Ni ti ija Obasanjo ati Buhari

Spread the love

Hun-un, nigba ti oro ba da bayii, ohun gbogbo a si fee su mi. Nigba toro ba da bii pe bi a se fee fa ese wa kan to ko sinu ira, tabi koto nla, yo, bee ni ekeji tun n ko si i, igba wo ni ori ati ara wa pata ko ni i ko si koto naa. Oselu ki i se ohun to dara ni ile adulawo, agaga ni Naijiria tiwa yii, nitori awon ti a n pe loloselu nibi yii, awon ehanna, awon ole, awon to ye ki won ti fi oro le kuro niluu lo po ninu won. Eni to fee se oselu aa je ore mekunnu, aa si mura lati ran ilu re lowo. Sugbon awon oloselu ti awa ni nibi yii, ota mekunnu ni won, imura ti won si mu ko ju lati je ilu run lo. Ohun meji sele lose to koja yii to mu gbogbo e su mi, bi omije ba si wa loju eni, afi keeyan ja die sile nibe, nitori oro Naijairia yii to ekun fun agbalagba to ti ni iriri, koda, o ju ekun lo, nitori loooto ni mo wi fun yin, ibi ti nnkan n lo yii ko daa.

Awon eeyan n yo mi lenu lori oro Egbon Segun (Obasanjo). Won n beere pe se bi egbon naa ti n ba awon agbaagba Yoruba sepade yii, bo se n leri lati yo Buhari yii, won ni se o ti pada sile ni, se o ti setan to fee ran Yoruba lowo ni, se oro Yoruba ti ka a lara ni, enikan si te atejise si mi leemeji pe afi ki n soro lori egbon naa lose yii, pe awon fee mo boya ariwo ti baba awon n pa lasiko yii nipa Buhari, se nitori awon mekunnu ile yii ni. Enikan tile ni gbolohun kan loun fe ki n fi da oun lohun, pe, “Se bi Obasanjo se n jo pada sinu PDP yii daa tabi ko daa?” Nibi yii ni n oo ti bere oro. Ijo yoowu, irin yoowu, ona yoowu ti egbon yii ba gba pada sinu PDP, ko daa! Nibi ti agbalagba ba ti so pe, “O daaro”, ko tun gbodo debe se, “E kaale” mo. Ohun ti egbon fi han ni pe oloselu loun, oloselu o si lojuti.

Se e ri i, bi enikan ba jokoo sibi kan, to ba ni bi Egbon Segun ti n ba Buhari ja yii, to n pariwo pe awon fee yo o, to ba so fun yin pe nitori awon mekunnu ni, e so fun tohun pe ko gbenu e sohun-un, ko mo ohun to n so. Egbon Segun ko tori mekunnu ba Buhari ja o! Ariwo yoowu ti enikeni ba pa leti yin nipa oro yii, kinni kan ni mo mo, eyin naa si mo on, iyen ni pe n ko ni i puro fun yin laye. Mo tun so fun yin, Egbon Segun ko tori mekunnu ile yii ba Buhari ja. Bo ba so pe nitori Naijiria loun se n ba a ja, o le see se bee, awon ni won jo mo ohun ti won n pe ni Naijiria, ati ipa ti won jo n ko nibe. Sugbon boya pe egbon n ba Buhari ja nitori awa mekunnu ile yii, iro gbuu ni! Egbon n ba Buhari ja nitori Buhari ko se ohun to fe ko se, ko gboro si i lenu, ko gbamoran lowo e, ko si fi tire se, bee ni ko gbe ise gidi kan le e lowo.  

Ni oni ti ile mo yii, bi Buhari ba ranse pe Egbojn Segun, to so fun un pe oun ni ise kan ti oun fee gbe le e lowo, ko jowo, waa ba oun yanju ogun awon Boko Haram, ko maa ti orile-ede kan lo si orile-ede mi-in, ko wo bi won ti n se kinni naa ni awon ibi ti won ti de ri, ko lo si Afghanistan, ko lo si London, ko de Amerika, ko de gbogbo Europe, ko maa gbe eronpileeni ijoba Naijiria kiri, e ko tun ni i gbo nnkan kan to jo mo oro pe Buhari ko dara lenu Egbon Segun mo. Iyen ti tun jinna ju. Loni-in yii, ti Buhari ba pe Egbon Segun pe gbogbo isoro ati idaamu to wa ni Naijiria yii, oun nikan lawon mo pe o le yanju e, ko waa ba awon se e, apa awon ko ka a o. Kia ni egbon yoo bo ewu ija kale, ti yoo maa ti ilu kan de ilu keji, ti yoo si maa so pe rere ni Buhari fe fun Naijiria, Buhari ki i se omooya awon Fulani apaayan rara.

Olorun mo pe ohun ti mo n so yii, n ko so o ni asodun tabi lati fi ba egbon wa je, bo ti ri ni mo wi yii, nitori ohun ti mo ti foju mi ri ni. Itan repete wa lowo mi nidii eyi, aaye ko kan si fun iyen bayii ni. Eyin omo Yoruba ti e si n ro pe Egbon Segun ti pada wa sile, o loo ba awon Afenifere sepade, o fee ran Yoruba lowo, e kuro ni idi ido, ere omode ni. Ko si ninu eje Egbon Segun lati ja fun Yoruba, Naijiria nikan loun n ja fun, lati kekere ni. Ko si ninu eje re rara. Nigba ti Egbon yii leyin to le fi geeyan je, to lagbara to le fi ja, to wa nipo to le fi pase, egbon ko ran Yoruba lowo, ko si duro ti won nigba kankan. Yoruba lo maa n duro ti egbon yii nigba to ba wa ninu isoro. Se nigba ti ko tie si eegun to le fi ja mo yii, ti ko si eyin to le fi geeyan je, ti ko si agbara ase kankan mo, se nigba yii ni yoo ran Yoruba lowo? Ko le see se!

Buhari ni egbon fee le kuro nipo, gbogbo ohun to si n se ni lati wa awon ti yoo ba oun se ise naa. Egbon ko ni egbe oselu, ko si da ni ero kan leyin, nitori ki i se oloselu lati ile. Bo ba ti kuro ni PDP, to koyin si APC, egbe oselu wo lo fee lo lati ko ero jo? Ohun to to fi n lo sile igba to n lo sile awo niyen. Bee ni ki i se odo awo asaaju Youra nikan lo n lo, o n lo sodo awon ti Ibo, bee lo n lo sodo tawon Hausa. Sugbon kinni kan ni mo mo, nigba ti Olorun ba setan to fee gbeja eda, tabi to fee gbeja iran kan, awon ota iran naa ni yoo lo lati gba eto won fun won, awon ota ni iran naa yoo lo lati fi dide. Bi yoo ti se e naa ni pe yoo da won ota yii lede ru ni, bee ni okan tabi pupo ninu won yoo ni awon ko gba mo ki won fiya je lagbaja tabi awon eeyan kan mo, o pari niyen. Bee ni eto to ti bo lowo won yoo pada si won lowo.

O see se ko je ohun to n sele si Egbon Segun ree, ko je Olorun ti setan lati ko Yoruba yo. Sugbon inu mi ko dun nigba ti mo ri awon PDP atijo ti won n ro lo si ile re, awon to je ole ni won ja titi ti ijoba fi bo lowo won. Bi inu mi ko se dun naa nigba ti awon APC ro lo si odo re ni 2014 ree, nitori mo mo pe kidaa eletan lawon, n ko si ti i mo nigba naa pe Buhari yoo ya alaigboran bayii! Sugbon inu mi to baje ni ti Egbon Segun ati PDP ko to ti eyi to baje ni ti ibo ti won di koja l’Ekiti. Gbogbo ilakaka mi, gbogbo ariwo ti mo n pa, gbogbo igbiyanju mi ni pe lojo kan, awon mekunnu funra won yoo logbon lori, won aa le da ronu, lati mo aburu ati wahala tawon oloselu n ko ba aye won. Won yoo si gba ara won lowo won. Sugbon ohun ti mo ri l’Ekit ba mi ninu je, awon mekunnu ko gbon, bawon oloselu ti n se won bii eru to.

Ni gbangba, lori intaneetib la ti ri i ti won n ha owo. Awon eeyan Fayemi ati APC n ha fo-taosan, awon ti Fayose ati PDP n ha tiri-taosan. Bo ba je oloooto ati olododo ni Buhari gege bi awon ti won feran re de oju iku ti n so ni, iru ibi yii ni asaaju ti n fi ododo ati agbara re han. Loni-in yii, o ye ki olopaa ti gbe Fayemi, ki won si ti wa bi won yoo ti mu Fayose, nigbeyin iwadii ati idajo, ewon lo ye ki won lo taara, okankan ninu won o si tun gbodo di ipo ijoba kan mu tabi da si oro idibo ni Naijiria, nitori abanilayeje ati ole ni won. Fayemi to na iru owo bee, ati Fayose to n pin tie, owo ta ni? Bi a ba ka iye awon oludibo to wa ni ipinle naa, won din die ni egberun lona ogorun-un meje ni. Iyen ni pe eni to ha fo-taosan yoo na bii bilionu meta Naira, eni to n fun won ni tiri-taosan yoo na bilionu meji o le. Ise wo ni Fayemi se to fi ri iru owo bee, awon eeyan si mo pe owo ilu ni Faysoe ji ko to n na. Ki lo de ti Buhari o mu won?

Sugbon bi Fayemi ba fee ba aye awon eeyan je, ti Fayose si mura lati so won di oloriburuku, tawon eeyan ko ba gba fun won, ko sohun tawon mejeeji le se. Iyen lo se fee pa mi lekun nigba ti mo ri awon eeyan wa bi won ti n sare loo gba owo epe yii lowo awon oselu. Se awon yii ko mo pe aye awon ni Fayemi ati Fayose n baje ni! Se ko ye won rara ni! O su mi o!  

(245)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.