Ni ti APC, ẹnu orofo ni yoo pa ọrọfọ

Spread the love

Ọrọ naa jo awọn APC lara. O ka wọn lara ju ohun ti gbogbo aye ro lọ. Awọn kan n beere pe ta lẹni ti a na ta lẹni to n ke, “Ẹ kaalẹ” fori sọ pẹpẹ; ẹni to ṣe “barika” fẹwu yagi, eeyan to n ṣe “Edumare dọmọ naa si” fapa jona, “Iya jẹ n gbọmọ wo”, niṣe niyẹn si fa itan ọmọ ya. Oyinbo mu ọti, ọti n pa kuuku lọrọ naa jare. Ariwo APC gan-an pọ ju tawọn ti ọrọ kan lọ. Awọn ni wọn bẹrẹ si i bu Ọbasanjọ, bi wọn ti n bu Ọbasanjọ ni wọn n fi epe le e, awọn mi-in si n bura pe bi awọn ri baba naa, awọn ko ni i ki i mọ. E e ṣe! Wọn ni ole ni Ọbasanjọ, alasọkojẹ ni, ko si wulo kankan nidii oṣelu, ko si agbara kan to ni, o kan n janu lasan ni. Wọn ni ki tiẹ ni iwulo ẹ paapaa! Bẹẹ ni wọn ni Atiku naa ole, ko fẹ nnkan meji ju ki o waa jale lọ. Wọn ni awọn ojiṣẹ Ọlọrun gbogbo to wa nibẹ, lati ori Oyedepo titi dori Gumi Alaaji, wọn ni ohun ti awọn yẹn yoo jẹ ni wọn n wa kiri. Ori redio to jẹ ti awọn gomina tabi tawọn ọmọ ẹgbẹ naa kun, ẹrọ ayelujara si ni ki lo ṣubu tẹ oun, APC binu, walahi, ọrọ naa jo wọn lara. Ṣugbọn ki lo de ti kinni naa le to bayii. Bi wọn ti n tu awọn aṣiri yii, bẹẹ naa ni aṣiri awọn naa n tu pe opurọ ati ẹlẹtan lasan ni wọn, ohun ti ọpọ awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ati olufẹ wọn ko mọ, awọn naa ni wọn n fi ẹnu ara wọn tu u jade. Wọn ti gbagbe pe bi Atiku ti lọ sile Ọbasanjọ yii, bẹẹ ni gbogbo awọn ti wọn n pe ara wọn ni aṣaaju APC loni-in, lati ori Aarẹ Buhari titi de ọdọ Aṣiwaju Tinubu ati Baba Bisi Akande, di igba di agbọn wọn, ti wọn gba ile Ọbasanjọ lọ ni 2014, ti wọn lọọ bẹ ẹ, ti wọn ni oun lawọn fẹ ko ṣaaju awọn ninu ilakaka awọn lati gbajọba lọwọ Jonathan. Nigba naa Ọbasanjọ ki i ṣe alatẹnujẹ, o si wulo daadaa! Wọn ti gbagbe pe awọn lawọn sọ fun gbogbo awọn ọmọ Naijiria ati ololufẹ awọn, pe ọmọluabi gidi ni Atiku, ọkan ninu awọn ti wọn fẹran Naijiria tọkantọkan, ti ko si si ohun ti wọn ko le ṣe lati wa ilọsiwaju rẹ ni. Igba ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ, ti Atiku gbe ẹronpileeni rẹ silẹ ti Buhari n gun un kiri ni wọn sọ bẹẹ. Wọn ti gbagbe pe gbogbo awọn ti awọn n pe ni ole yii lawọn ti pe leeyan daadaa ri, awọn ti wọn si sọrọ naa fun ko gbagbe, nigba to jẹ gbogbo iwe iroyin ati awọn onitẹlifiṣan pẹlu redio ati ẹro-ayelujara ni wọn gbe e. Gbogbo bi wọn ṣe waa n pariwo bii ẹni ti ilẹkun bọọsi-ọfan mu lọwọ lojiji yii, niṣe ni wọn n tu aṣiri ara wọn jade pe ẹlẹtan gidi lawọn. Ẹni to ba mọ wọn ni APC daadaa, ọrọ to wa nilẹ yii ki i ṣe ọrọ ariwo, ki wọn tete bẹrẹ si i fi awọn iṣẹ ti Buhari ṣe han gbogbo ilu, ki wọn si maa sọ awọn eto to n ṣe lati fopin si awọn iwa ipaniyan to n lọ labẹ ẹ, ohun to le gba wọn ni asiko ibo 2019 yii niyẹn o. Ṣugbọn bo ba jẹ ariwo eke yii ni wọn mura si, ọrọ naa yoo le fun wọn.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.