Ni ti Purofẹsọ to fẹẹ ṣe ṣọkiṣọki

Spread the love

Awọn alaṣẹ ileewe giga Yunifasiti OAU ti kede pe wọn ti da Ọjọgbọn Richard Akindele duro lẹnu iṣẹ fun igba pipẹ na, iyẹn ẹni to loun fẹẹ ba ọmọleewe kan sun ki oun le fun un ni maaki, nitori pe iyẹn ko paasi iṣẹ to ṣe. Yunifasiti ni awọn ṣi n ba iwadii ọrọ naa lọ ni, ṣugbọn awọn ti kọkọ fi ẹsẹ rẹ mulẹ pe Akindele lo n sọ gbogbo ọrọ (ẹẹmarun-un ni mo gbọdọ ba ẹ sun bo o ba fẹẹ paasi!) yẹn sinu foonu, orukọ ọmọbinrin to si fẹẹ ba sun naa ni Monica Osagie. Iyẹn ni ki oun too gba ohun ẹ silẹ, to si fi da bii pe oun ṣe akoba fun un yii, oun ti gbiyanju lati fi ẹjọ ẹ sun awọn olukọ ẹgbẹ ẹ meji, pe ki wọn ba oun kilọ fun un, ṣugbọn pabo lo ja si, o taku pe afi ti oun ba ba oun sun dandan. Bi iru iṣẹlẹ bayii ba waye, a maa dun-un-yan titi, nigba ti ẹni to ti fi ọpọlọpọ ọdun ṣe iṣẹ, to ti kọkọ kawe titi ko too di purofẹsọ, ba waa da aye rẹ ru nitori iru awọn nnkan bayii, ọrọ naa a maa ka ni lara. Amọ ohun ti aanu yoo ṣe ṣoro o ṣe lori ọrọ naa ni pe ko le jẹ akọkọ ti Akindele yoo ṣe kinni naa ree, o ti maa n fi maaki ba awọn ọmọ sun tipẹ, o si jọ pe kinni naa to asiko loju Ọlọrun lati tu aṣiri ẹ ni. Nigba ti olukọ ba n ba awọn akẹkọọ rẹ sun, tabi to n gba abẹtẹlẹ kankan lọwọ wọn lati fun wọn ni maaki, ko tun aye iru awọn akẹkọọ bẹẹ ṣe, o n ba wọn laye jẹ ni. Bi ọkunrin ba wa, to ba ri obinrin to ba wu u, ki i ṣe ẹṣẹ lati ba ara wọn sọrọ ifẹ, nigba to ba ti jẹ agbalagba lawọn mejeeji. Eyi to jẹ ẹṣẹ ni ka fẹẹ fipa mu obinrin olobinrin, tabi ọmọ ọlọmọ, paapaa ni ọna ti yoo ba aye iru ẹni bẹẹ jẹ. Lọna keji, rẹfurẹndi tabi pasitọ ni ọkunrin yii pe ara rẹ, nibi ti aye ti dorikodo niyi, nitori bi ẹ ba ba a ni ṣọọṣi, oun ni yoo maa pariwo pe o lodi si ofin Ọlọrun lati niyawo meji, ọmọ Ọlọrun ko gbọdọ ṣe agbere, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Oun lo delẹ yii o. Akindele ba orukọ ara rẹ jẹ, o ko itiju ba awọn ọmọ ati iyawo rẹ, pẹlu awọn ọmọ ijọ ṣọọṣi to n lọ, yoo si ṣoro ki ẹwu abuku yii too kuro lọrun rẹ laelae. Ẹkọ niyi fun awọn tiṣa oniṣọkiṣọki ni yunifasiti, ẹ yee ba aye awọn ọmọ ọlọmọ ti wọn ni kẹ ẹ kọ lẹkọọ jẹ; ati awọn ti wọn n fi orukọ Ọlọrun boju tan gbogbo aye jẹ, ti wọn n ṣofin agbere, ti wọn tun n ṣe ṣọkiṣọki lẹyin, ọkọọkan laṣiri yin yoo maa tu!

(112)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.