Ni ti Raufu Arẹgbẹṣọla

Spread the love

Bi a ba da ogun ọdun, yoo pe ni o, bi a si da ọgbọn oṣu, yoo pe naa ni o. Ko si ọjọ kan ti a da ti ko ni i pe ti ẹmi wa ba ṣi n bẹ, nitori bi ilẹ ti n mọ naa ni ilẹ n ṣu, ọlọjọ si n kajọ, ẹda ni ko fiye si i. Iyẹn ni Ọlọrun fi ju ẹda lọ. Bi ẹni kan ba wa ni ipo kan to ba ro pe ibẹ ni oun yoo wa titi aye oun, ẹ sọ pe o n tan ara rẹ jẹ ni, nitori bi oun ko ba fi ipo silẹ, ipo naa yoo fi i silẹ lọjọ kan ni. Raufu Arẹgbẹṣọla ti fi ọdun mẹjọ ṣe kọmiṣanna l’Ekoo ko too waa ṣe gomina l’Ọṣun, o si ti fọdun mẹjọ bayii ṣe gomina l’Ọṣun, Arẹgbẹṣọla n pada lọ sile rẹ. Ohun to ku ti awọn onpitan yoo maa yẹwo bayii ni bo ṣe ṣe ijọba rẹ, awọn ohun to ṣẹlẹ lasiko to n ṣejọba, boya ijọba naa dara tabi ko dara. Ṣugbọn eyi o wu ka wi, Arẹgbẹsọla ti ṣe iwọnba to le ṣe. Ọkunrin gomina naa ni fun ọdun mẹjọ ti oun fi ṣejọba, oun ko gba kọbọ gẹgẹ bii owo-oṣu, nitori ijọba lo n bọ oun, ijọba lo n sanwo mọto ti oun n gun, ijọba lo n ra epo si i, ijọba lo si n gbọ gbogbo bukaata oun. Nitori bi ọrọ oṣelu Naijiria ti ri, to jẹ oju ole ni aye fi n wo gbogbo oloṣelu, yoo ṣoro lati gba iru ọrọ bayii gbọ. Ṣugbọn bo ba jẹ ootọ ni Arẹgbẹ sọ, bi gbogbo aye ba pe e ni opurọ, Ọlọrun mọ pe olododo ni nidii eyi, ẹsan to ba si tọ si i, Ọlọrun yoo san an fun un. Koko ibẹ ni pe igba ko tọ lọ bii orere, aye ko tọ lọ bii ọpa ibọn, ọba mẹwaa igba mẹwaa ni, ko si oke ti eeyan gun ti ko ni i sọ kalẹ, bi ko ba sọ kalẹ lọwọ ẹrọ, yoo jabọ, bi aye ti ri niyẹn. Boya ọkunrin yii ṣe daadaa nipo gomina tabi ko ṣe daadaa, aṣiri oriṣiiriṣii yoo bẹrẹ si i tu bayii, bi ẹni to n bọ yii ko ba sọ ọ, awọn ti yoo tẹle e yoo sọ ọ, wọn aa ni Arẹgbẹ lo ba ilu yii jẹ bayii, tabi ki wọn ni Arẹgbẹṣọla lo ba wa tun Ọṣun ṣe. Oun ko ni i lagbara kan ti yoo lo lori ẹnikẹni mọ, afi ẹni to ba n fun un ni ọwọ nikan. Koda gomina to ja lati fi sipo le kọyin si i, nitori bi aye ti ri niyẹn. Nidii eyi, ko si ohun ti ẹda le ṣe ju ko ṣe daadaa nigba to ba wa nipo kan lọ. Arẹgbẹṣọla ti ṣe tirẹ, o n lọ o, ẹyin ara Ọṣun, ẹ ku amojuba gomina tuntun.

 

 

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.