Nibi ti tirela pa aboyun si n’Ibadan lo tun ti pa obinrin mi-in si lẹyin ọsẹ kan

Spread the love

Lẹyin oṣẹ kan ti tirela tẹ alaboyun kan pa labẹ biriiji Mọlete, n’Ibadan, tirela kan tun tẹ ẹlomi-in pa laduugbo Mọlete ọhun kan naa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

Yatọ si obinrin to padanu ẹmi ẹ yii, ọpọ eeyan lo farapa nigba ti mọto mẹta pẹlu Kẹkẹ NAPEP mẹrin bajẹ ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ ni nnkan bii aago mẹjọ kọja iṣeju meji aarọ ọjọ Jimoh ọhun.

 

Alaroye gbọ pe tirela ọhun to n gbe kọ̀ǹténà nla kan bọ lati ọna Challenge, to dojukọ ọna Bẹẹrẹ lo padanu ijanu ẹ, to si kọlu awọn ọkọ to wa niwaju ẹ labẹ biriiji Mọlete.

 

Ọkan ninu awọn tiṣẹlẹ yii ṣoju wọn ṣalaye fakọroyin wa bayii pe “nibi ti jiipu kan to jẹ ọkan ninu awọn mọto to wa niwaju tirela yẹn ti n sa asala fun ẹmi ara ẹ pe ki tirela yẹn ma baa kọlu u lo ti mu kẹkẹ NAPEP to wa niwaju ẹ gun, ati jiipu, ati kẹkẹ ni wọn si bajẹ pẹlu awọn moto ati kẹkẹ mi-in.

 

Ta o ba gbagbe, lọjọ mẹwaa ṣaaju iṣẹlẹ yii ni tirela kan tẹ alaboyun kan pa labẹ biriiji Mọlete yii kan naa, nigba ti bireeki iyẹn naa deede daṣẹ silẹ.

 

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ awọn FRSC, iyẹn ajọ to n ri si aabo ẹmi eeyan atawọn ohun irinsẹ loju popo, Ọgbẹni Oluwaṣeun Onijala, sọ pe eeyan mẹta lo fara ṣeṣe ninu ijamba naa, awọn si ti gbe wọn lọ sileewosan, wọn ti gbadun, kaluku si ti gba ile ẹ lọ.

 

Awọn oṣiṣẹ ajọ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n mojuto lilọ-bibọ ọkọ atawọn nnkan irinsẹ mi-in loju popo (OYTMA), ti gbe oku obinrin to ṣalaisi yii pamọ si ẹka ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan Ade-Ọyọ n’Ibadan. Ibẹ lo ṣi wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, nitori ẹnikẹni ko ti i yọju gẹgẹ bii mọlẹbi oloogbe naa.

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.