Ni ti Ọọni, Alaafin ati Aarẹ Ọna Kakanfo

Spread the love

Latigba ti mo ti n sọrọ aṣaaju Yoruba, igba kan ma fẹrẹ kọja ti n ko ni i gba atẹjiṣẹ lori awọn ọba ilẹ wa, paapaa awọn aṣaaju ọba meji ta a ni, Ọọni ati Alaafin, pẹlu Aarẹ Ọna Kakanfo. Atẹjiṣẹ ti mo n gba naa ni pe iru awọn to yẹ ko ṣe aṣaaju fun Yoruba ti mo n wi niyi, iru awọn ọba to yẹ ko ko Yoruba lọ sibi ti mo fẹ niyẹn, awọn ọba to laṣẹ lẹnu. Loootọ ni. Ko si ohun ti iba wu mi bi ki ẹni kan ninu awọn mẹtẹẹta yii jẹ aṣaaju fun Yoruba. Idi ni pe awọn mẹtẹẹta ni wọn ti di ipo naa mu ri, ti wọn si ko Yoruba debi to dara. Ni ibẹrẹ pẹpẹ, Oduduwa ni olori gbogbo wa, aṣẹ ti Oduduwa ba pa ni gbogbo Yoruba to ku yoo tẹle nibikibi ti wọn ba wa, bo ba ti paṣẹ bayii, aṣẹ naa yoo mulẹ ni. Ẹni to ba si fẹẹ mọ bi agbara yii ti pọ to ko ranti igba tawọn ilu Ibinni (Benin) n wa olori, to jẹ  Oduduwa ni wọn waa ba ko fun wọn lọba.

Tabi ta ni yoo sọ pe oun ko mọ agbara Alaafin nilẹ Yoruba wa yii. Igba kan ti wa to jẹ o fẹrẹ ma si ibi kan ni ilẹ Yoruba ti agbara ọba nla yii ko de, koda awọn ti wọn ko si labẹ rẹ gan-an, bo ba paṣẹ, wọn ko to ẹni ti i da a kọja. Alaafin lo nilẹ, oun ni ọba, oun naa si ni olori ilu, ohun gbogbo to ba sọ, aṣẹ ni. Asiko tirẹ ni ilẹ Yoruba ran kaakiri, ti ijọba rẹ bẹrẹ lati ilẹ awọn Tapa, titi to fi de orilẹ-ede Ghana, ti awọn ti wọn ko si sun mọ ilu Ọyọ rara n fi orukọ Alaafin ṣe ohun gbogbo ti wọn ba fẹẹ ṣe. Bo tilẹ jẹ pe nigba ti Alaafin yoo fi maa ṣe olori ilẹ Yoruba yii, awọn ọmọ Oduduwa ti fọnka, sibẹ, ọba yii fi agbara rẹ ko gbogbo wọn si abẹ ara ẹ, o si n ṣe akoso ilẹ naa, ti ko si sẹni to le beere pe bawo lo ṣe ṣe e, tabi ti yoo sọ pe oun o ni i tẹle aṣẹ to ba pa. Eyi ni pe bi Alaafin ṣe olori ilẹ Yoruba lasiko ta a wa yii, ko sohun to buru nibẹ.

Tabi ti Aarẹ Ọna Kakanfo la fẹẹ sọ ni. Bi ẹnikan ba wa ti Alaafin funra rẹ maa n bẹru ni kọrọ, Aarẹ ni. Idi ni pe ko si ọba, bi ko ba si jagunjagun laye igba naa: bi awọn jagunjagun ba ti to naa ni agbara ati iyi ọba kan n to, ọba ti ko ba le jagun ki i ṣe ẹni ti wọn yoo bẹru nibi kan. Bi wọn o ba si bẹru ọba, ko si iyi ti wọn yoo fun un. Alaafin funra rẹ ko ni i lọ soju ogun, Alaafin yoo ṣigun ni, ẹni ti yoo si paṣẹ yii fun naa l’Aarẹ Ọna Kakanfo, tori o ti mọ pe yoo lọ soju ogun naa, yoo si ṣẹgun. Bi agbara Aarẹ kan ba ti to ni iyi ati ibẹru oun naa n to, nitori ẹ lo ṣe jẹ ẹni ti o ba loogun, ti ko si le jagun, ko ni i jẹ aarẹ ọna kakanfo igba naa, ipo awọn alagbara ni. Ko si aarẹ igba naa kan ti wọn fi jẹ ti ki i ṣe alagbara, ajagun-ṣẹgun ni wọn. Bo ba si jẹ bi nnkan ṣe wa nigba naa lo ṣi wa lasiko yii ni, Aarẹ to lati ko ọmọ Yoruba jẹ, o too ṣe olori wa daadaa.

Ṣugbọn nnkan ti yatọ pata, aye ti kuro lọwọ awọn wọnyi, awọn mi-in ti n gba iṣẹ wọn ṣe. Lati igba ti iyapa ti de ba awọn ọmọ Yoruba ni iyi ti Ọọni ni ko ti to ti tẹlẹ mọ, nigba ti gbogbo wọn ti kuro ni ile baba wọn. Kaluku n ṣe tirẹ lọtọ ni, agbara naa si pọ de gongo, agaga nigba ti Oduduwa funra rẹ dagbere faye. Awọn ọmọ rẹ ko ri ara wọn bii ọmọ baba kan naa mọ, kaluku n ṣe ohun to ba fẹ ni adugbo tirẹ ni. Bi iran kan ba wa, tabi tawọn eeyan kan ba wa, tabi orilẹ-ede kan lo wa, nibi ti onikaluku ti n ṣe tiẹ lọtọ, iṣọkan yoo jinna si wọn, bi iṣọkan ba si ti jinna si wọn, ko le ṣoro kapa awọn ọta too ka wọn. Nigba ti iṣoro ti wa lati ṣakoso Yoruba lati Ile-Ifẹ ti i ṣe orirun gbogbo wa, igba naa ni ko ti si ẹnu kan lati fi sọrọ mọ: iyapa ẹnu wa ninu iwa ati iṣe wa. Ọọni ko lagbara bii tatijọ mọ, awọn oloṣelu ti gba iṣẹ ẹ ṣe.

Nigba tawọn oyinbo de, ọwọ ẹni ti wọn ba agbara ni Alaafin, bo tilẹ jẹ pe awọn ilẹ Yoruba mi-in, paapaa Ibadan, ti dide gẹgẹ bii alagbara lagbegbe wọn, iwọnba agbara to ku lọwọ Alaafin lo fi n paṣẹ. Nitori ẹ lo ṣe jẹ pe nigba ti wọn ti gba Eko, ti wọn kapa Ijẹbu, Ọyọ ni wọn lọ taara lati kori Alaafin sabẹ. Wọn ba Alaafin igba naa ja, wọn si tẹ ori ẹ ba ti ko fi le ṣe ohunkohun yatọ seyii tawọn oyinbo ba fẹ. Agbara ibọn ati ka sọ ọba to ba ṣagidi sẹwọn, ka rọ ọ loye, ka le e kuro niluu, lawọn oyinbo yii fi ṣẹruba awọn ọba wa, ati ọba gbogbo ni Naijiria paapaa, eyi o si jẹ kẹnikẹni ninu wọn laya lati dojukọ wọn. Ohun tawọn oyinbo yii foju Adeyẹmi akọkọ ri lo n lọ yii, ko si sẹni ti ko gbọ itan pe ijọba awọn Awolọwọ lo yọ Adeyẹmi Keji kuro lori oye, ohun toju Alaafin Kẹta to wa lori oye yii naa si ti ri lọwọ awọn oloṣelu, oun nikan lo le sọ.

Ni ti Aarẹ Ọna kakanfo, agbara awọn naa ti di otubantẹ nigba ti ko ti sagbara lọwọ Alaafin mọ. Tabi ogun wo ni Aarẹ kan ja ni ko-pẹ-ko-pẹ yii, awọn wo lo si ba jagun. Lati aye Akintọla, nigba ti Alaafin Gbadegẹṣin Ladigbolu fi i jẹ Aarẹ, ko si kinni kan to le ṣe, ohun to tiẹ jẹ ki agbara rẹ han saye diẹ ni pe olori ijọba ilẹ Yoruba (Western Region), loun nigba naa, oṣelu lo fi i ṣe olori ijọba. Nigba tọrọ naa kan Mọshood Abiọla, loootọ olowo nla loun, sibẹ, ko ni agbara kan lati fi ṣe akoso ilẹ Yoruba, nitori nigba ti oun naa n joye yii, ọpọ awọn gomina ologun ilẹ Yoruba igba naa ko debi ti wọn ti fi i jẹ. Ọrọ naa dun Abiọla, o si sọ ọ mọrọ pe ki odidi Aarẹ Ọna Kakanfo maa jẹ nilẹ Yoruba kawọn gomina ibẹ ma wa, ohun ti ko daa ni. Lati fi han Abiọla pe awọn ko mọ agbara Aarẹ, awọn ṣọja kan ya lọ sile rẹ ni bii oṣu keji to jẹ Aarẹ.

Wọn ni Kọla ọmọ rẹ ri awọn fin, wọn lu gbogbo awọn ara ile ẹ ni ilukulu ni o, wọn da Abiọla funra ẹ jokoo silẹẹlẹ, arifin naa si ba awọn eeyan lẹru, nitori olowo l’Abiọla, ọrẹ Babangida to n ṣejọba si ni. Ṣugbọn wọn ko ri awọn ṣọja ti wọn kọlu u yii mu, wọn ni awọn ṣọja ti wọn ko mọ ni (Unknown Soldiers). Ọrọ naa di awada laarin Abiọla atawọn ijoye Ọyọ ti wọn lọọ ki i nigba ti wọn sọ fun un pe Aarẹ ki i sa fun ogun o! Abiọla ni ko si Aarẹ kankan loju ibọn ṣọja o, afi ti a ba n tan ara wa jẹ. Ohun naa lo  ṣẹlẹ nigba ti wọn n fi Gani Adams jẹ Aarẹ yii. Gomina meloo lo wa nibẹ, bẹẹ gbogbo wọn lo to orukọ wọn sinu iwe-ipe, Siaka kan ṣoṣo to wa nibẹ binu kuro ni, o ni Olubadan roun fin. Ọmọ Ibadan si ni o, bo ba si l’Olubadan roun fin, o yẹ ki kaluku ti mọ pe nnkan ti ṣẹlẹ si Yoruba. Awọn ọba wa o jẹ kinni kan loju awọn oloṣelu yii rara.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọba ilẹ Hausa niyi daadaa loju awọn eeyan wọn, ati loju ẹni yoowu to n ṣejọba, ọrọ awọn ọba ti Yoruba ko ri bẹẹ rara. Igba kan wa to jẹ Sultan ilẹ Sokoto lo da bii olori ijọba Naijiria, nitori igbakigba to ba yọju si awọn olori ijọba, wọn yoo dide fun un ni, titi de ori awọn Babangida yii nigba ti Dasuki fi n ṣe Emir, ko too di pe Abacha kan iyẹ olori awọn ọba ilẹ Hausa naa.  Koko ohun ti mo n sọ ni pe iṣoro ni fun wa lati reti aṣaaju Yoruba lọdọ Ọọni tabi Alaafin, ka ma ti i sọ Aarẹ Ọna Kakanfo, nitori awọn oloṣelu ti gba agbara wọn lọwọ wọn. Bi ofin ti ṣe eto naa loni-in niyi, alaga ijọba ibilẹ ti ọba kan ba wa lagbara ju u lọ. Alaga ibilẹ ni olori ọba, ko si ti i kan kọmisanna fun eto ọrọ oye, ka ma ti i sọ alaṣẹ pata, iyẹn gomina ipinlẹ wọn. Bi gomina kan ba bu ramuramu, ko si ọba kan to gbọdo duro.

O jọ pe ohun to n jẹ kawọn kan ronu pe ka mu oloṣelu ṣe aṣaaju Yoruba niyi, iwe awọn naa pọ lọdọ mi rẹpẹtẹ. Ṣugbọn a ko le mu oloṣelu ṣe aṣaaju, nitori agbara tawọn ni ko lọ titi, bi oloṣelu kan ba wa nipo agbara loni-in ti a ba mu un, ta lo mọ oloṣelu mi-in ti yoo debẹ lọla. Paapaa julọ, awọn oṣelu ko tiẹ ṣee fi iru oye bẹẹ fun, wọn yoo fi ko gbogbo eeyan adugbo naa si abẹ wọn ni, iyẹn ko si sọ pe ki wọn tori ẹ ṣe aṣaaju naa daadaa, wọn yoo kan maa fi orukọ Yoruba lu jibiti bi wọn ti n ṣe loni-in yii naa ni. Iyẹn la o ṣe le mu oloṣelu. Bẹẹ, a gbọdọ lẹni ti yoo tọ wa sọna, ti yoo ṣaaju wa, awọn ọba wa lo si ti ha sabẹ ofin oṣelu yii. Boya bi ọrẹ mi purofẹsọ ọjọsi ṣe wi naa la o ṣe, funra wa la oo fa aṣaaju jade. Amọ bawo la oo wa ṣe ṣe e!

 

(59)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.