Muhammadu Buhari atawọn Fulani onimaaluu rẹ

Spread the love

“Irọ lẹ n pa. Gbogbo awọn Fulani ti wọn pọ ti wọn n gbe kaakiri ilẹ Yoruba lati igba to ti pẹ ni Gaa wọn gbogbo, ṣebi awọn Yoruba lo fun wọn nilẹ wọnyi, a ko si gbọ pe wọn fi tipa gba ilẹ ẹni kọọkan. Nitori ikoriira ti ẹ ni si Buhari ati awọn Fulani lẹ ṣe n sọ itan ibajẹ bayii. Ṣe ti Buhari ba lọ, ṣe ipaniyan yoo dopin ni Naijiria ni? Kaka ki ẹ sọ ọrọ si ibi ti ọrọ wa pe Naijiria ti ko si igbekun awọn adunkooko-mọ-ni (terrorist) oṣelu ni ẹ n ṣe pẹlu ẹmi awọn eeyan. Kọla, ABK.”

Mo fẹẹ fun yin ni nọmba ọkunrin yii, ṣugbọn n ko fẹ ki ẹ bu u tabi sọrọ buruku kan si i. Mo fẹ ki ẹ ṣalaye ọrọ fun un ko ye e ni. A ko gbọdọ sọrọ buruku si ara wa mọ nibi ti ọrọ de yii, ka maa ṣalaye awọn ohun ti ko ba ye wa funra wa ni. Ọrọ daadaa ni ọrẹ mi yii sọ, ohun to fi ba a jẹ ni pe o pe agbalagba lopurọ. A ki i sọ bẹẹ s’agba. 08039180620.

Mo sọ pe ọrọ daadaa lo sọ. Akọkọ ni pe o ni awọn Fulani ti wa ni Gaa nilẹ Yoruba tipẹ, tawọn Yoruba fun wọn nilẹ, ti wọn ko si gba ilẹ naa lọwọ wọn, ẹẹkeji ni pe o le jẹ awọn adunkooko-mọ-ni (terrorist), lo wọle tọ Naijiria wa, ẹẹkẹta si ni pe ṣe ti Buhari ba lọ loni-in, ṣe ipaniyan yoo dopin ni Naijiria ni. Ni ti pe awọn Fulani ti wa nilẹ Yoruba tipẹ, ni Gaa, ododo ọrọ gbaa ni. O fẹrẹ ma si ilu kan ti awọn Fulani ko si ti wọn ti n sin maaluu ni Gaa nilẹ Yoruba yii, awọn ni wọn si n ṣe wara fun wa ni kekere. Ṣugbọn Fulani le gbe ni ọdọ rẹ fun ọgọrun-un ọdun, bi ko ba ti si agbara ti yoo fi ba ọ ja lọwọ rẹ, tabi ti yoo fi gba ohun to o ni. Lọjọ kan ti agbara ba de ọwọ ẹ, lọjọ naa ni wa a ri iyatọ ẹni to ti n ba ọ gbe lati ọjọ yii wa. Bi awọn Fulani ti n gbe niyẹn nilẹ Yoruba lati bii 1700, ki ija too de n’Ilọrin, ni 1824, ti wọn ko ara wọn jọ, ti wọn si gba ilu naa titi doni.

Mo ti sọ pe ki i ṣe pe Fulani ni agbara kankan ti wọn fi n ja, koda, wọn ya ojo ju Yoruba ti a n pe ara wa ni ojo lọ, ṣugbọn nigba ti wọn ba ti ri atilẹyin, tabi agbara lati ọdọ ẹni ti agbara wa lọwọ rẹ, ika kan ko ni i wọ wọn nidii mọ, ẹ oo si maa ro pe agbara wọn ju bẹẹ lọ ni. Kọla sọ pe awọn Yoruba ni wọn fun wọn ni ilẹ ti wọn n lo bii Gaa; bo ti ri niyẹn. Ohun ti gbogbo aye si n sọ pe ki Buhari ṣe niyẹn, ko fi aaye silẹ, Fulani to ba fẹẹ sin maaluu ni ilu oniluu, ko lọ si ọdọ awọn ti wọn ba ni ilu, ko tọrọ ilẹ lọdọ wọn, tabi ko ra a, nitori iṣẹ to fẹẹ fi i ṣe, iṣẹ okoowo ti ara rẹ ni, ki i ṣe iṣẹ ilu tabi ti ijọba. Ṣugbọn ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu lawọn ko fẹ iyẹn, wọn ni ki ijọba Naijiria gba ilẹ fawọn nikan ni Naijiria fi le ni isinmi. Buhari naa si fẹẹ ṣe bẹẹ, oriṣiiriṣii ofin ati ọgbọn buruku ni wọn n da lati ri i pe awọn gba ilẹ onilẹ fun wọn.

Iṣoro to wa nidii iru eto bayii ni pe to ba di lọjọ iwaju, ko sẹni ti yoo le gba ilẹ naa pada lọwọ awọn Fulani yii, bẹẹ ni wọn ko si ni i jẹ ki awọn ọmọ oniluu da oko tabi ṣe ohunkohun nitosi ilẹ ti wọn ba gba, wọn aa sọ fun yin pe ijọba lo fawọn nilẹ, ki i ṣe baalẹ, tabi ọba yin. Ko si ọba tabi baalẹ iru ilu bẹẹ ti wọn aa gbọrọ si lẹnu, bi wahala kan ba si de, ẹyin wọn lawọn ọlọpaa yoo wa, nitori wọn lawọn eeyan nile ijọba. Lọjọ wo ni iru nnkan bẹẹ ko ni i pada dija. Bi Fulani ba fẹẹ sin maaluu, to fẹẹ ṣe iṣẹ rẹ ni ilu kan, ko lọ sibẹ, ko tọrọ ilẹ lọwọ awọn to ni in. Awọn yii yoo fun un ni ofin ilu wọn, abẹ wọn ni yoo wa, lọjọ to ba si ṣe ohun ti ko dara, wọn yoo ni ko maa lọ. Ohun to jẹ ki awọn Fulani ti wọn wa ni Gaa gbe jẹẹ niyẹn, ti wọn ko ṣe le fa wahala pẹlu awọn oniluu, nigba to jẹ ori ilẹ ti wọn wa, ọba tabi baalẹ lo fun wọn.

O da mi loju pe ọrẹ mi Kọla to kọwe yii yoo ni iṣẹ to n ṣe to fi n jẹun, njẹ oun waa le lọ si ilẹ Hausa bayii, ko deede bọ sori ilẹ onilẹ, ko ni oun yoo maa lo o, ti awọn yẹn ko ba si fun un laaye, ko bẹrẹ ija pẹlu wọn, ko ni nitori pe Ọbasanjọ, tabi ọmọ Yoruba mi-in, lo n ṣejọba. Ki Ọbasanjọ, tabi Yoruba mi-in yii naa waa ni afi dandan ki oun gba ilẹ fun Kọla, nitori ko ma baa pa awọn eeyan ti wọn ni ilẹ wọn mọ, ko si le maa ṣiṣẹ ẹ. Ohun ti ijọba Buhari fẹẹ ṣe niyẹn. Fulani mọ pe alatilẹyin awọn ni Buhari, nitori ọkan ninu awọn Baba-isalẹ ẹgbẹ wọn ni ko too di aarẹ Naijiria rara. Mo ti sọ ọ nibi yii lẹẹkan pe ni 2001, Buhari lo ṣaaju Buba Marwa ati awọn mi-in lorukọ ẹgbẹ awọn Fulani onimaaluu, ti wọn waa ba Lam Adeṣina ni ile ijọba ni Ibadan, ti wọn ni awọn ko fẹ bi wọn ṣe n pa awọn Fulani onimaaluu l’Oke-Ogun.

Bẹẹ awọn Fulani yii lọọ purọ fun wọn ni o, awọn gan-an lo n pa awọn oloko lẹyin ti wọn ba fi maaluu jẹ oko wọn, ti wọn n fi ipa ba awọn iyawo oniyawo sun, atawọn ọmọbinrin lọna oko. Olori SSS to jẹ Hausa, ati ọga awọn ọlọpaa ti oun naa jẹ Hausa lo ṣẹṣẹ ṣalaye ọrọ fun Buhari. Sibẹ, ko tẹ ẹ lọrun, nitori ko duro jẹ ounjẹ ti Lam se kalẹ fun un gẹgẹ bii olori Naijiria atijọ. Bi olori orilẹ-ede ba fa ara rẹ silẹ de iru ipo bẹẹ yẹn nigba ti ko si agbara lọwọ rẹ, bi agbara ba waa de ọwọ ẹ, kin ni o le ṣe. Ija ti Buhari ba ijọba Ọbasanjọ ja nitori ọrọ Sharia lo n lọ yii, to ni gbogbo agbara, ati ipo, lawọn yoo fi ja titi ti Sharia yoo fi di ohun ti gbogbo Naijiria yoo maa lo, koda, ko di ohun ti ẹmi awọn yoo ba lọ. Awọn ọrọ yii ki i ṣe ahesọ, ẹni ba tẹ ‘Buhari and Lam Adesina’, to tun tẹ ‘Buhari and Sharia’ sori Google, yoo ri gbogbo eyi ka daadaa.

Eyi ti ọrẹ wa yii sọ pe o le jẹ awọn adunkooko-mọ-ni lo n yọ wa lẹnu, iyẹn awọn afẹmiṣofo, ọrọ naa ki i ṣe bẹẹ. Bawo ni mo ṣe mọ? Bo ba jẹ bẹẹ ni, Buhari funra rẹ yoo ti sọ ọ. Ṣebi gbogbo aye lo ti pariwo pe ki Buhari pe awọn apaayan yii ni terrorist, afẹmiṣofo, ko sọ wọn lorukọ ti gbogbo aye yoo fi le gbeja wa, ṣugbọn ko dahun, titi di ọla. Ohun ti Buhari n sọ ni pe ija awọn onimaaluu atawọn agbẹ lo n ṣẹlẹ ni Benue-Plateau. Bi Buhari ba sọ bẹẹ, to si jẹ oun lolori ijọba, ta ni yoo waa sọ pe bẹẹ kọ lọrọ ri. Buhari ni ki i ṣe awọn terrorist lo n yọ wa lẹnu. Ẹni to ba waa ka awọn iwe itan, to ba mọ igba ti ọrọ ija ti wa laarin awọn Fulani atawọn ara Benue-Plateau, to ba beere itan lọwọ awọn bii Alao Akala, ohun to ri nigba to n ṣe gomina ti ija ṣẹlẹ ni Jos, yoo mọ pe ọrọ naa ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.

Gbogbo awọn ọga ṣọja ilẹ yii ni wọn mọ. Ṣebi ohun to ṣe iku pa Muritala ni 1976 niyẹn. Ẹni to ba ka itan bi wọn ṣe pa Muritala yoo mọ pe awọn ara Benue-Plateau lawọn ṣọja to pa a, lati ori Bisalla, titi de ori Dimka, titi dori Gomwalk, ati gbogbo awọn ti wọn ditẹ naa pata, ọmọ adugbo naa ni wọn n ṣe. Ohun ti ko si jẹ ki Danjuma le ṣe olori ijọba naa nigba ti Ẹgbọn Ṣẹgun loun ko ṣe niyẹn, nitori ibẹru pe wọn yoo sọ pe awọn ọmọ Benue-Plateau ni wọn fibọn gbajọba ki Danjuma toun naa wa lati ibẹ le di olori Naijiria. Awọn Gideon Orka ti wọn fẹẹ fibọn pa Babangida mọle ni 1990, to jẹ bi wọn ti ro pe awọn ti gbajọba ni wọn ti ni awọn pin Naijiria si meji, kawọn ara Sokoto maa lọ pẹlu awọn eeyan wọn, ki awọn ara South, lati Benue titi de ilẹ Yoruba ati Ibo maa ṣe tiwọn naa, ṣebi ọrọ ija yii naa ni. Ko ṣẹṣẹ bẹrẹ rara. Buhari mọ gbogbo eleyii, ohun ti ko si ṣe da awọn ti wọn n paayan kiri yii lẹkun niyẹn. Agbara ti wa lọwọ awọn Fulani, wọn si fẹẹ lo o lati gba ilẹ awọn eeyan naa ni. Ko si tabi-ṣugbọn nibẹ, bi Buhari ko ba si nijọba, ipaniyan to n ṣẹlẹ yii yoo dinku, ti ko ba tilẹ tan rara. Ohun ti yoo jẹ ko dinku ni pe bawọn Fulani yii ba ti mọ pe awọn o ni alatilẹyin ati olugbeja bi awọn ba n paayan, wọn yoo sa wọle lọ ni, ẹ ko si ni i gburoo wọn mọ fun igba pipẹ. Ko sẹni to koriira Buhari, ṣebi gbogbo wa la ṣa dibo fun un, ṣugbọn aburu tawọn Fulani n ṣe fun Naijiria ti ko da wọn lẹkun lo fa ikoriira rẹ. Bi Kọla ba si fẹẹ gbọ ododo ọrọ, emi o ni i fẹran apaayan ati afẹmiṣofo laelae!

(20)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.