Ni 1978, ẹmọ n lọ, afe n lọ, Azikiwe nikan ni ko ti i mọ ibi to fẹẹ gba lọ

Spread the love

Titi di ipari oṣu kẹwaa, ọdun 1978, ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo to wa ti ko loluwa ni ẹgbẹ NPP. Ki i ṣe pe ko loluwa bẹẹ naa, ko kan ni aṣaaju kan ti gbogbo wọn jọ fọwọ si ni. Ati nitori eyi, iṣoro inu ẹgbẹ naa ju ti ẹgbẹ yoowu lọ. Gbogbo eeyan lo ti gbọ orukọ ẹgbẹ Unity Party of Nigerian (UPN), ti wọn si mọ aṣaaju wọn pe Ọbafẹmi Awolọwọ ni. Bakan naa ni wọn mọ orukọ ẹgbẹ National Party of Nigeria (NPN), ti wọn si mọ alaga ẹgbẹ naa pe Alaaji Aliyu Makama Bida ni. Bakan naa ni wọn mọ orukọ ẹgbẹ Movement of the People (MOP), ti wọn si mọ pe Fẹla Anikulapo Kuti ni olori ẹgbẹ naa. Wọn tun mọ ẹgbẹ National Advance Party (NAP), ati pe Tunji Braithwaite lolori wọn nibẹ. Bẹẹ naa ni wọn si mọ People Redemption Party ati pe olori wọn ni Aminu Kano. Koda, awọn ẹgbẹ keekeeke to ku paapaa ni olori wọn, gbogbo aye lo si mọ wọn.

Ṣugbọn ko sẹni to mọ olori ẹgbẹ NPN tabi ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn oloṣelu nla nla ni wọn wa nibẹ, awọn oloṣelu gidi, awọn olowo ati awọn ẹni ti wọn mọ lawujọ. Awọn bii Adeniran Ogunsanya, Kọla Balogun, ati ọpọlọpọ awọn ti wọn jẹ ọmọlẹyin Azikiwe ninu ẹgbẹ NCNC lasiko ijọba awọn oloṣelu atijọ. Eyi ni awọn eeyan kan ṣe n sọ pe Azikiwe lolori ẹgbẹ naa, ti wọn si ni oun naa ni wọn fẹẹ lo lati du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn. Awọn oloṣelu inu ẹgbẹ naa ti wọn mọ eyi ko ṣiṣẹ fẹni meji ju Azikiwe lọ, bo tilẹ jẹ pe ẹni kan ti wa ninu ẹgbẹ naa to n nawo gidi ju awọn to ku lọ. Ọkunrin oloṣelu kan toun naa ti ṣe oṣelu daadaa, to si ṣe minisita laye awọn oloṣelu akọkọ ni, lẹyin to si kuro nidii oṣelu, ibọn lo n ta, bẹẹ lo n ta ẹtu, ati awọn ọta ibọn, eyi si jẹ ki owo rẹ ya mura lasiko ogun abẹle. Waziri Ibrahim lorukọ rẹ. Alaaji ni.

Iṣoro to wa ninu ẹgbẹ NPP yii ni pe ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ keekeeke ni wọn parapọ ti wọn di ẹgbẹ yii, ninu wọn si ni ẹgbẹ kan to n jẹ National Unity Council, ẹgbẹ yii ni ẹgbẹ Waziri Ibrahim, oun si ni olori ẹgbẹ wọn nibẹ. Ṣugbọn awọn ẹgbẹ mi-in naa wa nibẹ, ti awọn naa si jẹ ẹgbẹ gidi, ninu wọn si ni ẹgbẹ awọn ọmọ Eko, ati awọn ẹgbẹ mi-in bẹẹ, paapaa lati ilẹ Ibo. Nigba to si jẹ oju ọna kan naa ti wọn fi da ẹgbẹ NCNC silẹ lọdun 1944 ree, awọn eeyan ri ọwọ Oloye Nnamdi Azikiwe nidii ẹgbẹ tuntun yii naa, wọn si ni baba naa lo wa nidii ẹ, oun lolori wọn. Awọn ti wọn jẹ ọmọ Azikiwe ninu ẹgbẹ yii o yee sọ fawọn eeyan pe Azikiwe lawọn n ṣiṣẹ fun, oun ni yoo di olori awọn. Ọrọ yii n dun Waziri Ibrahim ati awọn ti wọn n tẹle e, wọn ni bawo ni ẹni ti ko ṣe nidii pẹpẹ yoo ṣe waa jẹ nidii pẹpẹ, bawo ni Azikiwe ti ko ba wọn da si ẹgbẹ yoo ṣe waa du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn.

Lọjọ kan ni Waziri kuku la ọrọ naa mọlẹ, o ni ẹgbẹ awọn, NPP, ko ti i ni olori kankan. O lo di igba ti awọn ba ṣe ipade gbogbogboo ẹgbẹ naa ti alakọọkọ, nigba naa ni awọn yoo mọ ẹni ti yoo jẹ olori ẹgbẹ ọhun. O ni loootọ lawọn eeyan n pe oun ni olori ẹgbẹ yii, ṣugbọn iyẹn ko ti i ṣee fi gbogbo ẹnu sọ, afi nigba ti awọn ba pade, ti gbogbo ẹgbẹ ba fọwọ si i. N’Ibadan lo ti sọ bẹẹ, nigba ti wọn n ko ẹgbẹ NPP yii jade ni ipinlẹ Ọyọ. Ọjọ Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 1978 ni. Bẹẹ bi a ba si fẹẹ sọ tootọ, Waziri ni gbogbo eeyan n ri kaakiri o, nitori ko si ibi ti wọn yoo ti ko ẹgbẹ NPP jade ti ko ti ni i si nibẹ, ko si si owo kan ti yoo jade ti ko ni i jẹ oun ni yoo ṣeto lati na an. Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa, paapaa awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa ko tilẹ gba pe ẹgbẹ ọhun tun ni olori mi-in ju ọkunrin yii lọ, wọn si ti mu un bii aṣaaju wọn.

Ọrọ to sọ ni Ibadan yii ko dun mọ awọn mi-in ninu ṣa, iyẹn awọn ti wọn ti n ṣeto labẹlẹ lati gbe Azikiwe jade bii iyawo tuntun. Awọn yii ni awọn ti sọrọ yii tẹlẹ laarin ara awọn, awọn ti wọn jẹ aṣaaju ẹgbẹ si ti mọ pe bo pẹ bo ya, Azikiwe lawọn yoo gbe jade, ki waa ni Waziri n lọọ sọ iru ọrọ yii nita gbangba si, ṣe ki wọn le mọ pe awọn o ti i mu olori awọn jade ni, abi ti kin ni! Awọn eeyan yii o si deede maa sọ bayii naa, awọn naa kuku n lọ si ọdọ Azikiwe, wọn si n ba a ṣepade, o si jọ pe ọrọ ti wọn ti sọ laarin ara wọn ni pe baba naa yoo jade bo ba ya, ṣugbọn Azikiwe ko ti i fẹ ki ẹnikẹni mọ pe oun yoo jade, boya ko si ti i mọ inu ẹgbẹ ti yoo wa ni, nitori pupọ ninu awọn ọmọlẹyin rẹ naa ti gba inu ẹgbẹ NPN lọ. Nibi ti wọn si ti n sọrọ yii, kinni kan ṣẹlẹ to ko rọyirọyi ba gbogbo eeyan, ati awọn ti wọn n woran oṣelu ọhun lọọọkan, ati awọn ti wọn n ṣe e.

Awọn ẹgbẹ NPN ni wọn fẹẹ ko ẹgbẹ wọn jade ni agbegbe Onitsha, iyẹn adugbo ti Azikiwe ti wa, ni wọn ba pe baba naa sibẹ, wọn ni ko waa ṣe alaga ipade awọn. Ọkan ninu awọn ọmọlẹyin rẹ to jẹ aṣaaju ẹgbẹ yii nilẹ Ibo, Chuba Okadigbo, lo pe e. Oun ati Uwafor Orizu ni wọn pe. Ọkunrin Nwafor Orizu yii, ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC, ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin Azikiwe nigba ti wọn n ṣe oṣelu akọkọ ni. Koda, nigba ti ara Azikiwe ko ya nipari ọdun 1965, to fẹẹ lọ siluu oyinbo lati gba itọju, Orizu ni Azikiwe gbe ipo aarẹ fun, to ni ko maa ṣe ipo naa lọ titi ti oun yoo fi de. Ṣugbọn Azikiwe ko de titi ti awọn ṣọja fi gbajọba ni ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 1966, bẹẹ lo ṣe jẹ pe Nwafor Orizu yii lawọn ṣọja gbajọba Naijiria lọwọ rẹ lẹyin ti wọn ti pa Balewa ti i ṣe olori ijọba. Oun lawọn ṣọja paṣẹ fun ko gbejọba fawọn nitori pe ilu o fara rọ, ti ko si si Azikiwe nile. Oun naa si ṣe bẹẹ.

Eyi yoo fihan, ibi ti ajọṣe ọkurin naa ati Azikiwe de duro nigba atijọ, to jẹ pe wọn jọ n jẹ, wọn jọ n mu ni. Nigba ti eto oṣelu awọn Ọbasanjọ yii si bẹrẹ, awọn NPN ro pe ti awọn ba ri Azikiwe ati Orizu mu, abuṣe ti buṣe, a jẹ pe gbogbo ilẹ Ibo ni yoo dibo fun ẹgbẹ naa niyẹn. Ṣugbọn lẹyin ti awọn olori ẹgbẹ naa ti gbiyanju titi ti wọn ko mọ eyi ti awọn agba mejeeji yii n ṣe, wọn da a bii ọgbọn, wọn ni ki awọn ti wọn wa lati agbegbe rẹ pe wọn sipade, awọn fẹẹ mọ boya wọn yoo wa tabi wọn ko ni i wa. Wọn ni bi wọn ba fi ti le wa si ipade wọn, a jẹ pe wọn ti gba lati di ọmọ ẹgbẹ NPN, ọkan awọn yoo si balẹ, nitori bi wọn ko ba fẹẹ jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ni, wọn o ni i wa sipade awọn. N lawọn Okadigbo atawọn mi-in ba kọwe si Azikiwe pẹlu Orizu lọdọ wọn.

Azikiwe gba lẹta tirẹ loootọ, nigba to si di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹwaa, ni 1978, o da esi iwe naa pada fun wọn. Ohun ti baba naa si kọ sinu lẹta rẹ si wọn niyi o: “Inu mi dun lati ri iwe ti ẹ kọ ranṣẹ si mi lọjọ kẹtala, oṣu kẹwaa, ọdun 1978, eyi ti ẹ fi pe mi si ipade yin, iyẹn ipade ẹgbẹ NPN ti agbegbe Onitsha. Ni asiko ti a wa yii, oju ti ọpọlọpọ eeyan fi n wo mi ni oju ‘Baba orilẹ-ede’, iyẹn ni pe emi ni baba gbogbo Naijiria, gẹgẹ bii aarẹ ilẹ wa, ati ẹni ti ko gbọdọ ni ikunsinu, tabi ikannu si ẹnikẹni. Nitori bẹẹ, ojuṣe kan ṣoṣo naa ti mo ni lasiko yii ni lati ri i pe awọn ọmọ mi ko ja, wọn ko si ba ara wọn fa ifakufa ti yoo tun mu wahala kankan wa si ilẹ wa. Iyẹn ni pe ipo baba ni mo fẹẹ wa, ki n le maa tọ awọn ọmọ mi sọna bi wọn ba fẹẹ ṣe aṣiṣe, tabi nibikibi ti wọn ba ti fẹẹ maa ba ara wọn ja. Mo gbadura pe ipade NPN ẹkun Onitsha yii yoo mu eso rere jade o.”

Bayii ni Oloye Azikiwe kọ sinu lẹta rẹ, ọrọ naa si lu kii kii lọkan awọn ololufẹ ati awọn ọmọlẹyin rẹ, nitori ohun to fẹnu ara rẹ sọ yii ni pe oun ko ni i ṣe oṣelu, oun ko si ni i ba wọn du ipo kankan. Ọrọ naa ya awọn ọmọlẹyin rẹ ti wọn ti n lọọ ba a lati ọjọ yii ti wọn si ti jọ n ṣepade lẹnu, abi kin ni ọga tun n sọ yii, ohun ti wọn n beere laarin ara wọn niyi. Ṣugbọn ọrọ naa dun mọ awọn eeyan Waziri Ibrahim ninu ni tiwọn, wọn loun ti awọn fẹ gan-an ree, ibi gẹrẹjẹ la a ba agba, ipo agba ni Azikiwe wa, ipo agba naa si lo yẹ ki wọn maa ba a. Awọn wọnyi ni ohun kan ṣoṣo ti yoo sọ Azikiwe di ẹni apọnle ree, nitori bi baba naa ba tun ko ẹwu oṣelu sọrun bayii, to n ba awọn ọmọde fa ipo aarẹ ati ipo mi-in ninu ẹgbẹ NPP, arifin ni yoo jẹ, nitori awọn ọmọde naa ko ni i fun un ni ọwọ to ba tọ si i. Ṣugbọn wọn gba pe pẹlu eyi ti Azikiwe ṣe yii, baba naa ti di baba gbogbo awọn.

Ṣugbọn ọrọ naa ko tan sibẹ rara, nitori awọn kan taku ninu ẹgbẹ NPP, wọn ni nigba ti awọn ọmọlẹyin Sardauna aye ọjọsi ko ara wọn jọ pọ sibi kan, ti awọn ọmọlẹyin Awolọwọ naa ko ara wọn jọ pọ sibi kan, ti Awolọwọ funra rẹ ṣaaju wọn, bi awọn ọmọ Azikiwe naa ba ko ara wọn jọ ti ko ba si Azikiwe nitosi lati ṣaaju awọn, awọn yoo kan da bii ọmọ ti ko ni baba ni, wọn ni eyi ti baba naa sọ yii, apo ara rẹ lo sọ ọ si, awọn yoo fa a jade dandan. Ohun ti ko waa si ẹni to mọ tabi to le sọ pato ni pe boya eto ni kinni naa laarin awọn aṣaaju NPP ti wọn fẹ Azikiwe gẹgẹ bii olori awọn ati Azikiwe funra rẹ, tabi ko jẹ awọn ọmọlẹyin rẹ yii ni wọn kan n fẹẹ fi ipa wọ baba naa lati waa ṣe ohun ti ko fẹẹ ṣe. Awọn oloṣelu ti wọn mọ Azikiwe daadaa fi ogun rẹ gbari ṣaa, wọn ni baba naa yoo jade, o kan n dibọn ni, ko fẹẹ wọ ẹgbẹ NPN lo ṣe kọ lẹta bẹẹ si wọn.

Bẹẹ ni gbogbo bi awọn ti n ṣe yii, awọn ẹgbẹ NPN ni tiwọn naa ko duro mọ, ọna ti wọn yoo fi tete fi ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn han ni wọn n ṣe. N ni wọn ba fi ọjọ ipade gbogbogboo akọkọ ti ẹgbẹ naa yoo ṣe si ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 1978, wọn ni lọjọ naa lawọn eeyan yoo ri awọn wo bii iran. Alaaji Aliyu Makama Bida ti i ṣe alaga ẹgbẹ yii lo kede bẹẹ, o ni Eko yoo gbalejo awọn, wọn yoo si ri iran gidi wo, nitori lọjọ naa lawọn yoo yan gbogbo awọn ti wọn yoo du ipo kan tabi omi-in, ninu ibo maraarun ti wọn fẹẹ di ni Naijiria nigba naa. O ni gbogbo bi awọn ti dakẹ jẹẹ ti awọn ko sọrọ, iyẹn ki i ṣe pe awọn ko ṣe nnkan kan, o ni eto gidi n lọ, eto naa si ni pe awọn o fẹ ohun ti yoo fa ija ninu ẹgbẹ, tabi laarin awọn ọmọ ẹgbẹ awọn, iyẹn lawọn ṣe n yanju gbogbo ikunsinu keekeekee to wa, ki wọn le jade pẹlu gbogbo agbara wọn.

Alaaji Makama ni gbogbo awọn ti wọn n sọrọ pe ẹru n ba awọn lati ṣe ipade gbogbogboo ẹgbẹ awọn, pe ko ma jẹ ọjọ naa ni ẹgbẹ awọn yoo tuka pata, ko mọ ohun ti wọn n sọ ni, o ni awọn n ṣe eto tawọn ni ọna ti eto ijọba tiwa-n-tiwa, iyẹn dẹmokiresi gba ni. Alaaji naa ni awọn eeyan nla nla ti wọn lọpọlọ gan-an ni wọn pọ ninu ẹgbẹ awọn, wọn si lẹtọọ lati du ipo yoowu ti wọn ba fẹ, awọn si gbọdọ ṣe e ni ọna to jẹ awọn ọmọ ẹgbẹ funra wọn ni wọn yoo fa ẹni to ba wu wọn kalẹ lati du ipo, ti ko ni i jẹ ẹnikan lo gbe ẹni kan le wọn lori bi awọn ẹgbẹ kan oke-ọhun ti n ṣe. Nigba ti wọn beere pe awọn ẹgbẹ wo waa ni ẹgbẹ kan oke-ọhun to n wi yii, ẹrin lo bu si, o ni awọn oniroyin naa mọ awọn ti wọn n wi funra wọn, to jẹ ẹni kan naa lo n paṣẹ, ohun to ba si ti wi lawọn to ku gbọdọ tẹle, ti ko sẹni to gbọdọ jiyan, oun funra ẹ lo n fi awọn to ba fẹ kalẹ, o lawọn yẹn loun n sọ.

Nigba ti yoo ba ọrọ jẹ, ti yoo si tu aṣiri ara rẹ fawọn eeyan lati mọ ibi ti o n juko ọrọ si, o ni gbogbo ara ti ẹgbẹ UPN n da tawọn eeyan ro pe wọn n dara gidi kan yẹn, lọjọ ti awọn ba jade sita yii lawọn yoo ba wọn, ti awọn yoo si fi wọn silẹ, to jẹ wọn ko ni i le ta putu mọ nigbakigba ti wọn ba gbohun awọn nigboro. Makama Bida ni ohun kan ni ẹgbẹ awọn ko ni i ṣe, iyẹn naa ni ki awọn maa bu awọn ẹgbẹ oṣelu ẹgbẹ awọn, tabi ki awọn maa sọrọ kobakungbe si wọn. O ni oṣelu asiko yii ti yatọ si tatijọ, oṣelu ti ko ni i ba orukọ ẹnikẹni jẹ lawọn fẹẹ ṣe, eyi si lo fi jẹ pe ko si ẹgbẹ meji to dara lasiko naa ju ẹgbẹ NPN lọ. “Ẹ wo o, loootọ lawọn UPN ti ṣaaju wa ninu eto ati ipolongo wọn, ṣugbọn mo fẹẹ sọ fun yin pe ki i ṣe pe a oo ba wọn nikan o, a oo la wọn, a oo ya wọn silẹ kia, ẹyin naa yoo ri gbogbo eyi nigba ti a ba kede eto wa, awọn eto idẹrun gidi fun gbogbo araalu, oju yin yii naa ni yoo ṣe.”

Boya ni ko jẹ ọrọ yii lo dun awọn UPN, n lawọn naa ba sare jade, wọn ni ẹni to ba moju NPN ko kilọ fun wọn o, ki wọn ma ji awọn wo ninu eto, ki wọn ma kọpi awọn, nitori onikọpikọpi ni wọn. Ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ naa, Alfred Rewane, lo sare sọ bẹẹ ni ilu Warri. O ni gbogbo ileri ti oun n gbọ yii, ati ihalẹ ti awọn NPN n ṣe yii, ẹru n ba oun o, ẹru to si n ba oun naa ni pe awọn ẹgbẹ naa fẹẹ ji ẹgbẹ awọn wo ni, nitori wọn le de bayii ko jẹ ohun ti awọn ti ni awọn fẹẹ ṣe lawọn naa yoo jade wa ti wọn yoo ni awọn fẹẹ ṣe, nitori ko jọ pe awọn eeyan naa ni eto gidi kan fun awọn araalu, ko si jọ pe wọn mọ ohun ti wọn n fẹ gan-an. O ni ki i ṣe pe ẹgbẹ awọn, iyẹn UPN, kan deede ji lọjọ kan lawọn gbe eto kalẹ, tabi ti awọn kede pe bayii lawọn fẹẹ ṣe fọmọ Naijiria, o ni ohun ti awọn ti n pete-pero le lori lati ọjọ to pẹ ni. Nitori bẹẹ lo ṣe ni ki NPN tete fi tiwọn ṣe tiwọn.

Awọn ṣọja ti wọn gbe eto idibo yii kalẹ ko mọ pe bi yoo ti ri ree, wọn ko mọ pe awọn oloṣelu atijọ yii naa ni wọn yoo tun gba oju ọpọn eto naa kankan, o fẹrẹ jẹ gbogbo igba ni Ọgagun agba Oluṣẹgun Ọbasanjọ n ṣepade pẹlu awọn ọmọọṣẹ rẹ bii Ọgagun Shehu Musa Yaradua, Ọgagun T.Y. Danjuma, awọn bii Ibrahim Babangida, James Olulẹyẹ, Alani Akinrinade, Muhammadu Buhari ati awọn ṣọja to ku gbogbo. Ohun ti wọn n fẹ ni bi eto idibo ti wọn dana rẹ naa ko ṣe ni i ku sọna lojiji, wọn n wa awọn eeyan ti wọn le fi rọpo awọn oloṣelu atijọ yii, ṣugbọn ko jọ pe kinni naa ṣee ṣe. Ẹgbẹ mẹta naa lo fẹsẹ mulẹ ju, ti wọn si lorukọ ju, NPP, NPN ati UPN ni. Bẹẹ, awọn oloṣelu atijọ lo kun inu wọn fọfọọfọ!

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.