Ni Kwara, o to gẹẹ loootọ

Spread the love

Nibi ti ibo to kọja yii yoo ti ya awọn eeyan lẹnu ju ni ilu Ilọrin ati agbegbe rẹ. Bukọla Saraki, ọmọ Baba Oloye, si jabọ silẹ patapata, koda, o rẹ pẹtẹpẹtẹ. Idi ti ọrọ ibo ti wọn fi na Saraki yii yoo fi maa ya awọn eeyan lẹnu ni pe ko sẹni to ro pe iru rẹ yoo ṣẹlẹ n’Ilọrin. Ko sẹni to ro pe lojiji, tabi nijọ kan ti ẹnikan ko mọ, wọn yoo yọ Saraki kuro lojiji. Ẹni ti agbara rẹ pọ debii pe nigba ti awọn oloṣelu ibẹ, koda awọn ti wọn to o bi i lọmọ ati awọn ti wọn ju u lọ gan-an ba fẹẹ ba a sọrọ, ori ikunlẹ ni wọn yoo wa, ti wọn yoo si maa pariwo rẹ pe ko si igbakeji rẹ ni gbogbo Kwara. Nigba to n ṣejọba, to n jale, tawọn eeyan n sọ pe ọkunrin yii n ṣe gomina, o si n ko owo jẹ, o n jale, o si n ba tawọn ara Kwara jẹ, niṣe lawọn mi-in ni ko si ohun to buru nibẹ, ọmọ Kwara ni, owo Kwara lo n na, ki waa ni wahala awọn araata. Oun naa paapaa ti ro pe ko si iru oun ni Kwara ati ni Naijiria, agbara to si lo lati bii ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni Kwara yii pọ debii pe ko sẹni to mọ pe ti wọn ba ti i lojiji, yẹbukẹ bayii ni yoo ṣubu. Wọn ti Saraki, o si subu gbayau, eyi fihan pe ko si alagbara kan nibi kan, awọn eeyan ni wọn wa lẹyin ẹnikan ti wọn fi n pe onitọhun ni alagbara, bi awọn eeyan ba si ti pada lẹyin onitọhun, titan de ba a naa niyẹn. Ohun ti a n wi niyẹn pe nigba ti eeyan ba ni agbara, ko lo agbara naa fun anfaani awọn eeyan ilu, ko lo o lati fi tun aye awọn ti wọn wa niluu ati agbegbe rẹ ṣe, eyi ni yoo jẹ ki awọn eeyan dide, ki wọn si duro lẹyin onitọhun nigba ti omi aye ba fẹẹ gbe e lọ. O ti pẹ ti a ti n sọ ọ lati ọjọ yii pe Saraki lowo, Saraki lowo, ti awọn kan n pariwo kiri, eelo lo na nibẹ lati fi tọju awọn eeyan Ilọrin ati Kwara lapapọ. O pẹ ti awa ti n sọ ọ pe ko mu laakaye dani ki ẹni kan ji, ko maa ha tọrọ kọbọ fawọn eeyan, ko maa fun wọn lowo ounjẹ ojumọ kan, ko si maa pin agolo irẹsi fun wọn. O pẹ ti a ti n sọ ọ pe ko si ohun to dara bii ki eeyan da ileeṣẹ to tobi silẹ ti awọn eeyan yoo ti ṣiṣẹ, ko mu iṣẹ gidi wọ ilu ibi to n gbe, nigba to jẹ titi aye ni iru ileeṣẹ bẹẹ yoo wa. Ṣugbọn awọn eeyan ko tete gbọn, Saraki ti jẹ wọn jinna ki wọn too mọ pe o n pa awọn lara. O ba naa ni ko bajẹ, nigba ti awọn ara Kwara ti jaja gba ara wọn silẹ bayii, ki wọn ri i pe ọkunrin naa ko wa mọ, eegun rẹ ko si ṣẹ nidii oṣelu ilu Ilọrin, ati agbegbe Kwara patapata. Eleyii yoo jẹ ikilọ fun awọn oloṣelu ole gbogbo to ku, wọn yoo mọ pe ohun ti i tan ni ogun eegun, ọmọ alagbaa yoo ra akara fi jẹkọ. Bi Saraki ti jabọ yii, iru ẹ la oo maa ri lawujọ wa, gbogbo oloṣelu ole ni yoo maa farapa!

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.