N ko ma ti i mọ ohun to fa ija nile wa laaarọ kutuktu o

Spread the love

Ọrọ to n lọ nile wa ki i ṣe kekere rara o. Ọrọ baba yin yii ni o. Bo ba jẹ nigba kan ni, bi mo ṣe rọra fibinu kuro niwaju ẹ nijọ yẹn, oun lo maa pada waa ba mi. O le jẹ oun ni mo maa ji ri nijọ keji, tabi ko waa kan ilẹkun yara mi, ko ni, ‘Suwe, mo kanra mọ ẹ lanaa, ma binu jare, aya mi. Awọn ọmọ ẹlẹran yẹn lo fẹẹ fironu ko ba mi!’ Bo ba si ti sọ bẹẹ yẹn ni yoo fọwọ pa mi lara, ọrọ naa yoo si tan sibẹ. Ṣugbọn eyi to ṣẹlẹ laarin emi pẹlu ẹ to n bu mi pe ta lo fi mi ṣe alufaisa oun yii, ko pada waa ba mi o, koda nigba ti mo tun pade ẹ laaarọ ti mo ki i, imu lo fi dahun.

Emi naa ti yaa paaki ẹ sẹgbẹẹ kan, mo pa a ti ni, n ko tilẹ ṣe bii ẹni pe mo ri i. Koda, n ko gba iwaju ọdọ wọn kọja, gbogbo omi ti mo fẹẹ lo, ati gbogbo nnkan ti mo ba fẹẹ jẹ, mo ti n gbe e bọ ni ṣọọbu mi, nitori n ko fẹ ka rira rara. Mo mọ pe ina ile ni ọmọ ehoro yoo ya gbẹyin, oju emi pẹlu rẹ yoo tun ara ri, ki wọn maa ṣe e niṣoo, Ọlọrun n ṣe tirẹ bọ lẹyin, Ọba Ọlọrun ti ki i le ni ko too ba ni. Ẹjọ ẹ ti mo ti fẹẹ lọọ ro fawọn famili paapaa, mo ti ja ara mi leekanna, nitori yoo sọ ọrọ naa di temi, o le ni mo n ro ẹjọ oun kiri.

Awọn alatẹnujẹ inu famili naa ko si ni i mọ, wọn ko ni i mọ ohun to ṣẹlẹ. Bi o ba ti fi burẹdi nla tabi igo sitaotu tan wọn, o ti pari niyẹn. Alaaji agba nikan ni ẹni ti ori wọn pe, awọn o si n fi gbogbo igba jade, igba mi-in si wa ti gbogbo awọn to ku yoo ko ẹnu bo wọn pe Iya Biọla ti gbe nnkan fun wọn jẹ ni, iyẹn ni wọn ṣe n gbeja mi. Ibi ti eeyan o ba si ti ri ẹni ti yoo gbeja rẹ, oluwarẹ ko gbọdọ ja ija ajabẹwusilẹ, nitori ẹ ni mo ṣe yaa sinmi temi jẹẹjẹ, mo ni n ko ni i ba ẹnikan sọrọ ẹ, n ko jẹ sọrọ ẹ fun famili kan bayii, bẹẹ ni n ko jẹ de sakaani wọn mọ.

Eyi to si ṣe to fimu dahun yii, yoo gba ṣenji ẹ, nitori bi o ba tun ri i ti mo ki i, ko ni iya kan baba mẹẹẹdọgbọn lo bi mi. Nigba ti mo sọ fun Sẹki, ẹrin lo n rin, o ni kanifa ni, o maa too ka loju baba oun. Mo ni ewo ni wọn n pe ni kanifa, o ni ki emi ṣa maa wo o. O ni ohun to n mu inu oun dun ni pe awa ti maa lọ siluu oyinbo ki wọn too ṣe oku ti wọn fẹẹ ṣe, pe nigba ta a ba de, a oo gburoo gbọ gbogbo bo ba ṣe lọ. Afi bo ṣe tun sọ iyẹn lọ to tun kunlẹ wẹsẹ, lo ba ni ki n jọọ, ki n ma pa baba oun ti, pe ki n ma jẹ ki Anti Sikira ba tiẹ jẹ pata. Mo ni kin ni mo waa fẹẹ ṣe.

Kin ni mo si fẹẹ ṣe loootọ. Ẹni ti a n ba sọrọ gidi to le wa bii aja, emi o si n ṣe ẹni abuku. Mo sọ fun Sẹki, mo ni aajo aṣeju lo n fa iwọ-lo-n-ṣe-mi wa. Ọwọ ti Alaaji wa yii, bi n ko ba ṣọra, wọn yoo sọ mi lẹnu. Mo ni ṣe o fẹ ki wọn pe iya ẹ lajẹẹ ni, ki wọn ni ajẹ ni mi, emi ni n ko jẹ ki baba ẹ gberi lati ọjọ yii, baba ẹ to ti fẹnu ara ẹ sọ fun mi pe oun ti rẹni to n ba oun ṣeto aye oun, itumọ ṣa ni pe emi o ba a ṣeto aye ẹ tẹlẹ, ti mo ba waa n ṣe ayọjuran ju bo ṣe yẹ lọ, wọn yoo yẹyẹ mi, emi o si n ṣe ẹni yẹyẹ, ẹni apọnle ni mi. Sẹki ni oun funra oun n lọọ ri i, mo si lo daa bẹẹ.

Oun lo ṣaa ni baba ẹ, bi yoo ba ri i ko tete lọọ ri i, boya yoo tun gbọrọ soun lẹnu. Amọ ko raaye ri i ti wahala mi-in fi tun ṣẹ yọ. Niṣe ni Sẹki sare waa ba mi ni ṣọọbu lọsan-an Alamisi, lo ni kin waa woran, Anti Sikira ti ra mọto, o ti ra mọto Jiipu. Mo ni irọ ni! O ni ootọ ni, pe o wa nibi ti wọn ti n ba a dawọọ ẹ bayii, ti Alaaji n fẹyin kẹẹ, to ni iyawo oun ṣoriire. O ni Iya wa agba loun ba ra yugọọti, nitori wọn fẹran ẹ, bii ọmọde ni wọn maa n ṣe bi wọn ba ri i, o ni iyẹn loun lọọ mu fun wọn, afi bi oun ṣe ba mọto tutun nita, oun wo o, oun ri i pe mọto tokunbọ to gbẹ nilẹ ni.

N ko le gba eti mi gbọ, mo ni ṣe ti Alaaji ni wọn waa pe e ni abi ti Sikira, lo ba ni ti Sikira ni wọn pe e o, wọn ko pe e ni ti Alaaji. Tipatipa ni mo fi duro ki ilẹ ṣu, nitori pe wọn si ti ri Sẹki ni n ko ṣe lọ bẹẹ, nitori wọn yoo ni oun lo waa sọ fun mi. Mo rọju ṣaa, igba ti mo si de ita ni mo ti ri i, wọn gbe e sẹyin mọto jiipu temi. Mọto to daa ni loootọ, o gbẹ nilẹ, Toyota ni, o si duro nilẹ daadaa, bi mo ṣe n wo o yii, ko le din ni miliọnu mẹrin. Anti Sikira ko si ṣe iṣẹ kankan, nibo ni yoo ti rowo ra mọto miliọnu mẹrin. Owo Alaaji ni!

Iyẹn ni pe ọkunrin yii n rowo to to bayii, o ma ga o! Mo ba awọn eeyan nita ti wọn ṣi n muti, ṣugbọn ọti ti wọn n mu wọ wọn lara ati ariwo ti wọn n pa ti wọn ko fi ri mi taara, nigba to si jẹ n ko ni i de ọdọ wọn ki n too ya si ẹnu sitẹẹpu temi ti mo fi maa gun oke, awọn kọọkan to ri mi, faaji ti wọn wa ko jẹ ki wọn ta si mi. Emi naa yaa goke lọ, mo tun ara mi ṣe, mo fẹyin le bẹẹdi, mo sun lọ pata. Bi mo ti n ki asubaa tan ni mo bẹrẹ si i gbọ ariwo buruku yii, ohun Iya Dele ti mo si n gbọ lo mu mi lara. Mo n gbọ to n ya fun Alaaji buruku buruku, to n pe e loriṣiiriṣii orukọ.

O ni aye ẹ n bajẹ o n woran,  o ro pe oriire loun n ṣe, ko mọ pe ori buruku ni, pe ti ko ba rẹni ba a sọrọ, oun aa sọ ọ fun un. Mo ti kọ fẹẹ jade, ṣugbọn ki wọn ma sọ pe a jọ mọ nipa ẹ ni, nigba  to si jẹ Ọlọrun ri i pe mi o mọ kinni kan nipa ẹ, n ko jade, mo pa gbogbo ina ile, mo ka kọtinni soke, mo n woran lati oju windo, ibi ti mo ti n woran ni Abbey, Iyawo Dele, naa ti rọra rin wa, to duro ti mi lẹgbẹẹ windo nibẹ, eke buruku! Lẹẹkan naa ni mo ri i ti Iya Dele bu towẹẹli Alaaji so, o bu u mọ ọwọ isalẹ nibi ti baba ko ti raaye janpata!

Ẹẹkan naa ni Anti Sikira fo jade, lo ba fi ariwo bọnu, ‘Ṣe o fẹẹ pa a ni, ṣe o fẹẹ pa a ni!’ Ko si wẹwu o, niṣe lo roṣọ maya. N ko mọ ohun to n bi Iya Dele ninu to bẹẹ, o si jọ pe ibinu yẹn lo fun un ni agbara buruku, nitori ẹru ti n ba emi pe Anti Sikira tun maa lu u. Ṣe ẹ ri i nigba to sọ Alaaji silẹ to rọọṣi obinrin yii, o si gbe e tan nilẹ pata, niṣe ni gbogbo aṣọ tu, ti idi danu silẹ, lọkọ iyawo ba n pariwo: ‘Ma ma sọ ọ mọlẹ! Ma ṣe bẹẹ yẹn sọ ọ mọlẹ! O o ma daran!’ Kin ni wọn o sọ mọle, mo gbọ gbaaa! Loun naa ba pariwo, ‘O pa mi o!’

Nigba ti Alaaji yoo fi raaye gba iyawo ẹ, awọn tenanti ti jade, awọn ọmọ Ibo! Anti Sikira ni ko si wọ pata ti ko wọ buresia yii, ni gbogbo ẹ ba ri rọpọtọ nilẹ. Iya Dele dide, o tun mu aṣọ ẹ dani, nigba ti iyawo Alaaji si raaye dide, niṣe lo n sa wọ inu palọ lọ! Kẹ ẹ waa wo bawọn ọmọ Ibo ṣe n wodi mọmi! Igba yẹn lemi naa too waa ri akọyinsi ẹ daadaa! Ki l’Alaaji ri lara obinrin yii to n pa a bii ọti bayii! Gbogbo idi naa lo ri gbagungbagun yii! Ọlọrun, idi Anti Sikira rọọfu! O ma ṣe o!   

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.