Mọto takiti ni Makun, eeyan mẹta lo doloogbe

Spread the love

Ijamba ọkọ to lagbara lo ṣẹlẹ lọjọ Ẹti to kọja yii, iyẹn ọjọ kọkanla, oṣu kin-in-ni, ọdun 2019. Mọto akero ti nọmba ẹ jẹ FST 578XM lo takiti lai mọye igba, to fi di pe eeyan mẹta ku, tawọn mọkanla si farapa gidi.

 

Agbegbe Makun, ni Ṣagamu, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, ni ijamba naa ti waye gẹgẹ bi ọga ẹka FRSC nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Clement Ọladele, ṣe ṣalaye f’ALAROYE.

 

O ni ere ti dẹrẹba ọkọ naa n sa lo pọ ju, lori ere ọhun ni taya bẹ si, lo ba di pe dẹrẹba padanu ijanu ọkọ, lọkọ ba bẹrẹ si i gbokiti ni marosẹ, ohun to si tẹyin rẹ yọ naa ni iku ọkunrin kan ati obinrin meji ninu mọto yii, ati ifarapa awọn eeyan mọkanla mi-in.

 

Ọkunrin mẹta ati obinrin mẹjọ lawọn to ṣeṣe pupọ ninu ọkọ to danu yii, ṣugbọn Ọlọrun doola ẹmi wọn. Eyi naa ni wọn ṣe ko wọn lọ sileewosan Idẹra, ni Ṣagamu, ṣugbọn mọṣuari ọsibitu Ọlabisi Ọnabanjọ ni wọn ko awọn to padanu ẹmi wọn lọ.

 

Ọga ẹka ẹṣọ alaabo FRSC yii tun rọ awọn awakọ gẹgẹ bii iṣe rẹ, pe ki wọn yee sare asapajude ni marosẹ, ki wọn maa lo taya to duro deede si mọto wọn, ki wọn si maa lo ina ti wọn nilo lati fi riran lọwọ idaji ati lalẹ, nitori awọn asiko meji yii ṣoro lati wakọ, beeyan ko ba ni iriran to duro deede.

 

 

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.