Nibi ọdun Oodua; Gani Adams rọ ajọ INEC lati ṣeto idibo alaakoyawọ

Spread the love

Aarẹ Ọna Kakanfo ti ilẹ Yoruba, Aarẹ Gani Adams, ti sọ pe bi ajọ eleto idibo orileede yii ba ṣe ko akoyawọ si ni yoo sọ bi alaafia yoo ṣe wa lẹyin idibo to n bọ lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ati ọjọ keji, oṣu kẹta, ọdun yii.

Nibi ayẹyẹ ọdun Oodua to waye niluu Ileefẹ lọsẹ to kọja ni Aarẹ Gani Adams ti sọrọ naa. O ni gbogbo oju lo wa lara orileede Naijiria nipa idibo naa, nitori oun ni yoo sọ bi irinajo ọdun mẹrin to n bọ nilẹ yii yoo ti ri.

O waa rọ ajọ INEC lati mọ pe ko si ibomi-in ti a le pe ni orileede wa ju Naijiria lọ, o ni wọn gbọdọ ṣeto idibo naa lọna ti yoo munadoko, ti yoo si jẹ apewaawo fun awọn orileede mi-in lagbaaye.

Bakan naa lo rọ awọn oloṣelu lati mọ pe alaafia nikan ni ọpakutẹlẹ idagbasoke nibi gbogbo, ki wọn yago fun iwa jagidijagan, ki wọn si gba ifẹ ọkan awọn araalu laaye lasiko idibo naa nipa fifaaye gba wọn lati dibo fun ẹni ti wọn ba fẹ ko ṣolori wọn lẹkajẹka.

Ni ti ọdun Oodua, Aarẹ Adams ni idi toun fi gbe e kalẹ gẹgẹ bii ayẹyẹ lọdọọdun ko ṣẹyin lati maa ran awọn iran Yoruba kaakiri agbaye leti nipa aṣa, ati lati jẹ ki wọn mọ pe wọn ko gbọdọ gbagbe ilẹ Ifẹ ti i ṣe orirun wọn.

O ni agbara ati aṣẹ wa niluu Ileefẹ, oun si fẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba mọ pe ko si nnkan ti wọn le fi ọkan kan beere nilẹ Ifẹ ti wọn ko ni ri idahun si ni kiakia.

Aarẹ Adams tun lo asiko ayẹyẹ naa lati gbadura fun alaafia orileede Naijiria, o pe awọn alalẹ ilẹ lati gbogun ti awọn Fulani darandaran ti wọn n yọ ilẹ yii lẹnu, paapaa, lapa Iwọ-Oorun orileede yii.

Ninu ọrọ rẹ, alakooso ẹgbẹ OPC nipinlẹ Ọṣun, Deji Aladeṣawe, dupẹ lọwọ Aarẹ Adams fun agbekalẹ ayẹyẹ ọdun Oodua, o ni ọpọ anfaani ni iran Yoruba ti jẹ nipasẹ rẹ, o si n ṣagbende aṣa iṣẹdalẹ iran naa kaakiri agbaye.

 

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.