Mọnsuru digunjale, ladajọ ba ni ki wọn lọọ yẹgi fun un l’Ekoo

Spread the love

Adajọ ile-ẹjọ giga to wa ni Ikẹja, niluu Eko, Raliat Adebiyi, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun ọkunrin awakọ kan, Mọnsuru Ayọọla, titi ti ẹmi yoo fi bọ lara rẹ, nitori ẹsun ole ti wọn fi kan an.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja, lo gbe idajọ naa kalẹ, nigba to ni ọkunrin naa jẹbi ẹsun jija ọga rẹ lole ti wọn fi kan an. Agbẹjọro ijọba, Abilekọ O.R Ahmed-Muili, ṣalaye fun kootu pe ọjọ kọkanla, oṣu kẹwaa, ọdun 2014, ni olujẹjọ huwa ọdaran naa ni ojule kẹrindinlogun, adugbo Yeye Ọlọfin, Lẹkki Phase 1, niluu Eko. Ibọn iṣere ọmọde ati ada lo si fi dẹruba ọkunrin naa.

O ni ṣe lo wọ iboju (mask), to si dihamọra pẹlu ada ati ibọn iṣere ọmọde, to si lọọ ja ọga rẹ, Alabi lole pọọsi rẹ ti ẹgbẹrun lọna aadọta Naira wa ninu rẹ, pẹlu foonu Nokia ati HTC rẹ.

Bakan naa lo tun ji ẹgbẹrun lọna mejdinlogun Naira lọwọ Ọgbẹni Oluwaṣeun Badia pẹlu foonu Nokia, to si tun gun ọkunrin naa lọbẹ lasiko to fẹẹ fẹsẹ fẹ ẹ. O ṣalaye pe awọn ọlọde adugbo naa lo mu Mọnsuru silẹ, nigba to n gbiyanju lati sa lọ.

Ayọọla, to n gbe ni ojule kẹtalelaaadọjọ, adugbo Adeniyi Adeniji, niluu Eko, ni wọn ti kọkọ wọ wa si kootu lọjọ kẹrinla, oṣu kẹta, ọdun 2016, awijare to si sọ nigba naa ni pe ọga oun toun ja lole naa jẹ oun lowo oṣu ni.

Ọmọkunrin naa loun ko jẹbi ẹsun mẹtẹẹta, iyẹn igbimọ-pọ lati huwa ọdaran, idigunjale ati dida ọgbẹ si eeyan lara ti wọn fi kan an, ṣugbọn Adajọ Raliat Adebiyi sọ pe awọn ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ naa fi han pe olujẹjọ jẹbi ẹsun idigunjale, ṣugbọn ko si ẹri to kun to lati fidi awọn ẹsun meji yooku mulẹ niwaju ile-ẹjọ.

 

Adajọ Adebiyi ni pe agbefọba naa ko mu ẹri to kun to wa si ile-ẹjọ lati fi gbe ọrọ rẹ lẹsẹ pe olujẹjọ naa da ọgbẹ si ara ọkunrin kan, Oluṣẹgun Badia, bẹẹ ni ko mu ọkunrin naa wa si kootu gẹgẹ bii ẹlẹrii lori ẹsun naa.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ijiya to wa fun idigunjale lagbara pupọ, bẹẹ ile-ẹjọ ko le sọ pe nitori ko jẹbi awọn ẹsun meji yooku, ko ni i jiya labẹ ofin.

Lọọya olujẹjọ, Amofin O Ọrẹagba-Ademọla, rọ adajọ kootu naa lati ṣaanu onibaara oun, o ni igba akọkọ ree ti yoo hu iru iwa naa. Ṣugbọn gbogbo arọwa yii ko ta leti Adajọ Adebiyi rara.

O waa paṣẹ pe ki wọn lọọ yẹgi fun Mọnsuru, gẹgẹ bi abala ọrun-din-ni irinwo-o-din-marun-un (295) ṣe ṣagbekalẹ rẹ, to si ṣadura fun un pe ki Ọlọrun ṣaanu ẹmi rẹ.

(25)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.