Mọto tẹ ọmọde marun pa n’Idi-Aba

Spread the love

Jẹẹjẹ wọn ni wọn jokoo niwaju ita, iyẹn awọn akẹkọọ  mẹrin lati ileewe Government Technical College, Idi-Aba, Abẹokuta, ati ọmọdebinrin kekere kan ti ki i ṣe ọmọleewe ni tiẹ, ti mọto Toyota Avensis kan si lọọ ya ba wọn nibi ti wọn jokoo si, to tẹ ori wọn fọ doju iku lalẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kin-in-ni, yii.

Alaye ti Alukoro TRACE nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, ṣe fawọn akọroyin lọjọ keji iṣẹlẹ yii ni pe alẹ, ni nnkan bii aago mọkanla ku ogun iṣẹju, ni ijamba naa ṣẹlẹ.

O ni aisun awọn musulumi ti wọn n pe ni Tahajud lawọn ọmọ naa fẹẹ ṣe ninu mọṣalaaṣi to wa nitosi ile ti wọn jokoo si. Aago mejila oru ni Tahajud naa yoo bẹrẹ, iyẹn ni wọn fi jokoo niwaju ile naa ti wọn n takurọsọ, ti wọn si n duro de aago mejila ti adua yoo bẹrẹ.

Alukoro tẹsiwaju pe nibi tawọn ọmọ naa jokoo si ni mọto ayọkẹlẹ Toyota Avensis kan ti n sare buruku bọ, aṣe o ti padanu ijanu ẹ, ni taya ba fọ, lọkọ ọhun ba n gbokiti leralera.

Nibi to ti n gbokiti naa lo ti lọọ ba awọn ọmọde marun-un yii, bẹẹ lo si ṣe tẹ wọn lori pa, koda, awọn eeyan meji mi-in tun farapa nibẹ pẹlu.

Ohun to ba ni lọkan jẹ ju ni pe ko sẹni to ri dẹrẹba to wa mọto yii mu, niṣe lo sa lọ bo ti paayan marun-un loju-ẹsẹ. Igo ọti ni wọn ba ninu mọto ọhun kitikiti, eyi to n tọka si i pe o ṣee ṣe ki awakọ naa ti yo ko too maa wa mọto yii kiri.

Mọṣuari ileewosan Federal Medical Center, (FMC), Idi- Aba, ni wọn gbe oku awọn ọmọleewe yii ati agbalagba obinrin naa lọ, ọsibitu yii kan naa ni si awọn to farapa ti n gba itọju.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.