Mutairu rọjo ẹṣẹ s’ọlọpaa lori, o tun ti si kọta l’Abẹokuta

Spread the love

Ana ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, ni wọn foju ọmọkunrin abẹṣẹ bii ku ojo kan, Mutairu Ajayi, han ni kootu majisireeti to wa n’Iṣabọ, niluu Abẹokuta. Ohun to jẹjọ le lori ni awọn ẹṣẹ aramanda to da bo ọlọpaa kan lori loṣu to kọja, to fi jẹ pe Ọlọrun lo ko ọlọpaa ti wọn pe ni Awojọbi Mutiu naa yọ lọwọ iku ojiji.

Agbefọba Ọlakunle Ibrahim lo ṣalaye fun kootu lasiko igbẹjọ naa pe lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa, nikorita Oluwo, niluu Abẹokuta, ọrọ ṣe bii ọrọ laarin Mutiu, ọmọ ogun ọdun ati ọlọpaa naa nibi tiyẹn ti n ṣiṣẹ ọba lọwọ.

Ṣugbọn bi wọn ti da Mutairu lẹkun to, ko gba sawọn eeyan to n pari ija naa lẹnu, kaka bẹẹ, ẹṣẹ buruku lo bẹrẹ si i rọjo sori ọlọpaa naa. O gba a lẹṣẹẹ naa ti ko ṣee ka, o si tun ti i si gọta to wa nitosi pẹlu aṣọ ijọba tiyẹn wọ sọrun.

Nigba to si ti han pe egungun ọdọ naa ju ti ọlọpaa to n lu lọ, ko sohun ti Awojọbi to ti bọ si gọta tun le ṣe, Ọlọrun ni ko si jẹ ko daku sori lilu ọhun paapaa bi a ṣe gbọ.

Eyi lọlọpaa naa ko ṣe le ṣe ohunkohun ju pe o lọọ fọrọ naa to teṣan leti nigba to bọ lọwọ Mutairu tan, wọn si lọọ gbe afurasi naa, o si wa lahaamọ latigba naa ki wọn too foju rẹ ba kootu lanaa ode yii.

Iwa yii ni agbefọba Shọnibarẹ sọ pe o lodi si abala irinwo din mẹrin, ẹka keji ofin iwa ọdaran ti wọn gbe kalẹ lọdun 2006, nipinlẹ Ogun.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Mutairu loun ko jẹbi iwa toun hu naa. Adajọ V.B Williams to gbọ ẹjọ yii faaye beeli silẹ fun un pẹlu egbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira (100,000) pẹlu oniduuro meji niye kan naa.

Awọn oniduuro naa gbọdọ ni ile tabi ilẹ l’Abẹokuta, wọn gbọdọ le fi iwe ẹri owo-ori sisan fọdun mẹta han kootu, ki ọkan ninu wọn si jẹ baalẹ tabi oloye pataki laarin ilu.

Gbogbo eelo beeli yii ni Mutairu ko ri, ko sẹnikan to duro fun un. Iyẹn ni wọn ṣe gbe e lọ sọgba ẹwọn Ibara ti adajọ paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ bi ko ba ti ri eto naa ṣe.

(21)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.