Oyinbo ara ṣinko wọ gau!

Wọn fẹsun fifi ẹyin pọn owo jade kan an. Ọwọ ajọ EFCC ti tẹ oyinbo alawọ funfun kan,wọn ni o fẹ fi ẹyin pọn owo to to miliọnu ọgọrun un o le mẹjọ naira jade lati ilu Abuja lọ si Dubai. Li Yanping lorukọ oyinbo naa, nibi to si ti n gbiyanju lati tẹ baalu leti ni wọn ti nawọ gan an.Adajọ Babatunde Quadri ti wa a ni ko ṣi maa gbatẹgun latimọle ọgba ẹwọn naa titi asiko ti yoo fi ri oniduro ti yoo gba beeli rẹ pẹlu miliọnu mẹwaa naira.Ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin lo sun igbejọ Yanping si.