Nibi ti Mohammed ti lọọ sin gbese ni won ti pa a Ni won ba gbe oku e so sinu igbo

Spread the love

Mohammed Umar to n gbe ni agọ Fulani Kosa, ni abule Aderan, nijọba ibilẹ Kaiama, ni awọn araalu ṣadeede ba oku rẹ ninu igbo, lẹyin ọjọ to lọọ sin gbese ẹgbẹrun mẹta Naira ti Aliyu Hassan jẹ ẹ.

Umar ni wọn lo ya Aliyu Hassan lowo, ọjọ to si ni koun lọọ gba owo naa lo dawati. Gbogbo awọn ẹbi rẹ lo ti daamu nigba ti wọn ko gburoo rẹ ko pada sile.

Nigba ti wọn fi maa ri i, oku rẹ ni wọn ba ninu igbo kan to wa nitosi ṣọọbu Hassan.Wọn ti rẹ ọrun rẹ, bẹẹ ni wọn ti ṣa gbogbo ara rẹ yanayana.

Kete ti wọn ri oku ọkunrin naa ni wọn gba ṣọọbu ẹni to lọọ sin ni gbese lọ. Bi Hassan ṣe ri wọn lokeere loun pẹlu awọn meji kan ti wọn furasi pe wọn jọ ṣiṣẹ ibi naa; Hassan Abdullahi ati Sa’adu Tanko ni wọn fẹsẹ fẹ ẹ.

Ṣugbọn ọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta, wọn ti wa lahaamọ ẹka to n gbogun ti iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ ọlọpaa.

Lasiko iwadii, wọn jẹwọ pe Hassan lo fọgbọn tan oloogbe naa lati waa gba owo toun ya lọwọ rẹ.

Nigba to de lawọn dọdẹ rẹ, tawọn si ṣa a ladaa titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ.

 

 

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.