Nibi ti Wolii Awosoya ti n ṣe itusilẹ fun akẹkọọ fasiti lo ti ba a lo po ninu igbo

Spread the love

Wolii Yusuf Awosoya to ki akẹkọọ Fasiti ipinlẹ Kwara kan mọlẹ niluu Malete, lasiko to n ṣe itusilẹ fun un ninu igbo ti ri ẹwọn oṣu mẹta he.

Awosoya lo fọgbọn tan ẹni ọdun mejidinlogun naa wọnu igbo kan, to si ba a laṣepọ, eyi lo pe ni ọkan lara awọn iṣẹ toun n ṣe fun un.

Adajọ Bilikis Baraje ti ile-ẹjọ Majisreeti ilu Ilọrin paṣẹ pe ki ọdaran naa lọọ ṣẹwọn oṣu mẹta lai si owo itanran.

Iwe ti ileeṣẹ ọlọpaa fi wọ ọ lọ sile-ẹjọ fi han pe akẹkọọ naa ti wọn forukọ bo laṣiiri lo fi iṣẹlẹ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Malete leti.

O nigba tawọn de inu igbo kan ni Awosoya tan oun pe lara akanṣe iṣẹ toun maa ṣe fun oun ni ki oun ba a laṣepọ. Nigba to ṣe e tan niye oun ṣẹṣẹ ṣi pe wolii ti lu oun nijibiti ara.

Ṣugbọn Awosoya loun gba iyọnda lọwọ ọmọbinrin naa koun too ṣe kinni naa fun un gẹgẹ bi awọn agbofinro ṣe sọ. O ni iranlọwọ loun ṣe fun un.

Ọdaran naa loun jẹbi ẹsun yii nigba ti wọn ka a si i leti nile-ẹjọ. O ni ki adajọ ṣiju aanu wo oun, ko si din ijiya oun ku.

Agbẹjọro ijọba, Insipẹkitọ Adewumi Johnson, rọ ile-ẹjọ lati sọ ọdaran naa sẹwọn.

Ni ti agbẹjọro rẹ, Arabinrin Jimoh, o ke si ile-ẹjọ lati foju aanu wo onibaara oun, niwọn igba to ti jẹwọ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa. O ni o ti mọ aṣiṣe rẹ.

Adajọ Baraje paṣẹ pe ko lọọ ṣẹwọn oṣu mẹta lai ni owo itanran.

 

 

 

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.