Niṣe lokiki Bọọda Lai tubọ n kan si i

Spread the love

Meji naa ni okiki, bi ko kan si daadaa, yoo kan si aburu. Lori ọrọ Atiku to wa nilẹ yii, niṣe ni okiki Lai n kan si i. Boya ni minista eto iroyin fun aarẹ, Alaaji Lai Muhammed, mọ pe okiki oun ko kan si daadaa laarin awọn ọmọ Naijiria, ohun ti ọkunrin naa yoo si maa ṣe, tabi ti yoo sọ fawọn eeyan nigba to ba fi ipo to wa yii silẹ, gbogbo aye ni yoo fẹẹ gbọ ọ. Ọkunrin naa ko mọ iru irọ kan la ki i pa, bẹẹ ni ko ni itiju lati pa irọ, yoo ju kinni naa lulẹ bii iso buruku ni. Ohun ti yoo sọ pe o de ti oun fi n pa iru irọ bẹẹ lẹnikan ko mọ, ṣugbọn o daju pe oun paapaa ti n gbẹ koto abuku yi ara rẹ ka, nigba to ba si gbejọba yii silẹ ni yoo ri i bi Yoruba ti n fi abuku kan awọn ti ko ba ni iwa ọmọluabi lara. Bi awọn eeyan yii ba ti dana aburu kan tan, ti wọn ba ti ṣe ohun ti ko dara tan, tabi ti wọn ba n mura lati pa irọ buruku kan fawọn araalu, Lai Muhammed ni wọn yoo lọọ wọ jade, oun ni wọn yoo fa sita ti yoo maa ba awọn oniroyin sọrọ, irọ buruku ni yoo si maa pa fun wọn, awọn irọ ti ko ni ibẹru Ọlọrun ninu. Lai Muhammed ni awọn ni ojulowo ẹri lọwọ to fihan pe Atiku ati awọn PDP fẹẹ fipa gbajọba lọwọ awọn, pe wọn fẹẹ da ijọba yii ru mọ awọn lori. Iru ijọba omugọ wo lo n sọ iru ọrọ bẹẹ jade! iru minista iroyin wo ni yoo maa sọ iru ọrọ bẹẹ. Ni gbogbo orilẹ-ede aye, ẹṣẹ pataki ni lati mura lati doju ijọba bolẹ, bo ba si jẹ laarin awọn ologun ni, iku ni ijiya ẹṣẹ bẹẹ. Bi ki i ṣe laarin awọn ologun paapaa, to jẹ laarin awọn oloṣelu bayii, ẹwọn gbere ni wọn yoo sọ iru ẹni bẹẹ si. Idi ni pe nigba ti ijọba ba daru, ki i yaa tun ṣe mọ, ọpọlọpọ nnkan ni yoo bajẹ pẹlu rẹ. Ifipagbajọba ki i ṣe eṣu kekere, nigba ti atubọtan iwa bẹẹ le da gbogbo orilẹ-ede kan ru. Bi ẹni kan ba fipa gbajọba ni Naijiria, ti inu awọn kan ko dun si i, eyi le di ohun ti yoo fa ogun, ti yoo si pin orilẹ-ede wa si wẹwẹ. Iyẹn lo ṣe jẹ pe ijọbo ki i mu iru ọrọ bẹẹ ni kekere, ẹnikẹni to ba fẹẹ doju ijọba bolẹ, lẹsẹkẹsẹ ni wọn ti n mu iru wọn. Ṣugbọn nitori pe irọ ni Lai n pa, ko si ẹri kankan nibi kan ti ijọba yii ni lọwọ, wọn kan n sọ gbogbo ohun ti wọn sọ nitori ẹjọ to wa ni kootu ni, ko sẹni to le lọọ mu Atiku pe o fẹẹ fibọn gbajọba, tabi ki wọn mu ẹnikẹni ninu awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n ṣe oṣelu. Ṣugbọn iru iroyin bẹẹ ki i fi ọkan araalu balẹ, paapaa nigba to ba jẹ ẹnu minista nla bii Lai Muhammed lo ti jade. Pupọ ninu awọn ọmọ Naijiria ni wọn ti mọ Lai bii opurọ, bo tilẹ jẹ pe ko ti i si ohun ti wọn le ṣe fun un. Ṣugbọn ki awọn ẹbi ati ọrẹ rẹ ba a sọrọ, nitori gbogbo ohun to n ṣe yii, ohun ti yoo lẹyin fun un lọjọ ọla ni. Bẹẹ, ọjọ ọla naa ko jinna pẹ titi mọ o, o ti sun mọle.

(23)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.