Nibo l’Amosun yoo gbe eleyii gba

Spread the love

Ko si ohun to yara sọ eeyan di ẹlẹtẹẹ ati alabuku ju aṣeju lọ. Nigba ti eeyan kan ba wa to jẹ alaṣeju, nigba ti yoo ba tẹ bayii, were ni. Ati pe agbara ti awọn oloṣelu maa n ni tiwọn ba wa nile ijọba yẹn, wọn maa n ro pe bi yoo ti ri ni gbogbo ọjọ aye awọn niyẹn. Laakaye ẹlomi-in maa n sọnu ninu wọn ti yoo fi ro pe agbara ti wọn gbe le oun lọwọ yẹn, agbara titi di ọjọ iku ni. Boya ni Ibikunle Amosun nigbagbọ pe ẹnikan to oun, tabi o tun le to oun ni gbogbo ipinlẹ Ogun mọ, o ro pe ohun ti oun ba ṣe naa ni gbogbo aye gbọdọ gba, ohun ti oun ba fẹ ni wọn gbọdọ ba oun fẹ. Tabi kin ni wahala, kin ni agidi lati ba ti ẹgbẹ oṣelu to gbe ọ depo jẹ nitori pe ẹgbẹ naa ko mu ẹni ti iwọ fẹ. O waa n fi orukọ Buhari halẹ, o n fi orukọ Buhari jẹun, o n fi i dẹruba awọn eeyan pe iwọ ati Buhari ti sọrọ, Akinlabi Akinlade ni yoo wọle. Iwọ fẹẹ fi orukọ APC lọ sile-igbimọ aṣofin, o fẹẹ fi orukọ APM ṣe gomina, iwọ nikan naa lo n ṣe oju meji bii ida yii o. Bo ba tiẹ jẹ oun nikan naa ni oloṣelu kan ṣoṣo to wa ni ipinlẹ Ogun, iba ni yoo mọ. Nigbẹyin, Buhari kangi mọ yẹyẹ lẹyin ọrun. Buhari ni iwa imọ-tara-ẹni-nikan ni fun oloṣelu kan lati kuro ninu ẹgbẹ APC lọ sinu ẹgbẹ mi-in, ko waa sọ pe oun Buhari lawọn yoo dibo fun lati inu ẹgbẹ awọn tuntun. O ni bo ba jẹ tọhun fẹran oun Buhari, yoo duro ninu ẹgbẹ APC ti awọn jọ n ṣe, gbogbo ija tabi awuyewuye to ba si wa ninu ẹgbẹ naa, awọn yoo jọ yanju rẹ. O ni ki i ṣe ki ẹnikan lọ sinu ẹgbẹ oṣelu mi-in, tabi ko da ẹgbẹ oṣelu mi-in silẹ, ko waa ni toun loun n ṣe. Olowe mowe, Amosun mọ pe oun loun ni owe naa, awọn eeyan si mọ pe ọrọ buruku to jade lẹnu Buhari yii, Amosun lo sọ loko naa, ibi to si ti ba ọkunrin naa ko daa. O pẹ ti a ti n lọgun nibi yii pe ki Amosun gba kamu, ko ma ba ẹgbẹ wọn jẹ nitori pe ẹni ti oun fẹ ni gomina ko wọle. Ṣugbọn ọkunrin onifila-gogoro naa ko gbọ, o ti ro pe bi a ba ti yọwọ Ọlọrun, Amosun lo ku. Yẹyẹnatu! Rọbọrebe lasan!

 

 

(29)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.