Nibi ti Biọdun ti fẹẹ lọọ paayan lọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ l’Ogijo

Spread the love

Kayọde Ọmọtọṣọ, Abẹokuta

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ti tẹ Biọdun Adelokun, lasiko to fẹẹ lọọ paayan l’Ogijo. Ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni ọmọkunrin naa, ọmọ ẹgbẹ alatako lo si fẹẹ lọọ pa ki ọwọ too tẹ ẹ lọjọ kẹrinlelogun, oṣu to kọja.

  Gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ si ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, o ni awọn ọlọpaa teṣan Ogijo lo mu Biọdun lasiko ti CSP Muhammed Baba to jẹ ọga wọn ko wọn ṣodi lati yide kiri agbegbe naa.

Wọn ri awọn ọkunrin mẹta kan lori ọkada Bajaj ti nọmba rẹ jẹ KJA 778 QH, laduugbo Fakalẹ, Ogijo, ṣugbọn bi awọn afurasi naa ṣe taju kan-an ri awọn ọlọpaa ni wọn yiri ọkada naa pada, lojiji ni wọn si bẹ silẹ, ti wọn n sa lọ. Awọn agbofinro naa tẹle wọn, lasiko naa si ni ọwọ wọn tẹ Biọdun pẹlu baagi kan lọwọ rẹ.

Ayẹwo ti wọn ṣe si baagi naa ni wọn fi ri i pe ibọn ilewọ kan, ọta ibọn, aake ati awọn oogun abẹnugọngọ ni wọn ko sinu rẹ. Nigba ti wọn beere ibi to ti ri awọn nnkan naa, ṣe lo ni ki wọn ṣe oun jẹẹjẹ, o ni ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye loun, oun loun si maa n ba awọn ẹgbẹ naa pa awọn eeyan kiri.

Biọdun ni awọn meji kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun alatako awọn ni wọn ni ki oun lọọ pa, ibẹ si loun pẹlu awọn yooku oun jọ n lọ ki ọwọ too tẹ awọn.

Ṣa, komisanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Bashir Makama, ti paṣẹ pe awọn ọlọpaa gbọdọ ṣawari awọn yooku Biọdun to sa lọ, ki wọn si ṣewadii to gbopọn lori wọn.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.