Nelson balẹ sọgba ẹwọn, wọn lo lu jibiti lori ẹrọ ayelujara

Spread the love

Ajọ EFCC, iyẹn ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorileede yii, ti wọ Olugbeje Nelson Adeoye lọ si ile-ẹjọ giga ilu Eko to wa ni Ikoyi, niwaju Onidaajọ Muslim Hassan. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe awọn ayederu iwe-ẹri kan wa lọwọ rẹ, bẹẹ lo si n fi ara rẹ pe ohun ti ko jẹ, to si fi maa n lu awọn eeyan ni jibiti. Awọn ẹsun yii ni wọn lo tako abala kejilelọgbọn, ipin kin-in-ni, iwe ofin to de iwa ọdaran to ba jẹ mọ itakun agbaye (internet fraud).

Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ naa fi sita ṣe ṣalaye, wọn ni lara ẹsun ti wọn fi kan Nelson ni pe lọjọ karundinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii, ni agbegbe ile-ẹjọ giga ilu Eko, ṣe lo ni awọn iwe kan to fẹẹ fi lu jibiti, eyi ti awọn adirẹsi oriṣiiriṣii (email), ti nọmba rẹ n ba ṣiṣẹ ninu, eyi to si ti fi lu awọn eeyan ni jibiti. Adeoye loun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.

Agbẹnusọ ajọ naa niwaju adajọ, Vera Agboje, rọ kootu lati fun awọn lọjọ ki awọn le waa rojọ niwaju adajọ. Agbẹjọro olujẹjọ, Eze Njoku, bẹ adajọ lati faaye beeli silẹ fun onibaara oun.

Adajọ Muslim Hassan paṣẹ pe ki wọn ṣi lọọ fi afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn, to si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii.

 

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.