Mọto pa onibaara ni Sango

Spread the love

Ọkan ninu awọn mọla ti wọn maa n jokoo bẹẹrẹ loju ọna to lọ si Owode-Ijakọ ni Sango Ọta lo padanu ẹmi ẹ lọjo Ẹti, Furaidee, to kọja yii, nigba ti bọọsi kan padanu ijanu ẹ, to si sare wọ agbo awọn onibaara to n tọrọ owo lori ijokoo naa lọ.
Gẹgẹ bi adari ajọ FRSC ni Sango-Ọta, Ọgbẹni Adekunle Oguntoyinbo, ṣe fiṣẹlẹ naa to ALAROYE leti, o ni ni nnkan bii aago marun-un kọja ogun iṣeju nirọlẹ, ni ijamba yii waye lọjọ yii. Nigba ti ọkọ akero kan ti nọmba ẹ jẹ FST 633 XW padanu ijanu ẹ.
Oguntoyinbo ṣalaye pe Toll-gate ni mọto naa ti n bọ, Owode-Ijakọ lo si n lọ. Ṣugbọn lojiji ni apa awakọ ko ka mọto naa mọ, nigba ti ijanu ẹ daṣẹ silẹ, to si bẹrẹ si i ṣiṣẹ kiṣẹ.
O ni gbogbo igbiyanju dẹrẹba lati da ọkọ naa duro ko seso rere rara, kaka bẹẹ, niṣe ni mọto naa ja wọ aarin awọn mọla to n tọrọ owo yii, to si ṣe bẹẹ pa ọkan ninu wọn lẹsẹkẹsẹ, ti awọn mẹta mi-in si tun farapa gidi.
Igbimọ ẹgbẹ onibaara ni Sango-Ọta lo gbe oku naa lọ fun sinsin, nigba ti ikọ alaabo FRSC gbe awọn mẹta to farapa lọ sileewosan jẹnẹra to wa ni Sango-Ọta kan naa. Nibi ti ọrọ wọn si lagbara de paapaa, ẹka itọju awọn alaisan tabi ipalara to ba pọ gan-an (Intensive care unit) ni wọn ko awọn to farapa naa si lọsibitu ọhun.
Nigba to n gba awọn alagbe to ṣẹku nimọran lẹyin iṣẹlẹ yii, Ọgbẹni Oguntoyinbo rọ wọn lati dẹkun titọrọ owo loju titi, ati bi wọn ṣe maa n fi gbogbo ara jokoo, ti wọn yoo maa reti awọn oninu didun ọlọrẹ.
O ni ewu pupọ lo wa ninu keeyan maa ṣagbe loju ọna ti mọto n gba ni gbogbo igba, nitori ijamba ki i sọ fẹnikan ko too waye.
Bakan naa lo gba awọn onimọto naa nimọran pe ki wọn maa ṣamojuto to yẹ si mọto ti wọn fi n ṣiṣẹ, ki wọn yee fẹmi awọn eeyan ṣofo lai nidii.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.