N’Ibadan, asofin merindinlogun ni Ladoja ko lo sinu egbe ADC *O lawọn gomina kan n bọ ninu egbe naa laipe *Lawon PDP ba jo lo sodo Akala

Spread the love

Lọjọ kẹta, oṣu kẹjọ, ọdun 2018 yii, iyẹn lọjọ Jimọh to kọja ni gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Sẹnitọ Rashidi Adewọlu Ladọja, kede pe oun ko ṣẹgbẹ oṣelu Alaburada (PDP), mọ, ẹgbẹ àgbájọ ọwọ́, iyẹn African Democratic Congress (ADC), lo loun n ba lọ. Ọpọ eeyan lọrọ naa ba lojiji, awọn to sun mọ agba ijoye ilẹ Ibadan yii daadaa mọ pe lati nnkan bii oṣu meji sẹyin ni baba naa ti fi ẹgbẹ oṣelu Alaburada silẹ, o kan n fi koronfo ara lasan ṣẹgbẹ naa tẹlẹ ni.

 

Ipade oṣelu kan waye nile aarẹ orileede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja. Ipade aṣiri ni, nitori wọn tilẹkun mọri ṣe e ni. Ladọja wa ninu awọn to ba Ọbasanjọ ṣepade ọhun pẹlu awọn mẹta kan ti wọn ti ṣe akọwe agba ijọba ipinlẹ Ọyọ ri, Oloye Ọlayiwọla Ọlakojọ, Ọmọwe Busari Adebisi ati Amofin Sarafadeen Alli.

 

Diẹ ninu awọn to ṣẹṣẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn jẹ igun Unity Forum ninu ẹgbẹ ọhun ni ipinlẹ Ọyọ naa wa ninu apero ọhun. Awọn bii Sẹnitọ Mọnsurat Sumọnu, ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba ilẹ yii; Ọnarebu Musa Abdulwasiu ti i ṣe igbakeji abẹnugan ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ atawọn aṣofin ipinlẹ ọhun mi-in bii Ọnarebu Muideen Ọlagunju; Bọlaji Badmus; Fatai Adesina; Ọnarebu Akeem Ọlatunji Ọnarebu Afeez Adeleke pẹlu Alhaji Kayọde Adanla.

 

Bo tilẹ jẹ pe l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja ni alaga apapọ ẹgbẹ ADC nilẹ yii, Ọmọwe Ralphs Okey Nwosu, Ladọja, atawọn to ko wọnu ẹgḅẹ tuntun naa kede orukọ awọn eeyan ti wọn yan sinu igbimọ ti yoo ṣeto idibo awọn alakooso ẹgbẹ naa lati wọọdu titi dori ibo awọn alakooso ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ lapapọ. Ninu ipade ti wọn ṣe nile Ọbasanjọ ṣaaju ọjọ naa ni wọn ti ṣagbekalẹ igbimọ naa, to jẹ niṣe ni wọn kan kede ẹ faye gbọ n’Ibadan lọjọ Tọsidee to kọja.

 

Dokita Fẹmi Majẹkodunmi, oloṣelu ipinlẹ Ogun, to jẹ ọkan pataki ninu awọn ọmọ ẹyin Ọbasanjọ ni wọn yan gẹgẹ bii alaga igbimọ ẹlẹni mẹsan-an ọhun. Awọn yooku ninu igbimọ ọhun ni Dokita Dele Ajadi (akọwe), Ọmọwe Busari Adebisi ati Ẹni-Ọwọ Ezekiel.

 

Gbogbo bi awọn eeyan ṣe n sọrọ to ninu ipade nla ọhun to waye ni gbọngan nla ileetura Nest, l’Agodi, n’Ibadan, ti kaluku n fọnnu pe ẹgbẹ awọn tuntun yii yoo gbajọba akoso ipinlẹ Ọyọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lọwọ, Ladọja ko sọ gbolohun kan, afi ninu ipade mi-in to ṣe pẹlu awọn alatilẹyin ẹ ninu oṣelu lọjọ keji, iyẹn ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, nibi to ti ṣalaye idi to ṣe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ, to diyawo tuntun ninu ẹgbẹ ADC.

 

Oṣu yii gan-an lo pe ọdun kan bayii ti Ladọja pada sinu ẹgbẹ PDP latinu ẹgbẹ Accord Party to gba lọ lẹyin to kọkọ kuro ninu ẹgbẹ PDP lẹyin idibo ọdun 2011. Inu oṣu kẹjọ, ọdun 2017, lo pada sinu ẹgbẹ PDP, ko too tun kọ wọn silẹ ninu oṣu kẹjọ, ọdun yii, o ni iwa ta-ni-yoo-mu-mi pọ lọwọ awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ naa, wọn ko si ka oun si pataki to bo ṣe yẹ.

 

Nigba to n ba awọn alatilẹyin ẹ sọrọ nile ẹ laduugbo Bodija, n’Ibadan, Ladọja, ẹni to sọ pe oun ko ni i dupo gomina ipinlẹ Ọyọ mọ sọ pe ẹgbẹ ADC ti oun ṣẹṣẹ darapọ mọ yii ti gbe iṣẹ nla le oun lọwọ yatọ si ẹgbẹ PDP ti wọn kan pa oun ti bii ẹni ti ko lákàsí oun. Lara awọn to wa ninu ipade ọhun ni Sẹnetọ Fẹmi Lanlẹhin, Amofin Sarafadeen Alli, Amofin Bayọ Lawal ati mẹrindinlogun (16) ninu awọn aṣofin mejilelọgbọn (32) to wa nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ.

 

O ni laipẹ rara si asiko yii, bii meloo kan ninu awọn gomina to n ṣejọba ipinlẹ wọn lọwọlọwọ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC yoo fi ẹgbẹ naa silẹ lati waa darapọ mọ ẹgbẹ ADC, oun Ladọja loun yoo si gba wọn lalejo sinu ẹgbẹ naa gẹgẹ bii eto ti oun pẹlu Ọbasanjọ jọ ṣe nile ẹ, l’Abẹokuta.

 

Ladọja fidi ẹ mulẹ pe ajọsẹpọ ṣi maa wa laarin ẹgbẹ PDP ati ADC loke lọhun-un, nitori ẹgbẹ mejeeji ti jọ tọwọ bọwe adehun lati fa ẹni kan ṣoṣo kalẹ lati dije dupo aarẹ ilẹ yii ninu idibo ọdun 2019. O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ADC ipinlẹ Ọyọ lati lọọ maa mura silẹ de idibo lati yan awọn oloye wọọdu ẹgbẹ yii ti yoo waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, oni, ati idibo adari ẹgbẹ naa nijọba ibilẹ, eyi ti yoo waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọla, titi dori idibo awọn ti yoo maa ṣakoso ẹgbẹ naa kaakiri ipinlẹ Ọyọ, eyi ti yoo waye lopin oṣẹ yii, iyẹn Satide, ọjọ kọkanla, oṣu yii.

 

Latigba ti awuyewuye ti waye nigba bii meji ọtọọtọ pe Ladọja fẹẹ kuro ninu ẹgbẹ PDP, ṣugbọn ti ọrọ naa jọ bii ahesọ lasan lo jọ pe ẹgbẹ oṣelu Alaburada ti su baba naa loootọ to si ti n dọgbọn foju wa ẹgbẹ mi-in to le darapọ mọ.

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.