Moses Simon di ogbontagiri ni France

Spread the love

Atamatase agbabọọlu ilẹ wa to n gba bọọlu lẹgbẹ agbabọọlu Nantes, ilẹ France, Moses Simon, ti di ọkan lara awọn ti wọn n figagbaga fun awọọdu agbabọọlu to ṣe daadaa ju ni kilọọbu naa loṣu to kọja.

Agbabọọlu ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun lo n figagbaga pẹlu balogun ẹgbẹ naa, Abdoulaye Toure atawọn meji mi-in, Nicolas Pallois ati Fabio.

Eyi ko ṣeyin bi Simon ṣe gba ayo ti Nantes fi na Amiens lọsẹ diẹ sẹyin wọle, iyẹn nibi ifẹsẹwọnsẹ akọkọ to ti kopa fun wọn lẹyin to kuro ni Levante, ilẹ Spain. Oun naa lo ṣeto bi kilọọbu rẹ ṣe na Montepellier pẹlu bo ṣe faaye gba ẹni to gba bọọlu sawọn.

Oni, Tusidee, ni ibo tawọn ololufẹ bọọlu n di fun awọn agbabọọlu mẹrẹẹrin lati mọ ẹni ti yoo jawe olubori yoo wa sopin, ẹni ti ibo rẹ ba si pọ ju lo yege. Ireti wa pe nnkan yoo ṣenuure fun Simon.

GBS Academy, ilu Jos, ni Simon ti kẹkọọ nipa bọọlu laarin 2003 si 2013, ko too kọja si Ajax, ilẹ Netherlands, nibi to gba de Trencin, ilẹ Slovakia, ni 2014.

Ọdun 2015 lo kọja si Gent, ilẹ Belgium, ibẹ lo si ti lọ si Levante, lọdun to kọja. Ọdun yii ni kilọọbu naa ta a fun Nantes fun saa kan pere.

Laarin ọdun 2013 si 2015 lo fi wa ni ikọ Flying Eagles ilẹ Naijiria ko too gba igbega, lara awọn agbabọọlu tawọn onimọ si gba pe yoo fakọyọ fun igba pipẹ ni Super Eagles ni.

(6)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.