Mo ri aanu Olorun gba ni mo fi wa laye doni__ Bisi Akande

Spread the love

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Oloye Adebisi Akande, ti sọ pe oun ri aanu gba lọdọ Ọlọrun pẹlu bi oun ṣe wa laye titi asiko yii, nitori oun ti ro pe oun ko le ju ọmọ aadọta ọdun lọ lori eepẹ.

 

Nibi eto ayẹyẹ ọgọrin ọdun ti wọn ṣe fun baba naa niluu rẹ, Ila-Ọrangun, lo ti sọrọ yii lọsẹ to kọja. O ni nigba tun jẹ ọmọ aadọta ọdun din marun-un ni iya oun ku, ti oun si padanu baba oun nigba ti baba naa pe ọmọ aadọta ọdun, oun si ti gbagbọ pe gbedeke ti wa fun ati gbe aye toun naa.

 

Nitori idi eyi, baba ọmọ keekeekee gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe Akande sọ pe oun ṣe laalaa pupọ nibẹrẹ aye oun lati le tete gbe nnkan rere ṣe ko too di pe oun naa yoo ku, gẹgẹ bii ero ọkan oun.

 

Gẹgẹ bi Baba Akande ṣe wi, “Mo ti ro pe mi o ni i ju ọmọ aadọta ọdun lọ laye, bi mo ṣe pe ọmọ ogoji ọdun ni mo tete fẹyawo, bẹẹ ni mo si tete bẹrẹ ọmọ-bibi, mo ṣe kirakita lati le tete fi nnkan gidi silẹ fawọn ọmọ mi, ṣugbọn mo ri aanu gba loni-in, mo di ọgọrin ọdun laye”.

 

Ninu ọrọ rẹ, gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla dupẹ lọwọ Oloye Bisi Akande fun igbagbọ to ni ninu rẹ lati dari ipinlẹ Ọṣun gẹgẹ bii gomina.

 

Arẹgbẹṣọla ni Baba Akande lo pe oun lati waa dupo gomina nipinlẹ Ọṣun lasiko ti oun ko ni i lọkan lati wa si Ọṣun rara, baba yii si duro ti oun titi ti oun fi ṣaseyọri lọdun mẹjọ nipinlẹ yii.

 

O ni Akande, ẹni to jẹ adele alaga akọkọ fẹgbẹ oṣelu APC lorileede yii, lo mu ki ipinlẹ Ọṣun rọ oun lọrun lati dari nitori ipinlẹ yii lo ṣoro julọ lorileede yii lati tukọ rẹ, ọgbọn ati itọsọna Oloye Akande lo si mu oun kogo ja lai si wahala.

 

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla ṣapejuwe Oloye Adebisi Akande gẹgẹ bii oloootọ oloṣelu, ẹni to ni ẹri-rere lorileede yii, ti ko si fi abawọn yi aṣọ aala rẹ nitori ohunkohun.

 

Oyetọla ni Akande yẹ lẹni teeyan maa n kan saara si pẹlu ipa rere to ti ko ninu idagbasoke ati ifẹsẹmulẹ ijọba tiwa-n-tiwa lorileede Naijiria, ati paapaa, nipinlẹ Ọsun.

 

O ni itan ko ni i gbagbe baba naa rara, bẹẹ ni gbogbo oloṣelu to ba ni i lọkan lati ṣaṣeyọri gbọdọ ṣetan lati mu ninu omi-ọgbọn baba naa.

 

Lara awọn ti wọn pesẹ sibi ayẹyẹ naa ni iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaja Kafayat Oyetọla, Alhaja Ṣẹrifat Arẹgbẹṣọla, Ọtunba Titi Laoye Tọmọri, Minista feto ilera, Ọjọgbọn Adewọle, igbakeji Dokita Fayẹmi, Ọtunba Iyiọla Omiṣore, Ọnọrebu Ṣọla Adeyẹye atawọn oloṣelu kaakiri iha Iwọ-Oorun orileede yii.

=

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.