Ni ti Fayoṣe, afaimọ ….

Spread the love

Bi Igbakeji Fayoṣe to fa kalẹ ba wọle, bi ko si wọle, kinni kan wa ti Fayoṣe funra rẹ yoo maa ranti, ti ko si ni i gbagbe, iyẹn naa si ni bi yoo ṣe ṣe e ti yoo maa tọju ibinu rẹ, ti yoo si mọ bi yoo ti maa sọrọ niwaju awọn agbalagba nigba ti ọrọ ba pa wọn pọ. Ko si bi ẹnikan ṣe le lawọ to, ko maa fọn owo kiri titi, ko si maa ba ọpọ eeyan ṣe, nigba ti ko ba ti mọ bi yoo ti sọrọ niwaju agba, ti awọn eeyan ba ti ri i pe o n ri agba fin, tabi ti wọn ni aṣa ọmọ kan ni, yoo ṣoro ki wọn too fẹ iru ẹni bẹẹ denudenu, tabi ki wọn too fun tọhun ni ohun to ba n wa. Fiimu kan wa lori ẹrọ ayelujara ti wọn n gbe kiri, bo ti wa lori fesibuuku (Facebook) naa lo wa lori ẹrọ Wasaapu (Whatsapp), o si kun ori intanẹẹti girangiran ni. Ipade kan ti Fayoṣe ba Ewi, Ọba Ado, ṣe l’Ekiti nitori ọrọ o ṣe ile wiwo ko ṣe ile wiwo, nigba ti Ọba Ado pe ọkunrin gomina naa pe ọrọ ile ti o n wo ni ilu Ado-Ekiti, ki wọn fi ẹsọ ṣe e, nitori awọn araalu n kigbe wa si ọdọ oun ọba. Niṣe ni Fayoṣe gbana jẹ lori ọrọ naa, to si fẹrẹ maa naka si ọba, nibi to ti n pariwo pe, “Ẹ ma sọ bẹẹ rara, ẹ ma sọ bẹẹ rara! A maa wole o! a maa wole daadaa!…” ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ko si ohun to buru bi ijọba Fayoṣe yoo ba wole, ṣugbọn ọna wa ti Fayoṣe le fi sọ ọrọ naa ju ariwo pipa le odidi Ewi lori lọ. Ọrọ naa waa ni wọn gbe jade ti wọn n ju sori afẹfẹ kiri yii, Fayoṣe lo si n fẹ ki awọn ara Ekiti, paapaa, awọn ara Ado, dibo fun ẹni ti oun fa kalẹ yii. Fayoṣe yoo ti ri i pe aye ko ṣe tẹnikan, oun to kọju si ọdọ ẹnikan loni-in, o le jẹ ẹyin ni yoo kọ si tọhun lọla. Iyẹn la ṣe gbọdọ fi ironu, ọgbọn ati laakaye ṣe gbogbo ohun ta a ba n ṣe. Wọn maa n sọ pe ọkunrin naa ṣe daadaa, awọn yoo dibo fẹni to ba fa kalẹ, ṣugbọn eyi to ṣe fun Ewi yii, afaimọ, afaimọ, afaimọ lọrọ naa ko ni i di oro, ko ma gbe ẹni to fa kalẹ lọ lo ku!

 

(85)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.