N’Ibadan, Okpara, olori ẹgbẹ NCNC koju Akintọla, olori ẹgbẹ Dẹmọ

Spread the love

Ojo n rọ lọwọ nigba ti Michael Okpara gunlẹ si papa ọkọ ofurufu Ikẹja, niluu Eko, lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun 1964. Ṣugbọn pẹlu bi ojo ti ṣe n rọ to lọjọ naa, awọn ero to ti wa nibudokọ yii lati pade rẹ le nirinwo, bẹẹ lawọn mi-in n sare bọ nigba ti wọn gbọ pe ọkunrin naa ti de. Ko sẹnikan to woju ojo, awọn mi-in gan-an ko mọ pe ojo n pa awọn, gbogbo wọn lo ni dandan ni ki awọn pade Okpara. Awọn ọmọ Ibo ni ki lo ṣubu tẹ awọn, nigba to jẹ Ibo ni Okpara funra rẹ, oun si ni Olori ijọba, Prẹmia ilẹ Ibo, Eastern Region. Ṣugbọn oun naa ni olori ẹgbẹ NCNC, ẹgbẹ Alakukọ, bẹẹ nigba naa, ni Eko ati ọpọ ilu nilẹ Yoruba, ẹgbẹ Alakukọ yii gbajumọ pupọ laarin awọn oloṣelu gbogbo. Iyẹn lo gbe ọpọlọpọ awọn ọmọ Yoruba naa debẹ, nigba ti Okpara yoo si fi bọ silẹ ninu ẹronpileeni rẹ, awọn ero to wa nibẹ ti sun mọ ẹgbẹrun kan.
Ọrọ irin-ajo Okpara yii ko dun mọ ijọba Western Region ninu, ṣugbọn ko si ohun ti wọn le ṣe si i, nitori o ti ni oun n bọ, awọn naa si ti ṣeto gbogbo ti ko fi yẹ ko wa, ṣugbọn ọkunrin naa ko gbọ, o ni gbogbo ohun to ba fẹẹ ṣẹlẹ ko ṣẹlẹ ki gbogbo aye foju ri i, ṣugbọn pe boya oun ko ni i lọ si ilẹ Yoruba ti oun ti dagbere fawọn eeyan yẹn, ki awọn oloṣelu ati ijọba Western Region tu itọ rẹ danu, oun n bọ gẹgẹ bi oun ti ṣe wi. Bi wọn ti gbọ pe o n bọ loootọ ni wọn ti fi ọlọpaa kun awọn ọlọpaa Ibadan, wọn si fi awọn ṣọja kun wọn, awọn ṣọja naa si n rin kiri pẹlu ibọn lọwọ wọn, bi wọn yoo yinbọn naa fun awọn eeyan ni o, boya wọn yoo si fi dẹruba wọn lasan ni, ko sẹni to ti i mọ. Ṣugbọn to ba jẹ wọn fẹẹ fi kinni naa dẹruba Okpara funra rẹ ki wọn si le e pada ni, kinni ọhun ko ṣiṣẹ o.
Idi ti ko fi ṣiṣẹ naa ni pe bi Okpara ti n bọ silẹ ninu ẹronpileeni lawọn to wa nibẹ pariwo, “Pawa (Power!)”, “M. I Power!” “Maiki Pawa!”, ati bẹẹ bẹẹ lọ. N lawọn oniroyin ba ya bo o, wọn fẹẹ mọ boya yoo lọ si Western Region to ti n leri pe oun n lọ tabi ko ni i lọ, pe boya Eko nikan ni yoo ti duro. Ọkunrin naa ni ọrọ naa ti kọja bẹẹ yẹn, o ni riri ti wọn ri oun yẹn, ki i ṣe Eko nikan ni oun wa, oun n lọ yika gbogbo ilẹ Yoruba ni, fun odidi ọsẹ kan loun yoo si fi maa yi ilẹ Yoruba po, ko si sẹnikan ti yoo da oun duro, nitori ni abẹ ofin orilẹ-ede Naijiria, oun lẹtọọ lati rin kaakiri ibikibi ni Naijiria, ti ko si sẹni to gbọdọ da oun duro. O ni ofin konilegbele, abi ka-ma-ṣepade, ka-ma-korajọ, ki i ṣe ofin ti yoo mulẹ, nitori ko si iru nnkan bẹẹ ninu iwe ofin Naijiria, Western Reegion ni wọn ti n ṣe bẹẹ, iyẹn o si le ṣiṣẹ.
Awọn oniroyin kan bi i leere pe ṣe bo ṣe n lọ si West yii, ṣe oun funra ẹ n reti wahala, ṣe o lọkan pe wahala yoo ṣẹlẹ lọhun-un, abi ki lero ẹ. Ọkunrin naa ni kin ni yoo fa wahala, o ni wahala kankan ko le ṣẹlẹ, ko si ohun ti yoo fa a. O ni gbogbo ariwo ti wọn n gbọ lọtun-un losi yẹn, ijọba Akintọla lo n pa a, ki wọn si fi le da ijangbọn silẹ ni. Okpara ni bi ijangbọn kankan ba ṣẹlẹ ni West lori irin-ajo oun yii, awọn Ẹgbẹ Dẹmọ ni wọn da a silẹ. O ni ko sẹni ti ko mọ pe Ẹgbẹ Dẹmọ ko lero kankan to jẹ tiwọn, awọn ọdalẹ inu ẹgbẹ NCNC ati ẹgbẹ AG ni wọn ko jọ, wọn si kere pupọ debii pe wọn ko le da wahala kankan silẹ rara. O ni alaafia loun mu wa si ilẹ Yoruba, nitori awọn eeyan funra wọn ni wọn n pe oun, oun si n lọọ jẹ ipe wọn ni, awọn ni wọn ni awọn fẹẹ ri oun, ki oun waa ba awọn sọrọ, oun si n lọọ ba wọn ni.
Ni tododo, niṣe lo jọ pe awọn ero ti n reti ọkunrin naa o, nitori lati papa-ọkọ-ofurufu yii titi de ile-Eko lọhun-un, awọn ero to soju ọna ni o, eyi ti fihan bi ẹgbẹ NCNC ṣe gbajumọ to ni ilẹ Yoruba nigba naa. Ariwo, “Okpara!”, “Okpara!”, tabi “Pawa!” “Pawa!” ni wọn n pa. Bo ti n lọ taara, Glover Hall, l’Ekoo ni wọn gbe e lọ, nigba ti yoo si debẹ, ibẹ naa ti kun pitimu fawọn ero. Iyatọ to wa ninu eleyii ni pe awọn aṣaaju ẹgbẹ NCNC ni wọn pọ nibẹ, wọn kun ibẹ fọfọ. Awọn minisita, awọn aṣofin, ati awọn oloye ẹgbẹ naa loriṣiiriṣii n rọ wa sibẹ, ni gbara ti ọkunrin olori ẹgbẹ wọn naa si wọle lariwo nla gba gbogbo ibẹ kan. “Paaaaaawa!” “Paaaawa!”, bi awọn ti wọn wa nibẹ ti n lọgun ree, niṣe lo si da bii igba pe wọn ti gba ijọba Naijiria kuro lọwọ awọn ti wọn n ṣe e, nibi ti inu wọn dun de, wiwa Okpara naa fi wọn lọkan balẹ gan-an.
Nibẹ lo ti kede pe ko si ọna meji ti awọn le gba lati gba ijọba lọwọ awọn jẹgudujẹra ti wọn n ṣi agbara wọn lo nitori ipo ti wọn wa bayii ju ki ẹgbẹ NCNC ati ẹgbẹ AG jọ ni ajọṣe, ki wọn jọ ṣe papọ, ki wọn pa agbara wọn pọ soju kan, ki wọn le le awọn eeyan naa danu bii ọgan. Okpara ni oun waa sọ fun awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu oun gbogbo pe oun n lọ si Western Region, ofin kan ti wọn ṣe ko da oun duro pe ki oun ma rin, oun si tun fẹẹ sọ fun wọn pe alaafia loun n ba lọ sibẹ, oun ko ba tija lọ, bẹẹ ni oun ko ya ile ẹnikẹni yatọ si ile awọn ọmọ ẹgbẹ oun, ati awọn ti awọn ba jọ ni ajọṣe. O loun ko de ile ijọba, oun o si ni i ya sọdọ ẹni ti ko ba fẹẹ roun, oju titi to jẹ tijọba apapọ loun yoo maa tọ, gbangba toun ba si ti fẹẹ sọrọ yoo jẹ tawọn eeyan ti wọn ba ni awọn fẹẹ ri oun. O loun o ni i dọdọ awọn eeyan Dẹmọ o, ki wọn ma yọ ara wọn lẹnu.
Bo ti n sọrọ lawọn eeyan naa n pariwo, wọn ni Okpara alaya-bii-kinniun, bo ti wi ni yoo ṣe. Awọn eeyan rẹ ti ṣalaye fun un pe awọn ti pa Alake Abẹokuta, Ọba Samuel Adeṣina Gbadebọ ti, pe awọn ko de ọdọ rẹ mọ, awọn si ti sọ fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ NCNC to wa ni Abẹokuta ati agbegbe rẹ pe wọn ko gbọdọ ba Alake naa ṣe. Wọn ni bo ba n ṣe ohunkohun awọn ko ni i debẹ, awọn ko ni i de aafin rẹ bo pe awọn si ṣiṣe, nibi yoowu ti wọn ba si ti gbọ pe o n bọ, awọn ko ni i lọ sibẹ, ko si kinni kan ti yoo gbe awọn pade ara wọn, nitori awọn ko fẹẹ ri i. Njẹ ki lo de, wọn ni Ọba Gbadebọ ti sọ ni gbangba pe oun ni baba ẹgbẹ awọn Dẹmọ, ọba to ba si jade to le sọ iru rẹ ki i ṣe ọba ti oloṣelu gidi gbọdọ sun mọ, kaka ki awọn sun mọ ọn, awọn yoo ba awọn ọba mi-in ti wọn ki i ṣe oloṣelu ṣe ni. Eyi fi han pe Okpara ko ni i ya sọdọ Alake.
Bi ilẹ ti n mọ lọjọ keji, iyẹn ọjọ keji, oṣu kẹfa, ni 1964, Okpara gbera lati Eko, o dọna Ibadan, o ni ọjọ iku ẹni ki i pe ka yẹ ẹ, ohun ti yoo ba ṣẹlẹ ko ṣẹlẹ ki awọn ri i. Oun nikan kọ lo n lọ o, awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu rẹ tẹle e, wọn si fi imu mọto kaa kan idi ara wọn bayii debii pe ko si alafo kan ti ẹni kan yoo gba, tabi ẹni to le da wọn duro bi wọn ti n lọ. Afi nigba ti wọn de Ikorodu ti awọn ero ya jade bo wọn, ko si sẹni to da awọn ọlọpaa ti wọn duro kaakiri lohun, ariwo, “Aawo! Okpara! Aawo! Eeji On Tọọ (AG on Top)!” Lawọn eeyan naa n pa. Ohun ti wọn ṣe n pariwo orukọ Ọbafemi Awolọwọ, ti wọn si tun n pariwo ti Okpara mọ ọn ni pe wọn ti gbọ pe ẹgbẹ AG ati NCNC yoo jọ ṣe ajọṣepọ, awọn ni wọn yoo si gbajọba kuro lọwọ Akintọla ati awọn Sardauna to n yọ wọn lẹnu, ti wọn yoo si da Awolọwọ pada fun wọn.
Iyẹn ni wọn ṣe ri Okpara bii ọkan ninu awọn ọmọ Awolọwọ, ti wọn si n pariwo rẹ bo ṣe n kọja lọ laarin wọn. Awọn ọlọpaa ti wọn ni ki wọn ṣe nnkan kan paapaa ko le ṣe kinni kan, apọju ero ko jẹ ki awọn naa le na kondo tabi ibọn soke, awọn naa mọ pe bi awọn ba ṣe bẹẹ, iye ọlọpaa ti yoo ku yoo ju awọn ti wọn wa laaye lọ. N ni kaluku ba yaa gbe jẹẹ, awọn naa sọ ara wọn di ero iworan, wọn n woran ohun to n lọ bawọn eeyan naa ṣe n sare tẹle mọto Okpara. Ọrọ naa yatọ ni Ṣagamu ati Ipẹru, nitori awọn ero ko jẹ ki Okpara kọja, wọn ni afi ko ba awọn sọrọ. Okpara ba wọn sọrọ, o fi wọn lọkan balẹ pe kinni kan ko ni i ṣe, awọn yoo gbajọba West kuro lọwọ awọn ti wọn n ṣe yii, nitori ile onile lawọn eeyan naa waa ya lo, wọn ki i ṣe ẹni to yẹ ko wa nibi ti wọn wa yẹn, awọn oloṣelu ti wọn waa lu araalu ni jibiti ni gbogbo wọn.
Ibadan ni kaluku ti fọkan si pe bi wahala kan ba fẹẹ ṣẹlẹ, nibẹ ni yoo ti waye. Nitori bẹẹ, awọn eeyan ti mura ki wọn too de Ibadan, wọn si ti ba ara wọn sọrọ ki wọn ma ba ẹnikẹni ja, ki wọn jẹ ki awọn ọlọpaa tabi ṣọja ti wọn ba wa loju ọna ṣe iṣẹ ọwọ wọn. Nigba ti wọn de Idi-Ayunrẹ, iyẹn maili mejila si ilu Ibadan nigba naa, wọn kan awọn ọlọpaa ti wọn to sibẹ bii esu, bẹẹ ni wọn si gbegidina pe ko si mọto kankan ti yoo kọja lọ. Kia lawọn eeyan bẹrẹ si ya bọ silẹ, nigba ti awọn ọlọpaa funra wọn si ri awọn igiripa ati gende ọkunrin ti wọn n fo bọ silẹ ninu mọto, ti awọn oloṣelu kọọkan naa si n jade, pẹlu awọn ọlọpaa ti wọn n ṣọ wọn, kia lawọn ọlọpaa naa tun ero wọn pa. Wọn gbe igi kuro loju ọna, wọn ni mọto kan lawọn yoo jẹ ko kọja laarin iṣẹju kan, awọn ko ni i jẹ ki mọto kan sare tẹle ara wọn leralera.
Eleyii ko ni itumọ kan, ṣugbọn bẹẹ ni wọn ṣe, awọn oloṣelu NCNC naa ba awọn eeyan wọn sọrọ, wọn ni ki wọn jẹ ki awọn ọlọpaa naa tẹ ara wọn lọrun. Ṣugbọn ọrọ naa su awọn ọlọpaa funra wọn nigba to ya, lẹyin ti mọto bii ọgbọn si ti kọja ni wọn ṣina fun awọn to ku pe ki wọn maa lọ. N lawọn mọto bii ọgọta ba rọ wọ ilu Ibadan lẹẹkan naa. Ibadan ni wọn ti ṣe ofin pe ki ẹnikẹni ma jade, ṣugbọn nigba ti awọn Okpara yoo fi yọ si ilu naa, oju titi ti daru pata. Awọn ero ti debẹ ni, wọn si to lati Orita titi de ile Awolọwọ ni Oke-Ado, nitori nibẹ ni awọn Okpara kọkọ n lọ. Eto ti wọn ti ṣe silẹ naa ni pe ile Awolọwọ ni wọn yoo kọkọ lọ, nibi ti wọn yoo ti sọ faye pe ajọṣe ti bẹrẹ laarin ẹgbẹ NCNC ati AG, ati pe awọn yoo jọ ṣe ajọṣepọ lati dibo to n bọ nipari ọdun naa ni, iyẹn ibo awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin apapọ.
Iyẹn lo fa a to fi jẹ pe ọna ile Awolọwọ yii lawọn eeyan wa, nibẹ ni wọn dorikọ. Awọn ọlọpaa wa nibẹ o, bẹẹ ni awọn ṣọja naa n yipo kaakiri, ṣugbọn ko sẹni to le da awọn ero naa duro, nitori wọn ti pọ ju ẹni to le ṣee da duro lọ. Kinni kan waa ṣẹlẹ niwọnba asiko ti Okpara fi kuro l’Ekoo to fi gba ọna Ibadan lọ yii. Awọn ọlọpaa ti ri awọn ero to n wọ lẹyin ọkunrin naa, wọn si ti ri i bi awọn araalu ko ṣe dakẹ mọle, to jẹ wọn n jade ni. Iroyin ti kan ọga ọlọpaa pata, koda, ọrọ naa ti de eti olori ijọba, iyẹn Tafawa Balewa, ohun ti wọn si n sọ funra wọn ni pe ta lo ṣofin koni-legbele yii gan-an, pe ti wọn ko ba tete pa ofin naa rẹ, ti ohunkohun ba ṣẹlẹ, ti ẹnikẹni ba ku, tabi ti wọn ba bẹrẹ rogbodiyan nibi kan, ọga ọlọpaa funra rẹ yoo jade lati rojọ ẹni to ṣofin konile-gbele, ki-ẹlẹsẹ-ma-rin ni Western Region. N lawọn ọlọpaa ba sare jade.
Bi wọn ti jade ni wọn n kede lori redio kaakiri, wọn ni ko si ofin konile-gbele, tabi ki ẹnikẹni ma ṣepade, tabi ki ẹnikẹni ma rin irin ẹsẹ rẹ ni West, iru ofin bẹẹ ko ti ile iṣẹ ọlọpaa jade o. Awọn ọlọpaa ni ikede ti awọn n ṣe yii, ileeṣẹ ọga ọlọpaa pata lo ti jade o, ohun ti awọn si n wi ni pe ki onikaluku rin irin ẹsẹ rẹ, ko si ofin to de ẹnikẹni ni Western Region. Wọn ni awọn mọto ti wọn n lọ si ọna Ibadan ti awọn ọlọpaa n da duro, wọn kan n da wọn duro lati ri i pe ko si sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ni o, ki i ṣe nitori ofin kankan. Wọn ni ileeṣẹ ọlọpaa ko kọwe jade, bẹẹ ni ko sofin kankan, ẹni to ba si ni iwe ti awọn ọlọpaa kọ jade lati fi sọ pe ki ẹlẹsẹ ma rin ni West, ki wọn mu iru iwe naa jade ki awọn le mọ ẹni to fọwọ si i, tabi ẹni to kọ ọ. Wọn ni atẹjade yii waye nitori ki awọn ti wọn n pariwo pe ọlọpaa ṣofin le mọ pe ko sohun to jọ bẹẹ ni o.
Bo tilẹ jẹ pe awọn aṣaaju NCNC ati AG mọ pe irọ gbuu lawọn ọlọpaa n pa pe awọn mọto ti wọn n da duro lona Ibadan, nitori gosiloo ni, sibẹ nigba ti ikede yii jade, idunnu gbaa lo jẹ. Wọn ti mọ pe awọn ti ni anfaani bayii lati jade lọ si ibi to ba wu awọn, awọn si ni afaani lati lọọ pade olori ẹgbẹ oṣelu awọn, ti ko sẹni kan to gbọdọ beere ibi ti awọn n lọ, tabi ti yoo waa di awọn lọwọ irin ẹsẹ awọn. O kan jẹ pe bi inu tiwọn ti n dun ni inu n bi Samuel Ladoke Akintọla, Olori ijọba West yii ni. Ọrọ naa ko si le ṣe ko ma bi i ninu nitori bii igba pe wọn fi abuku kan an ni. Oun naa mọ pe iṣẹ naa ki i ṣe ti Sardauna, o mọ pe Balewa ati Azikiwe ni wọn ṣe iru nnkan bẹẹ yẹn, awọn ni wọn paṣẹ fun ọga ọlọpaa, tabi ti wọn kilọ fun un pe ko ma tẹle ofin konile-gbele ti wọn ṣe ni West. Ọrọ naa dun un.
Ṣe Akintọla ti mọ tipẹ pe Tafawa Balewa ko fẹran oun, ko fẹ ọrẹ ti oun n ba Sardauna ṣe, ati pe ọpọlọpọ ohun to n ṣẹlẹ ni West, ọkunrin Balewa yii ko fi ara mọ ọn. Ṣugbọn bi eeyan ba ti mọ ẹkun, ogidan oloola-iju, a-kọmọ-lailabẹ, ko tun si ohun ti yoo mu un bẹru ologinni to n gbenu ile, Akintọla mọ pe bi Sardauna ba ti wa lẹyin oun, ko si ohun ti Balewa yoo ṣe. Nidii eyi ni wọn ṣe paṣẹ konile-gbele, kẹlẹsẹ-ma-rin, ti wọn pa. Ki i ṣe ọga ọlọpaa lo paṣẹ naa, ẹnikan ko si mọ ibi ti aṣẹ naa ti jade. Ṣugbọn bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ri iwe kan gba, awọn ọlọpaa Western Region ti bẹrẹ si i tẹle ofin naa, wọn ti fẹẹ maa yọ awọn ti wọn n rin irin ẹsẹ wọn lẹnu. Afi nigba ti ọga awọn ọlọpaa pata yii sọrọ, ti wọn si da Akintọla ati awọn eeyan rẹ lọwọ kọ, ti wọn ni ki wọn sinmi giragria ti wọn n ṣe. Iyẹn lọrọ yii ṣe dun Akintọla.
Nitori bi ọrọ naa ti jade sita ni ariwo tuntun bẹrẹ n’Ibadan, nigba ti Okpara yoo si fi de Oke-Ado, ẹsẹ ko gbero mọ, awọn ti wọn n rin n rin, awọn ti wọn n sare n sare, wọn ni wọn yoo ba Okpara, Olori ẹgbẹ NCNC, de ile Awolọwọ kẹlẹlẹ.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.