Musibau fipa ba ọmọ ọdun mọkanla lo pọ n’Ilaro

Spread the love

Baale ile ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Musibau Asindẹ lọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti to bayii ti wọn si ti taari ẹ si ẹka to n ri si ifipanilopọ nipinlẹ naa. Ohun ti wọn mu un fun ni pe o fipa ba ọmọ obinrin ti ko ju ọdun mọkanla lo pọ ninu oṣu kẹfa ọdun yii.

Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi lo fi iṣẹlẹ naa to ALAROYE leti. O ni iya ọmọ ti wọn forukọ bo laṣiiri naa lo fi to awọn leti pe lọjọ karun-un, oṣu kẹfa ọdun yii loun ran ọmọ oun niṣẹ ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ. Iyẹn lagbegbe Ibeṣe, n’Ilaro, ṣugbọn nigba to yẹ ko de lati ibi toun ran an naa, ọmọ oun ko de, niṣe lo pẹ gidi ko too wọle de.

Mama naa ti wọn pe orukọ ẹ ni Riskat Idowu, sọ fun awọn ọlọpaa pe bọmọ oun ti de lo sunkun wọle ti ko si gbadun ara rẹ, bẹẹ lo sọ foun pe Musibau lo tan oun wọle pẹlu ọgọrun kan naira to ni oun yoo foun, bo ṣe fipa ba oun laṣepọ niyẹn.

Teṣan ọlọpaa Ilaro gan-an ni Risikat ti fẹsun ọhun to wọn leti,ti CSP Ọpẹbiyi Sunday atawọn eeyan ẹ fi lọọ mu Asindẹ.

Nigba to n ṣalaye ara ẹ fawọn ọlọpaa, ọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun fipa ba ọmọbinrin naa sun lẹyin toun fi ọndirẹdi naira tan an wọle oun tan, o ni ṣugbọn eṣu lo fa a toun ko fi le mu ara duro bẹẹ, ki i ṣe ẹjọ oun rara.

Ileewosan jẹnẹra to wa n’Ilaro ni wọn mu ọmọbinrin naa lọ fun itọju, nigba ti Ahmed Iliyasu to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti paṣẹ pe ki wọn mu afurasi naa lọ si ẹka to n ri si ifipanilopọ ati ṣiṣe ọmọde niṣekuṣe.

Bakan naa lo gba awọn obi nimọran pe ki wọn ye e ran awọn ọmọ wọn obinrin niṣẹ alẹ, nitori awọn ikooko ti wọn daṣọ eeyan bora bii Musiliu yii pọ niluu, afi kawọn abiyamọ daabo bo awọn ọmọ wọn funra wọn.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.