Nibo lẹyin n gbe nibo lẹyin wa, nigba ti: AKINTỌLA DA IWE IROYIN SKETCH SILẸ N’IBADAN

Spread the love

Ki Oloye Samuel Ladoke Akintọla too bẹrẹ oṣelu, iṣẹ oniroyin lo n ṣe. Nitori pe ileewe awọn Baptist lo lọ, iṣẹ tiṣa lo fi bẹrẹ igbesi-aye rẹ, ṣugbọn bo ti n ṣe iṣẹ tiṣa naa lo n ba wọn kọ ọrọ sinu awọn iwe iroyin, nigba ti wahala diẹ si de nibi to ti n ṣe tiṣa rẹ ni Baptist Academy, Akintọla kuku fi iṣẹ tiṣa silẹ, o di oniroyin, oun si ni olootu iwe iroyin nla kan nigba naa ti wọn n pe ni Daily Service. Iṣẹ iroyin yii lo ṣe titi ti ijọba oyinbo igba naa fi fun un ni anfaani ẹkọ-ọfẹ pe ko waa lọọ kawe nileewe awọn oniroyin ni London, ko le tubọ di oniroyin nla si i. Igba to de ọhun lo yi adehun pada ti ko kawe lati di oniroyin mọ, o niṣẹ lọọya lo wu oun. Awọn oyinbo naa binu, wọn ni awọn ko lowo lati ran an ni ẹkọ nipa ofin, ẹkọ iṣẹ iroyin lawọn fẹ ko kọ, bi ko ba si ti wọ, konikaluku maa ba tirẹ lọ. Bẹẹ lawọn oyinbo pada lẹyin Akintọla, oun funra rẹ lo si ṣiṣẹ lati ran ara rẹ niwee lati di lọọya ni London.

Nitori pe Akintọla fi iṣẹ iroyin bẹrẹ aye rẹ yii, to si mọ bi agbara awọn oniroyin igba naa ti to ati bi iwe iroyin ti ṣe le yi nnkan pada laarin ọjọ kan si ekeji, ọkan ninu awọn ohun to wu u ju ni lati ni iwe iroyin, ṣugbọn kinni naa ko ṣee ṣe fun un titi ti oṣelu fi wọra, to si fi di olori ijọba. Nigba ti oṣelu de loju-mejeeji, ti ko si iṣẹ meji ju iṣẹ oṣelu lọ, awọn ọmọ ẹgbẹ Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, iyẹn Action Group, ri anfaani iwe iroyin Nigerian Tribune jẹ. Ṣe ki Awolọwọ too da ẹgbẹ oṣelu silẹ lo ti kọkọ fi iwe iroyin yii bẹrẹ, o si sọ pe iwe iroyin naa yoo jẹ eyi to n ja fun gbogbo Western Nigeria, ati awọn ọmọ Naijiria to ku. Ṣugbọn wọn kan pe kinni naa lorukọ bẹẹ ni, ko sẹni ti ko mọ nigba naa pe ohun to jẹ Tribune logun ju ni ọrọ Yoruba, lẹyin naa lo kan West, rabọrabọ rẹ lo si ṣẹṣẹ waa kan gbogbo Naijiria.

Titi ti Akintọla fi di olori ijọba West ni 1959, ọrọ naa ko yatọ, gbogbo ohun ti wọn ba ṣe ni i dara loju Tribune, ko si si iwa ibajẹ kan tọmọ ẹgbẹ wọn hu, daadaa ni n bẹ ninu Aa-bii-dii. Ṣugbọn o, nnkan yipada biri nigba ti ija de ni 1962, ti Akintọla bẹrẹ si i gbo Awolọwọ lẹnu, ti ọrọ naa si di ija, to di ohun ti ẹgbẹ n fọ mọ wọn lori, ti wọn ti wọn mọle, ti wọn tun ṣi wọn silẹ, ṣugbọn to jẹ itimọle ni Awolọwọ ba lọ si ẹwọn ni tirẹ, ti Akintọla si pada si ile ijọba. Nigba naa ni Tribune kawọ ija leri lala, o n yọ ina lẹnu bii Ṣango, ko si si ọta Akintọla to tun buru ju iwe iroyin yii lọ ni 1962 titi de 1964. Bi Akintọla ba so pẹnrẹn, iwe iroyin naa yoo gbe e gadagba, wọn ko si ni i pe kinni naa ni iso, wọn yoo ni o yagbẹ sara ni. Bi Akintọla ba si jaja ri daadaa ẹyọ kan bayii ṣe, iwe iroyin naa yoo kọle kekere kan bayii fun un sẹyin, ko ju bẹẹ lọ.

Akintọla binu titi, o fi ẹsẹ halẹ, ọpọ igba lo si gbe iwe iroyin naa lọ si ile-ẹjọ. Nigba ti agbara rẹ si pọ daadaa, ọpọ igba lo ni ki wọn mu awọn oniroyin tabi olootu iwe yii, wọn yoo si la wọn ju mọ itimọle ni. Awọn ti wọn n ba iwe iroyin naa kọ ọrọ apilẹkọ bii Bọla Ige, Ọnabanjọ ati awọn ẹlẹgbẹ wọn bẹẹ paapaa ko le duro sile wọn mọ, bẹẹ ni wọn ko le rin falala laarin ilu, bi wọn ba ṣe bẹẹ bi ọwọ ba tẹ wọn, isalẹ ẹwọn ni wọn yoo ju wọn si, nitori o pẹ ti ijọba Akintọla ti n wa wọn. Hẹn-an, ohun ti awọn naa n kọ ko dara, awọn aṣiri ti ọpọ eeyan ko mọ ni wọn n tu nipa Akintọla, ko si si ohun to ṣe ni ikọkọ ti iwe yii ko ni i gbe jade ni gbangba. Ọrọ naa n ka Akintọla lara, ṣugbọn ko ti i mọ bi yoo ti ṣe e.

Nigba ti kinni naa waa fẹẹ kọja afarada, ti Akintọla sọ pe iwe iroyin Tribune ko ni iṣẹ meji ju ko ba oun lorukọ jẹ lọ, oun naa bẹrẹ si i wa ọgbọn ti yoo fi ni iwe iroyin tirẹ. Bo ba ṣe pe owo gidi wa lọwọ ọkunrin oloṣelu yii ni, funra rẹ ni, yoo da iwe iroyin tirẹ silẹ, orukọ rẹ ni yoo si maa jẹ. Tabi ko wa awọn ọrẹ rẹ kan ti wọn yoo jọ da iwe iroyin kan silẹ, ti wọn yoo le fi koju iwe iroyin Tribune. Ṣugbọn nibi ti nnkan wa nigba naa, bi Akintọla ba fi le da iru iwe iroyin bẹẹ silẹ, tabi to ba ṣe e pẹlu awọn ọrẹ rẹ kan, kia ni ọrọ naa yoo lu jade, awọn ọta rẹ yoo si pariwo le e lori pe ole ti awọn n pe e gan-an naa ree, wọn yoo ni owo ijọba Western Region lo fi da iwe iroyin silẹ, tabi ki wọn ni o ko owo ijọba jẹ ni, owo naa lo si lo lati da iwe yii silẹ. Ohun ti ko jẹ ko gba ọna ibẹ yẹn lọ niyi, o mọ pe iyẹn ko ṣee ṣe.

Olori ijọba West yii tun ro o pe ki oun da kinni naa silẹ lorukọ ijọba, ko kuku jẹ ijọba ni yoo ni in. Eleyii daa, nitori bi ileeṣẹ iroyin kan ba wa to ba ti jẹ ti ijọba, olori ijọba naa ni yoo maa sọrọ rẹ ni daadaa, wọn ko bi awọn oṣiṣẹ ibẹ ire ki wọn sọrọ olori ijọba laidaa, nitori oṣiṣẹ ijọba ni gbogbo awọn ti wọn yoo maa ṣiṣẹ nibẹ, ohun ti ijọba ba fẹ ni wọn yoo si maa sọ. Wahala to wa ninu tiwọn ni pe ẹni to ba wa nijọba nikan ni wọn yoo maa sọrọ rẹ daadaa, bi olori ijọba kan ba ti kuro ni ipo rẹ, to di araalu, wọn yoo kọyin si i ni, wọn yoo ṣe bii ẹni pe awọn ko mọ ọn mọ, ẹni to ba wa nibẹ ni wọn yoo ba lọ, ti wọn yoo maa sọrọ rẹ daadaa. Ẹru waa ba Akintọla. Ẹru to ba a ni pe bi oun ba da ileeṣẹ iwe iroyin kan silẹ, ti ijọba ba bọ lọwọ oun lojiji, ko ni i si iwe iroyin ti yoo sọrọ oun daadaa mọ, eyi ti oun funra oun si da silẹ yoo tun maa bu oun.

Eyi ni ko ṣe jẹ ki Akintọla fi taratara gba nigba ti awọn kan bẹrẹ si ba a damọran pe ki ijọba rẹ da iwe iroyin tiwọn silẹ lo le kapa ohun ti Tribune n ṣe fun un. Amọ nigba ti ọwọ Akintọla jọ pe o ti tẹ eeku ida debi kan, ti wọn ti da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ, to si ti fọgbọn le awọn NCNC to n halẹ mọ ọn danu, to ko gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn mọra, o bẹrẹ si i ṣeto lati da iwe iroyin tirẹ silẹ, o ni kinni naa ti bọ si dandan. Idi to fi di dandan ni pe ibo ti n bọ lọna, ohun ti Tribune si n kọ jade nipa oun ki i ṣe ohun to le jẹ ki eeyan wọle ibo, bi oun ko ba si tete wa ọna ti awọn araalu yoo fi gbọ tẹnu oun naa, ti wọn yoo si mọ ohun ti ijọba oun naa n ṣe ni daadaa, iwe iroyin naa yoo ti ba toun jẹ ki ibo too de rara. Nigba naa ni Akintọla bẹrẹ lati da iwe iroyin silẹ lorukọ ijọba West, ko si sọrọ naa fẹnikan, wọn n dọgbọn ṣe kinni ọhun ni.

Bi ọdun 1963 ti n pari lọ ni wọn ti bẹrẹ eto yii, ṣugbọn awo ni wọn fi kinni naa ṣe, awọn eeyan ti wọn mọ ko to nnkan rara. Ṣugbọn ina nla ni iru iṣẹ bayii, ko si ki eefin ẹ ma ru jade bo ba ti n lọ. Ki ọrọ naa ma di ariwo ju bo ti yẹ lọ, awọn Akintọla ko duro si Ibadan, ọfiisi kekere kan ni wọn gba l’Ekoo, ninu Investment House, ibẹ ni wọn si ti bẹrẹ kinni naa, ti wọn ni ki olootu ti wọn kọkọ mu maa ba iṣẹ lọ pẹlu iwọnba awọn eeyan to ba gba. Olootu ti wọn kọkọ gba fun iwe naa ni Ọgbẹni Olu Akinsuroju, oun pẹlu awọn diẹ ni wọn si bẹrẹ iṣẹ naa ni Eko, ọpọlọpọ ara Ibadan tabi Western Region ko si mọ ohun to n lọ. Ni asiko ti wọn n da Ẹgbẹ Ọmọ Ọlọfin silẹ ni iwe naa yọ jade lojiji, igba ti o si kọkọ wọ ori atẹ ni Ọjọ Kọkanlelọgbọn, Oṣu Kẹta, ọdun 1964. Gbogbo ẹni to ri i lo n kọ haa haa, nitori iwe iroyin naa daa loootọ.

Yatọ si ti Ẹgbẹ Ọlọfin ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ nigba naa ti wọn n wa iwe iroyin tiwọn, asiko naa tun bọ si igba ti wọn n da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ, gbogbo atako ti wọn si n ri lati ọdọ iwe iroyin Tribune, awọn naa ti ni ẹni ti yoo maa da esi pada bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ. Loootọ iwe naa ni awọn ọmọ Yoruba loun waa ja fun, o tilẹ ni oun ko tori ohun meji wa, nitori ohun ti wọn ṣe da oun silẹ gẹgẹ bii iwe iroyin niyẹn, ṣugbọn awọn eeyan ko ri i bẹẹ, nitori oun naa ko ṣe bẹẹ, iṣẹ Akintọla lo waa ṣe. Eleyii ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, nitori iwe ijọba ni, ijọba Western Region lo da a silẹ, ko si le bẹrẹ si i ki oriki Ọbafẹmi Awolọwọ to wa lọgba ẹwọn, bo ba ṣe bẹẹ, wọn yoo le olootu wọn danu loju ẹsẹ, iyẹn bi wọn o ba tilẹ ti i mọle. Ohun ti iru iwe ijọba bẹẹ gbọdọ maa ṣalaye ni idi ti Awolọwọ fi wa lẹwọn, ati idi ti wọn ko ṣe ni i fi i silẹ lọgba ẹwọn.

Ki i ṣe Sketch nikan ni yoo ṣe eyi, gbogbo iwe iroyin ti ijọba kan ba ti da silẹ ni. Ko si ijọba ti yoo da iwe iroyin rẹ silẹ ti yoo ni ẹgbẹ alatako ni ko maa yin, tabi pe ọga awọn alatako ni ko maa pọnle. Rara o. Bo ba ṣe le bu awọn alatako to gan-an ni yoo fi gbayi lọwọ awọn ti wọn da a silẹ, ti wọn yoo si maa gbe oriyin fun awọn olootu pe wọn ṣe iṣẹ naa bii iṣẹ, ohun ti awọn ni ki wọn ṣe gan-an ni wọn n ṣe. Nidii eyi, ko pẹ rara ti Sketch ti di iwe ti gbogbo eeyan da mọ, nitori gbogbo ohun ti Tribune ba ti tẹ jade lawọn naa n tako, nigba to si jẹ ohun ti Akintọla ba ṣe ni Tribune n tako, ti yoo si bu oun ati ijọba rẹ, Sketch lo ku to n da esi pada fun wọn, wọn yoo ṣalaye ohun ti Akintọla ṣe ti Tribune ni ko daa, wọn yoo si sọ pe ohun to dara ju fun West ati fun gbogbo Yoruba niyẹn. Ogun naa si le laarin awọn iwe iroyin mejeeji nibẹrẹ.

Ibadan ni Akintọla n gbe iwe iroyin naa bọ, ṣugbọn o kọkọ fẹ ko fẹsẹ rinlẹ daadaa ki wọn too gbe e kuro l’Ekoo, o fẹ ki wọn tete da a mọ. Ati pe bo ba ṣe pe wahala kan yoo ti idi iwe naa jade, wọn fẹẹ mọ, ki wọn si mọ ohun ti wọn yoo ṣe si i. Iyẹn ni wọn ko ṣe tete wa si Ibadan, to jẹ Eko ni wọn ti da Sketch silẹ, koda, wọn ko duro ni Ikẹja tabi ibikibi ti Western Region de, lori ilẹ ijọba apapọ ni wọn da a silẹ si, wọn ti mọ pe nibẹ yẹn, ko si ohun ti ẹnikan le ṣe si i, awọn aṣofin ko si le paṣẹ kankan lori rẹ, nitori iwe iroyin naa ko si nibi ti wọn ti le paṣẹ le e lori rara. Akintọla mọ pe bo ṣe West ni iwe naa wa nibẹrẹ, ko si ohun ti ko le ṣẹlẹ si i. Bi awọn tọọgi atawọn oloṣelu ti wọn koriira Akintọla ati ijọba rẹ ko ba lọ sibẹ lati da ibẹ ru, awọn aṣofin le paṣẹ pe ki wọn ko iwe iroyin naa wọle lẹsẹkẹsẹ, iyẹn l’Akintọla ṣe gbe e sa fun wọn.

Sibẹ naa, awọn aṣofin Western Region gbọ, wọn si gbe ija nla ba Akintọla nile-igbimọ aṣofin. Iwe iroyin naa ko ti i jade ju ọsẹ meji lọ nigba ti wọn fi da ọrọ rẹ silẹ ni ile-igbimọ, nigba ti Akintọla wa si ile-igbimọ naa to n sọ pe ko si owo, ki wọn fi owo kun owo ti ọfiisi Premia, iyẹn Olori ijọba, yoo maa na. Jonathan Ọdẹbiyi lo dide, ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group, ọkan pataki ninu awọn ti wọn lẹnu nile-igbimọ aṣofin naa ni. Ọdẹbiyi ki i deede sọrọ, bo ba si sọrọ bayii, kaluku yoo pa lọlọ ni. Ọdẹbiyi lo sọ fun Akintọla loju rẹ bayii pe ki lo n beere owo to fẹẹ na si, ki lo fẹẹ fi kun owo ti wọn n bu fun ọfiisi rẹ si, ṣebi wọn fun un lowo kan tẹlẹ, bawo lo ṣe na an. O ni ko si ki owo ti wọn n fun un to o na, nigba to jẹ inakunaa lo n na, awọn ohun ti ko yẹ ko fi owo ijọba ṣe lo n fi i ṣe. Nigba naa ni Ọdebiyi la ọrọ mọlẹ.

Aṣofin yii beere pe nibo ni Akintọla ti ri owo da iwe iroyin tuntun to pe ni Sketch silẹ, owo wo lo lo lati fi da a silẹ, ati pe ta lo sọ fun nigba ti yoo da a silẹ gan-an. Bẹẹ ni Ọdẹbiyi ni ki Akintọla ṣalaye ohun to fẹẹ fi iwe iroyin ṣe, nigba ti ki i ṣe iṣẹ ijọba lati da iwe iroyin silẹ, ijọba ki i ṣe oniroyin, iṣẹ awọn araalu ni. O ni bi Akintọla ba fẹẹ da beba silẹ, ṣebi yoo ti fi i sinu iwe iṣuna ọdun naa, awọn yoo ti sọrọ lori rẹ, awọn yoo si ti fọwọ si i fun un bi awọn ba mọ pe ohun to dara ni. Ṣugbọn Akintọla ko fi i sinu iwe owo to fẹẹ na, o kan lọọ gbe kinni naa kalẹ lẹyin awọn, o waa sare pada wa pe ki ile-igbimọ fun oun lowo ki oun ri ohun na. O ni ni toun, fifi owo araalu ṣofo lasan ni iru eleyii, nitori ko si oore kan ti iwe iroyin bẹẹ yoo ṣe fun awọn eeyan Western Region, bii igba ti eeyan da owo sinu kanga lasan ni.

Ṣe ọrọ to delẹ yii, aaya gbọn, Ogungbe naa gbọn ni: bi aaya ti n tiro, bẹẹ ni Ogungbe n bẹrẹ. Ohun to yẹ ki Akintọla ṣe ni Ọdẹbiyi sọ yẹn, bo ba jẹ nibi ti nnkan ti daa. Ki olori ijọba kan too da ileeṣẹ nla bii ti iwe iroyin Sketch bẹẹ silẹ, o gbọdọ fi to awọn aṣofin leti, ki awọn aṣofin si fọwọ si i. Ṣugbọn Akintọla mọ pe bi wọn ba gbe iru iwe bẹẹ de ọdọ awọn aṣofin West, wọn ko ni i ba oun fọwọ si i, wọn yoo si sọ ọrọ naa di ariwo debii pe gbogbo aye ni yoo pe oun ni apa, ọmọ oninaakunaa, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi ko si ni i jẹ ki oun le da iwe iroyin ti yoo gbeja oun silẹ, ti awọn ọta oun yoo si maa lo tiwọn lati fi bu oun. Ọdẹbiyi to n sọrọ pe ko gbe e wa naa mọ pe bo ba gbe e wa, awọn ko ni i fọwọ si i, ohun to ṣe jẹ ọgbọn lawọn mejeeji n ta fun ara wọn niyẹn. Ṣugbọn ni tododo, ọrọ naa ka awọn aṣofin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ AG lara.

Akintọla naa jade, o ni ki awọn aṣofin ṣe suuru, ẹbẹ loun kuku n bẹ wọn, oun ko ṣakọ. O ni, “Haba, Ọnarebu Ọdẹbiyi mọ pe dida iwe iroyin silẹ ki i ṣe inakunaa, bẹẹ ni ki i ṣe ina apa, wọn kan n sọ eleyii nitori ọrọ oṣelu ni. Oloye Ọdẹbiyi mọ pe lara ohun ti yoo mu Western Region goke si i la ṣe yii, ti a ni iwe iroyin tiwa, ṣebi ko le maa la awọn araalu lọyẹ ni, ko si maa polongo ohun ti ijọba ba n ṣe ni!” Bi Akintọla ti n sọ bẹẹ lawọn ọmọlẹyin rẹ n hoo, ti wọn n pariwo, “Good talk! Good talk!”, iyẹn ni pe ọrọ rere lo n ti ẹnu ọga awọn jade yẹn. Ṣugbọn bẹẹ naa lawọn ọmọ ẹgbẹ alatako, paapaa awọn AG, n pariwo tiwọn naa, ti wọn n ṣe, “No! No! No!” ti awọn mi-in si n pariwo, “Lie! Lie!” ti wọn ni irọ ni Akintọla n pa. Ọrọ naa si tun di awuyewuye laarin awọn aṣofin, wọn si fa kinni naa fun bii wakati kan gbako.

Ṣugbọn nigbẹyin, bi a ba jẹkọ, a aa dariji ewe lọrọ naa da, nitori lẹyin gbogbo awuyewuye, wọn fi Akintọla silẹ pẹlu iwe iroyin rẹ ni, wọn ni ko gba owo to fẹẹ gba, ibi to ba si wu u ko lọ na an si. Bẹẹ ni agbara de si ọwọ Akintọla, iwe iroyin Sketch ti rọna gbe e gba, nitori gbogbo owo ti ọkunrin naa ri, irinṣẹ nla lo fi ra, o si ra ẹrọ itẹwe tuntun ti iru rẹ ko pọ ni Naijiria nigba naa, o si ri i si Ibadan. Ni ọjọ Satide, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 1964, iwe iroyin Sketch tẹ atẹpari wọn niluu Eko, wọn si ko angara wọn. Nigba to di ọjọ Aje, Mọnde, ọgbọnjọ, oṣu kọkanla, 1964, Daily Sketch jade lori maṣinni tuntun niluu Ibadan, nigba ti Akintọla si ri iwe naa, ẹrin lo tẹnu rẹ jade, o ni “O ti ṣee ṣe!” bẹẹ lawọn minisita rẹ fidunnu wọn han, ọpọ ọmọ Yoruba lo si dunnu, wọn ni iwe iroyin Sketch gori atẹ.

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.