Nibo lawọn oloṣelu yii ti n ri ero rẹpẹtẹ bayii

Spread the love

O ti di aṣa bayii, pe bi Aarẹ Muhammadu Buhari ba lọ si ibi kan lati lọọ ṣe kampeeni, awọn ero yoo yapa sibẹ ni. Nigba ti ẹ ba wo wọn lọ lori tẹlifiṣan, ori wọn yoo si lọ salalu bii omi okun. Ṣugbọn iyanu ibẹ ni pe bi Atiku Abubakar ba lọ si ilu kan naa yii ti Buhari lọ loni-in lọla, ero tirẹ yoo tun fẹrẹ ju ti Buhari lọ. Eleyii ṣẹlẹ ni Kano, o ṣẹlẹ ni Kaduna, bẹẹ naa lo ri ni Ibadan ati awọn ilẹ Ibo kọọkan. Ibeere ni pe, nibo ni awọn oloṣelu ti n ri ero rẹpẹtẹ to n tẹle wọn yii. Ṣe awọn ti wọn fẹran wọn naa lo kuku pọ to bayii ni abi awọn ti wọn ko ni iṣẹ lọwọ ti wọn n rin kiri, ti wọn si n wa ibi ti wọn yoo ti fun oju wọn lounjẹ, ti wọn yoo fi ri iran wo fun igba diẹ. Tabi awọn ti wọn n rẹnti funra wọn lati ba wọn lọ sibi ipolongo ni wọn ni. Ohun to daju ni pe lasiko ti awọn oloṣelu n ṣeto ipolongo wọn yii, ọsan gangan lo maa n saaba a bọ si, awọn ti wọn ba si ni iṣẹ lọwọ ko ni i le lọ si iru ipolongo bẹẹ, yatọ si ti wọn ba jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu nikan. Amọ ko waa si ibi ti wọn lọ, ko si ipolongo ti wọn ṣe ti ero ko ni i yapa sibẹ, ti wọn yoo si maa wọ bii omi. Eyi o wu ko jẹ ninu ọrọ mejeeji yii, bo ba jẹ awọn ti ko niṣẹ ni wọn pọ to bẹẹ nigboro, ohun buruku ni, apẹẹrẹ ti ko dara ni fun ilẹ yii, nitori  wahala lo n bọ lọjọ iwaju yẹn. Bo ba si jẹ awọn eeyan lawọn oloṣelu n rẹnti, ti wọn n ko wọn kaakiri lati ipinlẹ kan si ipinlẹ keji, eleyii naa ko dara, owo araalu ni wọn n na, owo ti wọn ti ji ko pamọ tẹlẹ ni wọn n na, tabi ko jẹ awọn mi-in lo ṣẹṣẹ n ya wọn lowo tuntun. Wọn ko le na iru awọn owo bayii nitori pe wọn fẹran awọn eeyan Naijiria, wọn n na an nitori pe wọn fẹẹ ṣowo ni. Ẹni to ba fi owo gọbọi bẹẹ ṣe owo kan, to n ha owo le awọn ti wọn n tẹle wọn kiri yii lọwọ ni gbogbo ode ti wọn ba ba wọn lọ, iru ẹni bẹẹ ko ni ijọba gidi kan ti yoo ṣe faraalu, nitori owo to n na ni yoo kọkọ tete maa sare ko jọ. A ko fẹ iru awọn oloṣelu bayii, awọn ti yoo tun ilu ṣe la fẹ, awọn ti yoo ko oriire ba mẹkunnu gbogbo. Amọ kawọn araalu naa ṣọra wọn, kawọn mẹkunnu paapaa kilọ funra wọn, ki wọn yee gba owo buruku lọwọ awọn oloṣelu, ki wọn si yee tẹle wọn kaakiri, nitori bo ba ṣẹlẹ, awọn ni iya ibẹ yoo jẹ ju, ohun ti kaluku ba si fori ara rẹ pe ni yoo ri, ko si ogun to buru ju ogun afọwọfa lọ. Ki ọlọmọ kilọ fọmọ rẹ o.

 

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.