Ni 1977, Abiọla ati ileeṣẹ ITT ko girigiri ba Ọbasanjọ atawọn ọmọ ogun rẹ    

Spread the love

 

Ileeṣẹ kan ti wa nilẹ yii ri ti wọn n pe ni ITT. Bi eeyan ba gbọ orukọ ileeṣẹ naa lati inu orin Fẹla Anikulapo Kuti, ọtọ ni yoo tumọ rẹ si, nitori oun lo pe ileeṣẹ naa ni, International Thief Thief, to si n darukọ Abiọla sinu orin naa bo ti n kọ ọ lọ. ITT, International Thief Thief; Abila International Thief Thief, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ṣugbọn ija lo de nigba naa ti orin dowe o, orukọ ileeṣẹ yii gan-an ni International Telephone and Telegraph Corporation, ITT, bi aye ba si n sọ pe Abiọla lowo, nibi tọkunrin naa ti bẹrẹ owo rẹ niyẹn. Ileeṣẹ naa ti wa tipẹ, nitori lọdun 1920 ni wọn da a silẹ ni Amẹrika, ṣugbọn kia lo ti di ileeṣẹ agbaye, to kari aye. Iṣẹ ti wọn mọ-ọn ṣe ju, ti wọn si fi bẹrẹ ọja wọn ni iṣẹ pipeelo awọn ohun ija ogun loriṣiiriṣii, ṣugbọn ko pẹ ti wọn fi mu awọn iṣẹ mi-in mọ ọn, paapaa iṣẹ tẹlifoonu ati gbogbo awọn ohun to rọ mọ ọn.

Ileeṣẹ naa ti dohun tijọba Amẹrika n lo fun ọpọ iṣẹ wọn, nitori ko si orilẹ-ede ti wọn ko de, ko si sibi ti wọn ko ti ni owo nla ati ileeṣẹ nla si kari aye. Nigba ti Moshood Kaṣimawo Ọlawale (MKO) Abiọla de si Naijiria lẹyin to ti kawe jade ni ilu Glasgo, ni United Kingdom, ninu oṣu kẹta, ọdun 1966, lẹyin to ti kawe, to si ti di akauntanti, iyẹn awọn aṣiro-owo onimọ nla, ileeṣẹ to ti ṣiṣẹ niyẹn. Ibẹ yẹn naa kọ lo ti kọkọ ṣiṣẹ o, bo ti de, ọsibitu LUTH, ni Idi-Araba, l’Ekoo ni wọn gba a si. Ko si pẹ nibẹ to fi lọ si ileeṣẹ Pfizer, o jọ pe iṣẹ ọsibitu yẹn ko ba a lara mu. Lasiko to fi wa nileeṣẹ Pfizer yii ni 1968 ni awọn kan gbe ikede agbayanu kan jade, wọn ni wọn n wa aṣiro owo agba to mọ iṣẹ naa julọ ni gbogbo Afrika, wọn ni ẹni naa ni wọn fẹẹ gba fun ileeṣẹ nla kan.

Wọn ni ilu oyinbo ni wọn yoo ti ṣedanwo o, gbogbo ẹni to ba si laya ko kọwe wa, bi wọn ba ti mu un, wọn yoo fowo ọkọ ranṣẹ ati bi yoo ti de ibi idanwo ni London fun un. Ki i ṣe pe Abiọla n wa iṣẹ tuntun, nitori ileeṣẹ Pfizer to wa n sanwo to to o daadaa. Ṣugbọn ohun to ya a lẹnu ni pe wọn n wa ẹni to mọ iṣẹ akauntanti julọ l’Afrika, Abiọla si lo yẹ koun naa ba wọn danra wo, ki awọn jọ mọ ẹni to mọwe ju, ẹni to mọ iṣẹ akauntanti ọhun ju ninu gbogbo Afrika. Ohun to jẹ ki Abiọla loun naa yoo ba wọn kopa ninu ẹ niyẹn. Ṣugbọn nigba to danra wo tan yii ni wọn ṣedanwo naa, ko si akauntanti kan to mọ iṣẹ naa ju Abiọla lọ ni gbogbo Afrika, iyẹn ni ileeṣẹ naa ṣe da a duro, wọn ni wọn yoo gba a, ko sọ iye owo-oṣu to fẹ gan-an. Abiọla darukọ iye owo oṣu kan, ṣugbọn ko tẹ awọn oniṣẹ lọrun, ni wọn ba sọ owo to beere di ilọpo meji fun un.

Lẹyin naa lo mọ pe ileeṣẹ ITT ti wọn ṣẹṣẹ da ẹka rẹ silẹ ni Naijiria ni wọn ti fẹ ko waa ṣiṣẹ. Ileeṣẹ naa ti ni awọn ọga ti wọn jẹ oyinbo, wọn ni Jẹnẹra-Maneja, wọn si ni Manejin Darẹkitọ, Abiọla ni yoo ṣe ikẹta wọn gẹgẹ bii akauntanti agba. Iṣẹ akọkọ ti Abiọla ba wọn ṣe, iṣẹ olowo nla gbaa ni. Iṣẹ naa jẹ iṣẹ miliọnu mẹta ataabọ nigba naa, miliọnu mẹta ataabọ owo Pọn-un, ọdun 1969 ni, owo nla gbaa ni. Awọn ileeṣẹ yii ti ṣiṣẹ naa fun awọn ṣọja, awọn ṣọja ra ohun ija ogun lọwọ wọn ni, ṣe asiko naa ni ogun abẹle n lọ ni rẹbutu, iyẹn ogun abẹle ti Naijiria ja ti wọn n pe ni Ogun Ojukwu, laarin ọdun 1967 titi di 1970, ileeṣẹ ITT yii si wa ninu awọn to ta ohun ija ologun fun wọn, lati olu ileeṣẹ naa to wa ni London ni wọn ti ta a. Ṣugbọn awọn ṣọja ti gba  ohun ija oloro yii, koda, wọn ti lo o, wọn ko kan sanwo ni.

Awọn ọga agba ileeṣẹ naa lati London ti paara paara, wọn o rowo ọhun gba, awọn ọga ti wọn wa ni Naijiria naa ti lọ titi, ko bọ si i. Ni gbara ti Abiọla debẹ, awọn oyinbo ti wọn jẹ ọga pata tun wa lati London, Abiọla si tẹle wọn lati ri wọn nileeṣẹ ologun yii, Muritala Muhammed si ni ọga to wa nibi ti wọn ti ra ohun ija ologun yii fun wọn. Ṣugbọn wọn duro lati aarọ ṣulẹ si ọfiisi Muritala ni, ko ri wọn. Wọn tun pada lọ lọjọ keji, wọn si tun duro lati aago mẹjọ aarọ titi di aago mẹta aabọ ọsan ti Muritala fi lọ sile, sibẹ, ko ri wọn. N lawọn oyinbo yii ba binu pada lọ, wọn ni ko si bi awọn yoo ṣe ṣe e, o da bii pe wọn fẹẹ ti ileeṣẹ naa pa ni Naijiria, nitori iṣẹ akọkọ ti awọn ṣe lawọn ko ri owo ẹ gba yẹn. Igba ti awọn oyinbo lọ, Abiọla funra rẹ lọ si ileeṣẹ naa nijọ kẹta, o ni aago marun-un aarọ loun ti ji, o si ti wa nileeṣẹ naa laago meje geere.

O duro si ẹnu ọna ọfiisi Muritala gan-an, nigba to si di aago meje aabọ tọhun de lati wọ iṣẹ rẹ. Bo ṣe bọ silẹ lo n lọ wai wai bii ologun, Abiọla ki i, ko dahun, bo tilẹ jẹ ko mọ ọn ri. O tun fẹẹ kọja lara Abiọla ko maa lọ, ṣugbọn iyẹn dina mọ ọn, o ni ko le lọ, afi ko da oun lohun, nitori awọn wa nibẹ lanaa, awọn wa nibẹ nijẹta, bẹẹ ni ki i ṣe pe awọn waa tọrọ owo, iṣẹ ti wọn gbe fawọn ti awọn ṣe tan lawọn n beere owo awọn. N lọrọ ba dariwo, n ni Muritala ati Abiọla ba n pariwo le ara wọn lori. Ariwo yii ni olori awọn ṣọja nigba naa, Hassan Katsina, gbọ lo fi sare jade pe ki lo de, o si ya a lẹnu lati ri i pe sifilian, iyẹn Abiọla, ti ki i ṣe ṣọja lo n ba ọga ologun to ti jagun Ojukwu, to si ti lokiki nibẹ fa wahala gidi. Lo ba beere lọwọ Abiọla pe ṣe o mọ ẹni to n ba binu yii ṣa, Abiọla naa si ni ko beere lọwọ Muritala naa pe ṣe o mọ iru ẹni toun naa n ṣe.

Lọrọ kan, Hasssan Katsina, lo ba awọn mejeeji yanju ọrọ naa, to si sọ fun Muritala ati Alaaji Gobir ti i ṣe akọwe agba nibẹ pe ki wọn san owo Abiọla fun un. Bẹẹ ni Muritala mu Abiọla wọ ọfiisi rẹ lọ, wọn si jokoo, ibẹ naa lo si wa titi ti wọn fi yanju owo naa, ti wọn si kọ ṣẹẹki fun Abiọla. Lọjọ naa si ni Muritala ati Abiọla di ọrẹ ara wọn, lọdun 1969 ni. Ṣugbọn ni gbogbo igba ti Abiọla n gba ṣẹẹki yii, nnkan mi-in ti n ṣẹlẹ ni ọfiisi tiwọn, iyẹn ọfiisi ITT. Ṣe bi ọrọ naa ti n lọ lo n fi to wọn leti nibẹ, to si n sọ ohun to n lọ laarin oun ati awọn sọja naa fun wọn, nitori wọn ni irinṣẹ kan ti wọn le fi maa gbohun ara wọn nibi ti wọn ba wa. Bi ọga agba, iyẹn Manejin Darẹkitọ ti gbọ lẹnu Abiọla pe o ṣee ṣe ki oun gba owo naa jade nibẹ, niṣe lo bẹrẹ ariya rẹpẹtẹ, to si ko kinni naa ran awọn oṣiṣẹ to ku.

Nigba ti Abiọla yoo fi pada de, ati ọga ati ọmọọṣẹ ti ba faji jinna, faaji naa si le debii pe ọga pata yii, Manejin Darẹkitọ, ti mu ọti yo binaku. Bi Abiọla ti ri i bẹẹ, ko duro ti wọn, bẹẹ ni ko si sọ ohun to fẹẹ ṣe, bẹẹ ni ko si fi ṣẹẹki ọwọ rẹ silẹ fẹnikan, kaka bẹẹ, o mu un, o di London, lọdọ awọn ọga pata, awọn ọga ti wọn ṣẹṣẹ lọ. O ni oun ti gba ṣẹẹki wọn fun wọn, ṣugbọn oun ko ni i fun wọn ni ṣẹẹki naa afi ti wọn ba sọ oun di ọga agba ni ileeṣẹ naa, iyẹn Manejin Darẹkitọ, bakan naa ni wọn yoo tun sọ oun di darẹkitọ ni ileeṣẹ ITT ti Naijiria, to jẹ awọn yoo jọ ni ileeṣẹ naa ni. Awọn oyinbo to lọọ ba gbọ ọrọ naa, ṣugbọn inu wọn ti dun tayọ ati maa wadii ọrọ kiri. Wọn ni to ba jẹ ti ko di ọga agba, Manejin-Darẹkitọ ni, wọn ni iyẹn ko le rara. Loju ẹsẹ nibẹ naa ni wọn si ti pe oyinbo to wa nipo naa to muti yo l’Ekoo, wọn ni ko maa bọ nile.

Ṣugbọn wọn ni bo ba jẹ ti pe ki oun naa di darẹkitọ fun ileeṣẹ naa ni, apa awọn ko ka iyẹn bayii, awọn gbọdọ jọ jokoo pẹlu awọn ọga pata ti wọn wa ni Amẹrika ati kari aye, ki wọn too le fọwọ si i pe ki oun Abiọla di darẹkitọ wọn. Ṣe owo ti Abiọla gba yii, kọmiṣan, iyẹn owo ọya ti wọn yoo fun un ninu rẹ to lati ṣe nnkan rere, owo naa si n gbe Abiọla funra rẹ ninu, ko si si ohun to fẹẹ fi owo naa ṣe ju ko fi ra ipo darẹkitọ, ki oun naa jẹ ẹni ti wọn yoo jọ ni ileeṣẹ ITT ni Naijiria lọ. Wọn ni ko fun awọn ni oṣu mẹfa, lẹyin oṣu mẹfa, awọn yoo ti yanju ọrọ ẹ, awọn yoo si fun un lohun to n fẹ. Bẹẹ ni Abiọla pada sile, lọjọ naa gan ni wọn si kede orukọ MKO Abiọla gẹgẹ bii Manejin Darẹkitọ tuntun fun ileeṣẹ ITT, ọmọ ọdun mejilelọgbọn pere ni.

Bo ti di Manejin Darẹkitọ yii, bẹẹ ni iṣẹ nla nla bẹrẹ si i wọle fun ileeṣẹ ITT, nitori Abiọla ti di ọrẹ awọn ọga ṣọja gbogbo, agaga Muritala to wa nidii iṣẹ tẹlifoonu, ọrẹ wọn naa si ti di ko-ri-ko-sun, ko si sọjọ kan ki wọn ma gbohun ara wọn. Nigba to ku diẹ ki oṣu mẹfa ti awọn oyinbo yii da fun Abiọla pe, ti oun naa si gbọ pe wọn ti n sọ ọ laarin ara wọn pe awọn ko le fi oun ṣe darẹkitọ, nigba ti awọn ko ṣe iru rẹ fun ẹnikan ri, Abiọla lọọ da ileeṣẹ tirẹ silẹ, iyẹn Radio Communication of Nigeria, RCN, o ni bi wọn ko ba ti foun ni ohun ti oun n fẹ, oun yoo kọwe fi iṣẹ naa silẹ fun wọn ni. Awọn ti wọn ni ITT ko tete mọ, nigba ti oṣu mẹfa si pe ti Abiọla ko gbọ kinni kan lati ọdọ wọn, o lọ si London, o si kọwe fun wọn, o fi oṣu mẹta silẹ pe ti oṣu mẹta naa ba pe o, oun n lọ ni toun niyẹn. Ẹnu ya awọn oyinbo yii gan-an.

Sibẹ naa, wọn ni ṣakara ni, Abiọla ko le lọ, ko sẹni ti yoo fi iṣẹ olowo nla bẹẹ yẹn silẹ ti yoo maa rin kiri. Ki oṣu mẹta naa too pe ṣaa, Abiọla ti ba ọrẹ rẹ, Muritala, sọrọ, wọn si gbe iṣẹ olowo nla onimiliọnu mẹta ataabọ mi-in, iyẹn iye owo iṣẹ to ba wọn gba lọdọ awọn oyinbo gan-an foun naa, wọn ni ko tete ṣe e ko tun waa gba omi-in si i. Ọlọrun lo waa mọ ẹni to lọọ sọ fun wọn ni ITT, kaka ki wọn si pe owo naa ni miliọnu mẹta, wọn ni miliọnu ọgbọn owo Pọn-un ni. Ara awọn oyinbo yii bu maṣọ, ni wọn ba sare pe Abiọla lọjọ to ku ọla ki oṣu mẹta to fi silẹ pe, ni wọn ba ni awọn ti gba, darẹkitọ ni, awọn yoo fun un ni iko mọkandinlaaadọta ninu ọgọrun-un (49%), awọn yoo si fọwọ mu iko mọkanlelaaadọta (51%) ni tawọn. Lọjọ naa ni Abiọla di ọkan ninu awọn darẹkitọ fun ileeṣẹ ITT agbaye, bii ẹni pe oun lo si ni ti Naijiria yii ni.

Nigba naa ni owo bẹrẹ si i ya de, nitori ileeṣẹ nla meji naa lo wa ti wọn n ri si awọn ohun eelo ogun yii ati Telephone ni Naijiria, ITT ati RCN ni, Abiọla lo ni mejeeji. Bi wọn ti n ta awọn ohun eelo ogun fun ijọba, bẹẹ ni wọn n bẹrẹ eto tẹlifoonu olowo nla ti yoo kari gbogbo Naijiria, iṣẹ naa si pọ debii pe ko si bi wọn yoo ṣe pari rẹ laarin ọdun mẹwaa, ki wọn maa ṣe e, ki wọn maa tun un ṣe ni nitori gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria ni wọn fẹẹ sọ tẹlifoonu si, Muritala to jẹ ọrẹ Abiọla timọ lo si wa nidii ohun gbogbo. Inu awọn oyinbo paapaa dun, nitori wọn mọ pe ko si bi awọn ṣe le da ṣe ileeṣẹ naa ti yoo mu iru owo ti wọn n ri yii wa, wọn ni ọpẹlọpẹ Abiọla lara awọn ni. Nigba naa ni okiki Abiọla kan lati ilẹ Naijiria kari gbogbo aye, nitori ko si orilẹ-ede kan ti ki i de, ko si si ibi ti wọn ko ti mọ ọn gẹgẹ bii ọga ITT ni Naijiria.

Amọ ileeṣẹ ITT yii ko fi bẹẹ ni orukọ daadaa. Lati Amẹrika titi de awọn ilẹ Europe, orukọ ileeṣẹ ITI maa n dẹruba awọn eeyan ni. Idi si ni pe wọn ni ileeṣẹ naa maa n gbabọde fun awọn orilẹ-ede ti wọn ba wa, iyẹn ni pe wọn maa n tu aṣiri orilẹ-ede wọn fun ijọba Amẹrika, nitori ijọba Amẹrika ni wọn n ba ṣiṣẹ to pọ julọ. Awọn naa tilẹ sọ pe awọn ti wọn ba jẹ olori ileeṣẹ naa, iyẹn awọn ti wọn ba ti dagba ninu iṣẹ naa bii Abiọla yii, wọn maa n wa ninu awo Amẹrika, iyẹn ni pe wọn maa n ba ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ wọn ti wọn n pe ni CIA ṣiṣẹ, to jẹ ko si ibi ti wọn le wa lagbaaye ti wọn ko ni i maa ṣofofo ohun to ba n lọ nibẹ fun wọn ni Amẹrika, ọpọ awọn orilẹ-ede ni wọn si ti ran Amẹrika lọwọ lati le ijọba ibẹ lọ. Ṣugbọn ọrẹ Abiọla ati ti Muritala ti kọja iyẹn, ko si sẹni to ronu nipa pe Abiọla yoo gbabọde fun Naijiria.

Nitori ITT yii ni ọrọ ṣe di wahala ni 1978 nibi ipade apero ti wọn n ṣe fun ofin oṣelu alagbada ti yoo bẹrẹ ni Naijiria ni 1979, nibẹ ni ẹru Abiọla ati ITT ti mu awọn ti wọn jọ n ṣe apero naa, ọrọ naa si ko girigiri ba ijọba Oluṣẹgun Ọbasanjọ.

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

 

 

 

(102)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.