Nibo lẹyin n gbe nibo lẹyin wa, nigba ti: ỌFỌ NLA ṢE ILU IBADAN, GBADAMỌSI ADEBIMPE LO ỌDUN KAN LORI OYE LO BA KU LOJIJI!

Spread the love

Yoruba ni owe kan, iyẹn naa ni pe ilu ki i ṣe ọfọ, itumọ rẹ si ni pe aburu ki i ba gbogbo ilu lẹẹkan naa. Bi wọn ba n ṣe oku ọfọ lapa kan laarin ilu, o le jẹ ikomọ ni wọn n ṣe ni apa keji, ti gbogbo ibẹ yoo si maa dun yungba, o si le jẹ ile ọti ni awọn mi-in wa ti wọn n ṣe faaji ara wọn. Awọn mi-in paapaa le wa ni ọsibitu, ki awọn mi-in wa ni ọna irin-ajo, onikaluku aa si maa ba kadara aye rẹ kaakiri, eyi ni Yoruba ṣe n sọ pe ilu ki i ṣe ọfọ, nitori ohun ti wọn n ṣe tabi to n ṣe wọn ni apa kan ilu ko ni i ṣe wọn ni apa keji. Ṣugbọn owe naa ko ri bẹẹ ni ilu Ibadan ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, ọdun 1977, lọjọ naa ni gbogbo ilu yii ṣọfọ lẹẹkan. Ati awọn ti wọn wa nile ni o, ati awọn ti wọn wa loko ni o, ati awọn ti wọn wa lọna ajo, ko si ọmọ Ibadan kan to wa nibi kan ti ọfọ naa ko kan, afi bii igba pe ọmọ kekere kan lo ku.

Bẹẹ Ọba Gbadamọsi Akanbi Adebimpe ki i ṣe ọmọde, koda, o pe ọmọ ọgọrin ọdun, nitori ọdun 1893 ni wọn ti bi i, ko too waa ku ni 1977, ṣugbọn ohun to n dun awọn eeyan ju ni pe ninu itan Ibadan, ọkan ninu awọn ọba ti ko pẹ lori oye rara ni Ọba Adebimpe i ṣe. Ibeere ti gbogbo eeyan n bi ara wọn naa ni pe bawo ni eeyan yoo ṣe jọba lọdun to kọja, ti yoo si ku lọdun yii, iru iku wo niyẹn! Ọba ki i lo ọdun kan lori oye, bii ogun ọdun, bii ọgbọn ọdun, bii ogoji ọdun, bii aadọta, awọn ọba mi-in paapaa n lo ju ọgọta ọdun lọ. Eyi naa lo di iyanu ati ẹdun-ọkan, pe ki lo de ti ọba to jẹ ni 1976 ti sare ku ni 1977, agaga nigba to jẹ Ọba Shittu Oyetunde to jẹ ki oun too jẹ, ọdun mẹrin pere loun naa lo, ọrọ naa si di nnkan laarin ilu pe ki lo n ṣe awọn Olubadan ti wọn n ku tuẹtuẹ bayii, ṣe ki i ṣe pe awọn ọba naa n lo nnkan funra wọn.

Ọrọ naa lo di ahesọ agbekiri nigba naa pe bi eeyan ba ti jẹ oye ọba Ibadan, bii pe wọn dajọ iku fun un ni. Ṣe loootọ, lati ọdun 1946 titi di 1976, yatọ si Ọba Isaac Akinyẹle to lo ọdun mẹsan-an lori oye (1955-1964), ko tun si Olubadan kan to lo ọdun marun-un pe nipo, bii ki wọn lo ọdun kan, meji, mẹta si mẹrin ni. Ni 1946 yii ni Ọba Oyetunde akọkọ jẹ, ṣugbọn ọdun naa gan-an lo dẹni agbegbin. Wọn tun fi Akintunde Bioku jẹ Olubadan ni 1947, oun naa si waja ni 1948. Ọba Fijabi Keji pẹ diẹ lori oye, o joye ni 1948 o si dẹni ẹbọra n ba jẹun ni 1952, oun lo ọdun mẹrin. Ọba Mẹmudu Alli-Iwo to jẹ Olubadan ni 1952, 1952 naa lo wọ kaa ilẹ lọ. Ọba Igbintade Apẹtẹ to jẹ Olubadan ni 1952 lo lo ọdun mẹta, nitori 1955 loun bẹrẹ si i ba awọn ara ọrun jẹun. Lẹyin naa lo kan Ọba Akinyẹle, ṣugbọn Ọba Yesufu Kobiowu to jẹ lẹyin Akinyẹle ni 1964, ọdun naa gan-an lo ba ilẹ lọ.

Ọba Salawu Akanbi Aminu lo tayọ ọdun marun-un diẹ, o jẹ ni 1965, wọn si kọ ile-ẹlẹsẹmẹfa fun un ni 1971, ki wọn too waa fi Shittu Oyetunde jọba ni 1972, toun naa si di ẹni akọlẹbo ni 1976. Bi oun si ṣe dagbere faye ni wọn fi Akanbi Adebimpe jẹ Olubadan ninu oṣu keji, ọdun 1976. Lasiko ti oun si jọba yii, ijọba awọn ṣọja ti fẹsẹ mulẹ, oriṣiiriṣii idagbasoke lo ti wa, oju awọn eeyan si ti la daadaa. Ko sẹni to beere ọjọ ori rẹ, wọn o tilẹ ranti. Ohun ti awọn eeyan ṣa mọ ni pe Olubadan mi-in ti jẹ. Pabambari tun waa ni pe awọn kinni kan ṣẹlẹ laye Olubadan yii ti ko ṣẹlẹ ni ilu naa ri, igbega ti Ibadan si ri laarin ọdun kan tayọ ohun ti eeyan le deede royin soju iwe kan. Iyẹn lawọn eeyan ti ṣe waa gbọkan tẹ Olubadan Adebinpe, wọn ni gbogbo ire Ibadan to ti lọ, asiko rẹ ni yoo pada s’Ibadan, afi bi ina ọba naa to n jo lọwọ ṣe ku pii!

Bẹẹ ki i ṣe pe ooṣa kan wa to n pa Olubadan nigba naa, tabi pe kinni kan wa laafin wọn ti ki i jẹ ki wọn tọjọ. Ọjọ ori lo n fa iku wọn ki i ṣe ẹnikan. Ipo ọba Ibadan yatọ si ti ọpọlọpọ eto ifọbajẹ ni ilẹ Yoruba, nitori lọdọ tiwọn, ọba jijẹ ki i mu ija dani rara. Bi ẹni kan ba n jẹ ọba lọwọ, ẹni to kan ti mọ pe oun lo kan, nitori wọn n to kinni naa lẹsẹẹsẹ ni. Nigba ti Olubadan kan ba waja, Ọtun Olubadan to ba wa nipo naa ni yoo jọba, Osi Olubadan yoo si bọ si ipo Ọtun Olubadan to di ọba yii, nijọ ti Olubadan tuntun yii naa ba si tun dagbere faye, Ọtun rẹ ni yoo gba ipo ọba. Bi wọn ti n ṣe kinni naa lati ayebaye niyi, o mu eto naa rọrun, iyẹn ni ki i ṣe i si ariwo kan nidii oye Ibadan, ẹni ba kan ti mọ pe oun lo kan, ko ni ariyanjiyan ninu rara.

Ṣugbọn ki eeyan too de ipo Osi Olubadan, tabi ko too di Ọtun, irin-ajo kekere kọ rara, nitori lati agboole wọn ni ọrọ oye naa yoo ti bẹrẹ, Mọgaji ile wọn ni yoo kọkọ jẹ ko too bẹrẹ si i jẹ oye Olubadan, ti wọn yoo si maa sun un siwaju diẹdiẹ. Ọpọ oloye ki i de ipo karun-un ti wọn yoo fi dagbere faye, nitori irin-ajo naa maa n le ni ogoji ọdun, tawọn mi-in si maa n le ni aadọta. Eyi lo ṣe jẹ pe ko wọpọ ki eeyan too ri Olubadan to jẹ ọmọ ọgọta ọdun, tabi to jẹ ọmọde to kere ju bẹẹ lọ. Ọjọ ori Olubadan to ba kere ju gbọdọ ti to ọmọ aadọrin (70) ọdun, marundinlọgọrin, tabi ko tun ju bẹẹ lọ. Meloo meloo ni Olubadan to ti le ni ọmọ ọgọrin ọdun ki wọn too de ipo ọba, eyi lo dowe pe arugbo lo n jọba ilu Ibadan, oye Olubadan ki i ṣe fawọn ọmọde pinṣinni. Nidii eyi, nigba ti Adebimpe yoo jọba, o ti sun mọ ọgọrin ọdun.

Iyẹn ko ṣe pataki loju awọn eeyan igba naa, nitori aye tuntun ti bẹrẹ, ko si ye wọn pe arugbo lo wa lori oye, orukọ lasan ni wọn n gbọ, wọn si ro pe ẹnikan ti yoo pẹ lori kinni naa ni. Afi bi wọn ṣe fi i jọba ninu oṣu keji, ni 1976, to si dero ọrun ninu oṣu keje, 1977 to tẹle e. Okiki Olubadan yii kan pupọ, nitori awọn ohun to ṣẹlẹ lasiko tirẹ ni. Oun ni Olubadan akọkọ ti yoo de ade sori bayii. Itan ilu naa ni pe baba to ṣẹ wọn ti binu fa ade ti wọn gbe fun un ni Ile-Ifẹ ya, lati igba to si ti fa ade ya ni ọmọ rẹ kankan ki i ti i de ade, nigba to jẹ ko si ọmọọba Ileefẹ ti i ni ade meji, ade kan yii naa ni. Idi niyi ti wọn ṣe n ki awọn ọmọ Ibadan ni “Ọmọ f’ade ya!” Iyẹn ni ọmọọba to fa ade tirẹ ya. Niwọn igba ti oun ti fa ade ti wọn gbe fun un ya, ko sẹni kan to tun reti pe yoo de ade kankan mọ.

Ọrọ naa ko ṣe ẹnikẹni ni kayeefi lasiko to n ṣẹlẹ, abi lasiko ti ilu naa bẹrẹ si i kun, ti wọn ko si ri ade ti wọn n de. Ṣugbọn nigba ti okiki Ibadan kan, to di ilu nla keji to tobi ju ni gbogbo Afrika, to si jẹ olu ilu fun Western Region, ẹnu bẹrẹ si i kun awọn ti wọn n ṣejọba pe ṣe Ibadan ko ni i ni ade ni. Ọba ti ko ba ni ade ki i ṣe ọba gidi kan ti wọn yoo fun lọwọ nibi kan, baalẹ lasan ni. Eyi lo ṣe jẹ pe fun igba pipẹ, abẹ ilu Ọyọ, labẹ Alaafin, ni Ibadan wa, nigba ti ko si ade kan ni Ibadan, to si jẹ awọn ti wọn pada waa di olori ilu naa bii Oluyọle, ọmọ Ọyọ lo pọ ninu wọn. Ọrọ naa ti n lọ labẹlẹ, ti wọn n fa kinni naa mọ ara wọn lọwọ pe lọjọ wo ni Ibadan yoo bẹrẹ si i de ade, lọjọ wo ni wọn yoo fi Ibadan si ipo to tọ si i. Kinni naa ko ṣee ṣe titi di ọdun 1976 yii ti Adebimpe di Olubadan, ti wọn si yanju ọrọ ade Ibadan loju aye rẹ.

O ti jọba tan o, wọn ti ṣe e bi wọn ti n ṣe e, ko too waa di pe wọn bẹrẹ irin lori ọrọ naa, ti Alaafin ati awọn igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ọyọ tuntun igba naa si fọwọ si i pe Ibadan gbọdọ ni ade. Eyi ni ijọba awọn ṣọja igba naa fọwọ si, to si jẹ nigba ti Adebimpe yoo fi lo ọdun kan lori oye, ade Olubadan lo fi ṣe ayẹyẹ ọdun kan rẹ, Olubadan ti di ọba alade. Eyi ni wọn ṣe yi orukọ ilu naa pada, wọn ko ki wọn ni “Ọmọ f’adeya” mọ, wọn si sọ wọn di “Ọmọ t’ade ṣe”, eyi to fi han pe awọn ni ọmọ to n tun ade ṣe. Ṣugbọn eeyan ko ni i peri aja ko ma peri ikoko ti wọn yoo fi se e, ko si bi wọn yoo ṣe ki oriki bẹẹ ti wọn ko ni i fi Adebimpe to kọ gbe kinni ọhun wọlu si i, wọn aa si maa ki Adebimpe bayii pe “Gbadamọsi Akanbi Adebimpe, ọmọ Okeebadan to kọ to loun o jẹ Yade mọ, Adebimpe waa di ọmọ Tadeṣe!”

Bawo leeyan kan yoo ṣe waa gbagbe ọba to gbe ade wọlu, ohun to ṣẹlẹ si Gbadamọsi ree, ti gbogbo aye si n pokiki rẹ kaakiri. Nnkan mi-in tun ṣẹlẹ bẹẹ naa. Ni gbogbo igba ti wọn ti n jẹ Olubadan, iyẹn ko too di ọdun 1976 yii, ko si aafin kan pato tawọn Olubadan n lo, kaluku lo n kọ aafin tirẹ si adugbo rẹ, ibẹ naa ni yoo si wa ti yoo fi maa jọba. Bi Olubadan kan ba ti lowo to, bẹẹ naa ni aafin rẹ yoo ti dara to, nitori ko si aafin kan to jẹ ti gbogbo ilu, ohun to ba wu ọba to jẹ ni yoo kọ laafin, tabi bi apa rẹ ba ti mọ. Ko si sija ni ṣọọṣi ni, ṣadura ki n ṣe amin naa ni, ibi ti wọn ba ti pe laafin ni aafin. Nigba ti Adebimpe yoo si jọba tirẹ, aafin rẹ to ti n lo naa tẹlẹ lo lo, iyẹn nile rẹ, wọn kan tun kinni naa ṣe ni. Odinjo ni. Odinjo yii si ni ọba naa wa to ti n ṣejọba.

Ṣugbọn aafin Olubadan to wa l’Ọjaaba bayii loni-in, aye ọba yii ni wọn bẹrẹ rẹ, oun lo si ṣeto ifilọlẹ rẹ, loju rẹ gan-an lo ṣe. Aafin naa ko pari loju rẹ, koda, wọn ko ti i ba a de ibi kan to fi waja, ṣugbọn o wa ninu itan, o si wa ninu akọsilẹ titi doni pe Akanbi Adebimpe yii lo bẹrẹ ifilọlẹ aafin Olubadan yii, iyẹn lo ṣe jẹ gbogbo ọba to ba n lo aafin naa loni-in ni i maa i ṣejuba Adebimpe Olubadan Ọba. Awọn mi-in aa ni bi ko si tiẹ, Ibadan le ma ti i ni aafin, awọn mi-in aa si sọ pe bi wọn yoo tilẹ ni aafin, o le ma ya to bo ṣe ya nni, ṣugbọn eyi to ṣe pataki ninu itan Ibadan naa ni pe laye Adebimpe ni wọn bẹrẹ Aafin Olubadan, oun si lọba to fi okuta ipilẹ ibẹ lelẹ, eyi lo si di aṣa pe ti Olubadan kan ba ti jẹ, aafin yii naa ni yoo lọọ lo, ko si jẹ dandan ki Olubadan kan tun kọ aafin mi-in funra rẹ mọ, nitori ọba lo laafin.

Titi di ọdun 1976 yii, Naijiria ko gba ife agbaye kan ri, bẹẹ ọdọọdun ni wọn n kopa ninu ere bọọlu, ti awọn eeyan agbaye si n woju Naijiria pe lọjọ wo lawọn naa yoo gba ife-ẹyẹ ti yoo jẹ eyi ti wọn da mọ kaakiri aye. Afi bi kinni naa ṣe ṣẹlẹ ni 1976, lẹyin ti Adebimpe ti jọba. Awọn agbabọọlu gbogbo ni ilẹ Afrika pe jọ, wọn si ṣe idije nla, wọn fẹẹ mọ ẹgbẹ agbabọọlu to dangajia julọ ni gbogbo Afrika. Lati origun mẹrẹẹrin ilẹ Afrika lawọn agbabọọlu naa ti pe jọ, awọn alakooso ere bọọlu ni gbogbo aye naa si ba wọn pe sibẹ, wọn fẹẹ mọ agbabọọlu Afrika to jẹ baba julọ. Ọpọ eeyan ko gbọ orukọ ẹgbẹ agabọọlu kan ti wọn n pe ni IICC ri bo tilẹ jẹ ni gbogbo igba naa, wọn ti n pitu meje ni Naijiria, ti wọn ti n gba ife-ẹyẹ Challenge Cup, ọdun 1976 yii ni wọn ri wọn ni gbangba.

Ọdun yii ni ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria maa gba ife-ẹyẹ agbaye, iyẹn ife-ẹyẹ African Cup, ko si si ẹyẹ meji ti i jẹ aṣa, ẹgbẹ agbabọọlu IICC ti ilu Ibadan ni. Nibi yii ni okiki ti kan kaakiri aye pe ko si ẹgbẹ agabọọlu meji ni Naijiria to ju IICC lọ. Awọn oyinbo gbọ, awọn eeyan dudu gbọ, ijọba Naijiria naa labẹ Ọbasanjọ paapaa si kan saara si wọn. Ṣugbọn awọn alarojinlẹ ni wọn ni o yẹ ki awọn yẹ ọrọ Ọba to wa lori oye wo, wọn ni o yẹ ki wọn wo Gbadamọsi Akanbi Adebimpe yii lẹẹkan si i. Wọn ni o ṣe jẹ asiko tirẹ ni nnkan daadaa daadaa bayii n ṣẹlẹ niluu Ibadan, wọn ni ki lo de to jẹ gbogbo ire ti awọn ko ri lati ọjọ yii wa, asiko Adebimpe yii lawọn n ri i. Nigba naa lawọn ọmọ Ibadan yi orukọ rẹ pada, ti wọn si n pe e ni “Ọba Akorede”, ki i ṣe nitori ohun meji, bi ko jẹ awọn ohun meremere to n waye lasiko rẹ yii ni.

Laarin ọdun kan pere ni gbogbo eleyii ṣẹlẹ o, awọn nnkan kanka kanka mẹta ọtọọtọ, yatọ si awọn nnkan wẹwẹ mi-in to ti n ṣẹlẹ si i. Iyẹn ni ko ṣe si ẹni to gba iku rẹ gbọ nigba ti wọn gbọ, wọn n beere lọwọ ara wọn pe, “Adebimpe wo?”, tabi “Olubadan wo lẹ n sọ?” Nigba ti awọn eeyan si ri aridaju rẹ, ti redio n gbe e, tawọn onitẹlifiṣan n sọ ọ, ti gbogbo iwe iroyin si fọn ọn ka si oju-iwe iroyin wọn, ọrọ naa di ọfọ nla si wọn lara, kaluku ti ko tilẹ mọ ọba naa si bẹrẹ si i sunkun, wọn n beere pe ki lo le ṣẹlẹ, ki lo de ti iku fi mu ẹni daadaa bayii lọ. Niṣe ni awọn ero bẹrẹ si i rọ lọ si aafin rẹ ni Odinjo, wọn fẹẹ mọ boya irọ ni tabi ootọ, awọn ti wọn si ti mọ naa n lọ sibẹ lati lọọ daro ọba daadaa to lọ ni. Kayeefi ni iku rẹ jẹ fun wọn, nitori ko si ẹni to mọ pe bẹẹ lọba naa yoo ti ṣe tete ku, ọba to n ṣe daadaa fun ilu rẹ ni.

Ọjọruu, ọjọ Wẹnẹsidee, ogunjọ, oṣu keje, ọdun 1977, iyẹn lọjọ keji ti ọba naa waja ni wọn gbe e wa si Oke Mapo, wọn ni ki gbogbo aye foju ri i ki wọn too sin in. N lero ba n wọ bii omi, nigba ti ibẹ ko si gbero mọ logunlọgọ ọmọ Ibadan duro sita, wọn ni awọn naa fẹẹ foju kan oku ọba to ṣe daadaa fawọn. Ọrọ naa kan David Jẹmibẹwọn, olori ijọba ologun, bẹẹ ni Oluṣẹgun Ọbasanjọ to jẹ olori Naijiria naa ranṣẹ wa, ko si seeyan gidi kan ti ko ba awọn ọmọ Ibadan daro, wọn ni iku to pa Adebimpe yii ko ṣe daadaa fawọn rara ni. Gbogbo awọn ẹya loriṣiiriṣii ti wọn wa n’Ibadan, Ijẹbu ni o, Ifẹ ni o, Ọyọ ni o, gbogbo wọn naa ni wọn n kọrin ṣedaro Akanbi Adebimpe, kaluku lo si n pariwo pe ọba daadaa ti lọ.

Igba tawọn eeyan yii ṣẹṣẹ gbọ ọjọ ori Olubadan to waja naa ni wọn ṣẹṣẹ gba pe ko si kinni kan to n pa awọn ọba n’Ibadan, ko si nnkan kan to n mu ọba wọn lọ, ọjọ ori awọn ọba naa lo n mu wọn lọ. Ṣugbọn beeyan lo ọdun kan lori oye, iye igba to lo nibẹ kọ ni pataki, ohun to gbe ipo ọba ṣe ni. Iyẹn ni Gbadamọsi Akanbi Adebimpe ko fi ṣee gbagbe fun ọpọ ọmọ ilu Ibadan, wọn ni oun gangan ni “Ọba Akorede!”

(146)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.