi wọn naa. Ṣugbọn wọn ko ṣee ri, wọn ti rin jinna, eyi si fihan pe ijọba ati adajọ yii ti mọ ohun ti wọn fẹẹ ṣe lati ilẹ wa, wọn kan n gbe awọn Fẹla mọra lasan ni. Gbogbo ohun ti Adajọ Anya ati ẹni keji rẹ ri, o jọ pe wọn gba gbogbo ẹ si ẹgbẹ kan ni o, esi iwadii wọn si le koko.

Ohun akọkọ ti wọn sọ to ṣe gbogbo aye ni kayeefi ni pe awọn ṣọja kan ti ẹnikẹni ko mọ (Unknown Soldiers), awọn ṣọja ti wọn ko lorukọ, ti ẹnikan ko si mọ ibi ti wọn ti wa ni wọn dana sun ile Fẹla. Wọn ni ki i ṣe awọn ṣọja lati Abalti Barracks, to ba si jẹ awọn ṣọja lati baraaki yii ni, ki i ṣe gbogbo wọn rara, nitori ko si ọfisa kan, tabi ọga kan to paṣẹ iru rẹ pe ki wọn lọọ dana sun ile Fẹla. Anya ati igbimọ rẹ yii ni ki i tilẹ i ṣe pe wọn dana sun ile Fẹla naa bẹẹ, awọn ṣọja ti wọn lọ sibẹ ṣana si ilẹ kan ti wọn ko jọ sitosi ibẹ ni, ilẹ ti wọn si ko jọ yii waa jẹ ọọkan ibi ti jẹnẹretọ ile Fẹla to n muna sile Fẹla wa, jẹnẹretọ yii lo si kọkọ gbina. O ni bi jẹnẹretọ naa ti gbina, ni awọn mọto kan ti wọn gbe sita naa gbina, ti wọn si bẹrẹ si i fọn gaasi inu wọn jade sita, o ni ohun to jẹ ki gbogbo ile naa pada jo ree.

O ni bi awọn bẹntiroolu to wa ninu awọn mọto yii ti n jo, bẹẹ ni ina naa n kẹ si i, ti jẹnẹretọ si n ṣe tirẹ, ina jẹnẹretọ naa ati tawọn mọto yii lo si sọ ile Fẹla di ahoro, to jo gbogbo mọto ati awọn dukia ti wọn wa nibẹ, ti ko si si ẹni to ri ohun kan mu jade. Adajọ Anya ni awọn ṣọja ti wọn waa jo ile Fẹla yii, awọn ṣọja kan ti ẹnikan ko mọ ni, nitori wọn ki i ṣe lati Abalti, ọpọlọpọ wọn lo jẹ wọn kan n lọ ni titi ni wọn gbọ ariwo hee hee hee, ni wọn ba ya ile Fẹla, ti wọn si ri i pe awọn ṣọja mi-in wa nibẹ, ni wọn ba ni ki awọn kuku ran wọn lọwọ. O ni bi wọn ba fẹẹ mu ẹnikẹni to dan iru eyi wo, awọn ṣọja ti ọrọ ko kan ti wọn ba wọn dana sun ile Fẹla yii ni, nitori awọn ni wọn mọ ohun ti wọn n wa kiri. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe eeyan ko le ri iru awọn ṣọja bẹẹ, nigba ti ko sẹni to mọ wọn, tabi ibi ti wọn ti wa.

Ohun ti eleyii tumọ si ni pe gbogbo fọto awọn ṣọja ti awọn Fẹla ko kalẹ, gbogbo fila awọn ṣọja ati ofarọọlu to ba, gbogbo ẹ ni ko ṣiṣẹ mọ, nitori ohun ti Adajọ naa n sọ ni pe ko si ṣọja to wọle Fẹla, ita ni wọn ti sọna si ile rẹ, awọn ṣọja ti ẹnikẹni ko mọ ni. Bi awọn eeyan ti n ka ọrọ ọkunrin naa ni inu n ru wọn ṣuu, wọn mọ pe ki i ṣe ohun to ṣẹlẹ lo n sọ, wọn mọ pe adajọ naa n jẹ iṣẹ buruku ti ijọba Ọbasanjọ gbe le e lọwọ ni, tabi ko jẹ oun funra rẹ ti koriira Fẹla ati bo ṣe n lo aye rẹ. Ohun ti awọn eeyan n beere ni pe bawo ni Adajọ Anya ṣe le sọ pe oun ko mọ awọn ṣọja ti wọn dana sun ile Fẹla, nigba ti ijọba n ba awọn ọmọ Fẹla ṣẹjọ pe wọn dana sun alupupu, iyẹn maṣinni, ṣọja kan niwaju ile wọn, wọn si lu ṣọja naa, pe ṣọja naa lo lọọ ko awọn ero wa ti wọn fi waa fa wahala nile Fẹla.

Titi di igba ti Anya gbe iwadii rẹ jade yii, ẹjọ ti wọn pe Fẹla ati awọn ọmọ rẹ pe wọn dana sun maṣinni ṣọja yii ṣi wa nile ẹjọ, wọn darukọ ṣọja naa, ki i ṣe pe wọn ko darukọ rẹ, wọn si sọ ibi to ti n bọ ati nọmba maṣinni rẹ, wọn si fẹnu ọrọ jona pe ṣọja yii lo pe awọn ara rẹ wa lati waa ja nibẹ. Bawo ni ọpọlọpọ ṣọja yoo ṣe waa jade pẹlu ibọn lọwọ wọn, ati awọn ohun ija oriṣiiriṣii, ati mọto, to si jẹ ṣọja kan lo wa nibẹ to n kọmandi gbogbo wọn, to n paṣẹ ohun ti wọn yoo ṣe fun wọn, ti adajọ Anya yoo waa sọ pe oun ko gba pe awọn ṣọja to lorukọ, tabi awọn ṣọja ti ẹnikẹni ko mọ lo lọ sile Fẹla, nitori ko si ọga kan to fun wọn laṣẹ. Ọrọ naa ṣe awọn eeyan ti wọn n tẹle ọrọ yii ni kayeefi, kaluku si n mi ori rẹ pe bawo ni adajọ yii waa ṣe ṣe yii, adajọ ti awọn ti fọkan tan tẹlẹ pe eeyan gidi ni. O wa ṣe ṣe bayii!

Adajọ Anya o kuku tiẹ ti i sinmi. O ni gbogbo ariwo ti Fẹla ati awọn ọmọ rẹ n pa pe wọn fi tipatipa ba awọn sun yẹn, pe awọn ṣọja n ki awọn ọmọbinrin mọ inu yara wọn n reepu wọn nigba ti wọn n ṣe iṣẹ aburu wọn, adajọ naa ni ko sọrọ nibẹ rara. O ni gbogbo oju abẹ awọn ọmọbinrin naa ti wọn n fihan pe awọn ṣọja lo ri nnkan mọ awọn labẹ nibẹ ko le jẹ bẹẹ, ohun to le ṣẹlẹ ni pe nibi akọlukọgba to n lọ nigba naa ni wọn ti farapa, igba ti wọn si farapa ti wọn ko mọ ohun ti wọn yoo wi ni wọn ṣe n sọ pe awọn ṣọja lo fipa ba awọn sun. O ni ohun to tun le ṣẹlẹ ni pe ko jẹ nigba ti awọn ṣọja naa fẹẹ mu awọn ọmọ wọnyi, wọn yari pe ọlọpaa kan ko le mu awọn, tabi ki wọn ni ṣọja kan ko le mu awọn, gẹgẹ bi ọga wọn naa ṣe ṣe, iyẹn ni ọrọ si fi dija rẹpẹtẹ, ko too di pe awọn ọmọbinrin naa fi ara pa.

Bayii ni ọrọ Adajọ Anya tun tako ara wọn. Ẹni to ni oun ko gba pe awọn ṣọja wọ ile Fẹla, to ni oun ko gba pe wọn debẹ rara, oun naa lo tun ni awọn ọmọ Fẹla n ba awọn ṣọja ja, wọn ko fẹ ki wọn mu wọn, wọn n ṣagidi pẹlu wọn bi ọga wọn ṣe ṣe, iyẹn ni wọn ṣe fara ṣeṣe, ti abẹ wọn si fi n ṣẹjẹ! Ewo ni eeyan yoo gbagbọ ninu ọrọ adajọ yii o, ohun ti awọn eeyan n wi niyẹn. Tabi adajọ to sọ pe awọn ṣọja ko wọle, ṣọja ti ẹnikan ko da mọ ni wọn, to tun sọ pe wọn n ṣe agidi nigba ti wọn fẹẹ mu wọn. Adajọ Anya si mọ pe nigba ti wọn mu awọn eeyan yii o, ti wọn mu Fẹla ati iya rẹ ati awọn ọmọ rẹ, baraaki Abalti ni wọn ko wọn lọ, ti wọn sa wọn sinu oorun ni gbangba, ti awọn ṣọja duro ti wọn tibọn-tibọn lọwọ wọn, ti wọn n ṣọ wọn, ti wọn si n sọ pe eyi to ba ṣagidi, wọn yoo yinbọn pa a.

Lati inu ọgba Abalti yii, lẹyin ti wọn ti wa nibẹ fun igba pipẹ ni awọn ọga kan ṣẹṣẹ de ti wọn waa ni ki wọn ko wọn lọ si ọsibitu, nibi ti wọn ti ṣe itọju wọn. Adajọ Anya ko lọ si baraaki Abalti, awọn ṣọja ko waa jẹjọ ọrọ naa, oun kan jokoo si Iganmu, nibi ti wọn ti n ṣewadii yii, o n ko irọ tawọn eeyan ati ijọba pa fun un jọ ni. Ọrọ yii loun si gbe jade lai si ibẹru Ọlọrun kan nibẹ rara. Adajọ yii ni oun ko ri ṣọja kan ti oun le bu, tabi ti oun le mu si ọrọ yii, nitori awọn ko mọ ṣọja to huwa naa, awọn ko mọ ibi ti wọn n gbe tabi ibi ti wọn ti wa. O ni iwadii oun ti fihan pe ọpọ awọn ṣọja baraaki Abalti ni ko tilẹ si nile lọjọ naa, to jẹ wọn ti ba iṣẹ ijọba lọ, igba ti awọn naa de ni wọn n gbọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ, ohun ti oun si fẹẹ mọ ni bi awọn ti wọn ko si nile yoo ṣe fajangbọn to to bẹẹ yẹn, ti wọn yoo si dana sunle.

Related image

Ṣugbọn Adajọ Anya tu aṣiri ara rẹ ninu iwe to kọ sijọba. O ni ọrọ to ṣẹlẹ yii o, ko si ẹni meji ti awọn ri ba wi, ko si ẹni meji ti awọn le bu ju awọn ọlọpaa lọ. Adajọ yii ni awọn ọlọpaa ni ko ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ rara. O ni bo ba jẹ wọn ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ ni, wọn yoo ti mọ pe iru Fẹla ati awọn ọmọbinrin rẹ yẹn ko yẹ ki wọn wa laarin igboro, wọn yoo ti mọ pe Fẹla ati awọn ọmọ ti wọn n ba a kọrin ti wọn n gbe ile rẹ yii ko yẹ lẹni to gbọdọ wa nitosi ibi ti ọpọ eeyan n gbe, nitori nibi ti wọn ba wa, wọn ko ni i fun ibẹ ni alaafia kan. O ni awọn ni wọn n wo Fẹla ni gbogbo igba to n gun kẹtẹkẹtẹ kiri ilu, to n lu awọn alaiṣẹ, ti awọn ọmọ rẹ n huwa ipanle laarin ilu, ti wọn n fiya jẹ awọn araalu, ti wọn ko si wi kinni kan fun wọn. O ni awọn ọlọpaa yii ko le wi kinni kan, nitori awọn naa kuku n lọ sile Fẹla lati ṣe iranu.

Adajọ Anya ni eyi to tilẹ buru ju ninu iwa awọn ọlọpaa naa ni pe awọn araalu, iyẹn awọn ti wọn n gbe ni agbegbe Idi-Oro ati Mọsalaṣi, gbogbo wọn ni wọn n lọ si ọdọ awọn ọlọpaa lati fẹjọ Fẹla ati awọn ọmọ rẹ sun, ṣugbọn awọn ọlọpaa ko ni i da wọn lohun, kaka bẹẹ, wọn yoo sọ fun wọn pe apa awọn naa ko ka Fẹla ni. O ni eleyii lo sọ Fẹla di ologomugomju, to sọ ọ di aṣẹmalu, to si fi n huwa to n hu laarin ilu, nitori o ti gba pe ko sẹnikan ti yoo mu oun si i. O ni bo ba jẹ awọn ọlọpaa ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ ni, ti wọn tete palẹ Fẹla mọ ni gbogbo igba to ṣẹṣẹ bẹrẹ awọn iwa lile yii, o ni ko ni i si iru ijaagboro to ṣẹlẹ yii, bẹẹ ni ko ni i si ogun a n dana sun ile awọn ẹni ẹlẹni. O ni ọrọ to ṣẹlẹ naa kan awọn eeyan, nitori ki i ṣe ile Fẹla nikan ni wọn dana sun, wọn tun sun awọn ile to wa lẹgbẹẹ rẹ, bẹẹ awọn ti wọn ni ile naa, ki i ṣe ọmọ Fẹla.

O ni ohun ti oun yoo kọkọ sọ pe ki ijọba ṣe ni lati pe awọn ọlọpaa jọ, ki wọn fun wọn ni idanilẹkọọ to ye kooro, idanilẹkọ tuntun lori iṣẹ ti wọn gba, ki wọn mọ bi wọn yoo ti ṣe iṣẹ wọn. O ni ki wọn wadii awọn ọlọpaa ti wọn wa ni agbegbe ibi ti Fẹla n gbe yii wo, ki wọn si mọ ohun ti wọn ṣe ati bi wọn ti ṣe lasiko to fi yẹ ki wọn ti mu Fẹla tipẹ, tabi ki wọn ti kilọ fun un ko tọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ. Adajọ Anya ni ohun tawọn ri niyẹn ni tawọn o, oun naa lawọn si gbe kalẹ, ohun to ba wu ijọba ni ki wọn fi ọrọ naa ṣe.

Bayii ni Adajọ Anya ba ti Fẹla ati idile rẹ, ati awọn ẹgbẹ olorin rẹ jẹ, nitori abajade iwadii rẹ yatọ pata si ohun to ri nibẹ, o si sọrọ naa bii pe ijọba fi si i lẹnu ni, tabi pe oun naa kuku ti ni ikoriira fun Fẹla. Eyi to si ya awọn eeyan lẹnu ju ni pe adajọ naa ko ṣe bayii nigba to n wadii ọrọ, gbogbo alaye to fẹ ni wọn fun un. Ṣugbọn o han pe ko mu alaye naa lo rara, ohun to ti wa ninu rẹ tẹlẹ lo ṣe.

(50)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.