Mo nigbagbọ ninu eto idajọ orilẹede yii lati gba ẹtọ mi pada lọwọ APC -Ademọla Adeleke

Spread the love

Bii igba tawọn elere ori-itage ba n ṣere ni ọrọ atundi ibo gomina to waye kọja yẹn, magomago ojukoroju, lai naani awọn agbofinro lawọn ẹgbẹ oṣelu APC ṣe kaakiri ibi ti eto idibo naa ti waye.

Emi o faramọ esi idibo naa rara nitori pe ko ṣafihan ifẹ ọkan awọn araalu. Ṣe dandan ni wọn fi maa n ṣejọba ni? Awọn araalu dibo fun ẹgbẹ mi, ẹgbẹ PDP lakọọkọ, ajọ INEC lo ọgbọn ayinike, wọn yọ nnkan to din diẹ lẹgbẹrun marun-un kuro ninu ibo mi, wọn waa sọ pe nitori wahala to ṣẹlẹ lawọn ibi kan, ṣe ni ka lọọ tun ibo di nibẹ. Igba yii lawọn APC pẹlu awọn ikọ agbofinro waa rọjo wahala sori awọn ọmọ ẹgbẹ wa. Wọn na awọn eeyan lai ro ti ọjọ ori wọn, oyun bajẹ lara obinrin kan nijọba ibilẹ Guusu Ifẹ, ẹyin oniroyin naa le sọ nnkan ti oju yin ri kaakiri, ṣugbọn mo mọ pe Ọlọrun Ọba lagbara lori ohun gbogbo to da, a ṣi ni awọn ti wọn bẹru Ọlọrun lawọn ẹka eto idajọ wa lorilẹ-ede, mo nigbagbọ pe awọn APC kan sun ọjọ ominira awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun siwaju ni, imọlẹ aa tan dandan laipẹ lagbara Ọlọrun.

Ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun

Ọna eru ni ẹgbẹ PDP fẹẹ gba lati gba iṣakoso ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, ṣugbọn Ọlọrun ju wọn lọ. Ko sẹni to le lero pe ẹgbẹ naa yoo ri ipo keji gba gan-an, ṣe la ro pe aarin ẹgbẹ wa ati ẹgbẹ SDP nikan ni ire-ije naa wa tẹlẹ, a si ti maa n pariwo tipẹ pe wọn fẹẹ da ọgbọn buruku nipasẹ ẹrọ to n ṣayẹwo kaadi idibo, iyẹn card readers, eleyii lo si jẹ ki wọn ni iye ti wọn ni ninu idibo alakọọkọ. Nitori pe awọn ọlọpaa ko jẹ ki wọn raaye ra ibo tabi ki wọn maa gba kaadi idibo lọwọ awọn araalu lasiko ti atundi ibo yẹn lo ja wọn bọ, wọn kan n sunkun kiri lasan ni, Ọlọrun ti gba awa eeyan ipinlẹ Ọṣun lọwọ ikẹkun awọn pẹyẹpẹyẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Bunmi Jẹnyọ, akọwe ẹgbẹ oṣelu PDP niha Iwọ-Oorun Guusu Naijiria

Abuku nla ni ohun to ṣẹlẹ lasiko atundi ibo yẹn jẹ fun ijọba tiwa-n-tiwa nipinlẹ Ọṣun ati lorilẹ-ede yii lapapọ.

Afi bii igba ti awọn alọkolohun-kigbe ba ṣọṣẹ nibi kan, iyalẹnu lo jẹ pe awọn oṣiṣẹ alaabo lẹdi apo pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati huwa buburu yii, ṣugbọn mo mọ pe iyanjẹ yii ko le duro laelae.

Ọpọlọpọ awọn oludibo ni wọn le jade kuro ninu ile wọn nijọba ibilẹ mẹrẹẹrin ti eto atundi ibo naa ti waye. Loju awọn ọlọpaa ni tọọgi kan ti wọn pe ni Sunday Iba Akinṣọla fi n da ibudo idibo ru, yannayanna ni baba agbalagba, ẹni ọgọrin ọdun, Oloye Sẹsan Ọlanrewaju, farapa, bẹẹ ni wọn ṣe Barista Tọpẹ Eluṣọgbọn leṣe.

Ọpọlọpọ awọn ti ko lẹtọọ lati dibo ati awọn ti wọn mu kaadi idibo ti ki i ṣe ti awọn wọọdu yẹn lọwọ ni wọn gba laaye lati dibo nitori wọn ti kọkọ le awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kuro nitosi ibudo idibo.

Wọn ko jẹ ki awọn alaabojuto (Observers) ati awọn oniroyin lanfaani lati de awọn Ward 10, Unit 2, ni Ariwa Ifẹ, Ward 8, Unit 1, ni Orolu, Ward 8, Unit 4, ni Orolu, Ward 7 Unit 12, ati Ward 8, Unit 10, ni Guusu Ifẹ. Nigba ti yoo fi di aago mọkanla aarọ, fọfọ ni baagi kaadi idibo kun pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ APC ati ajọ INEC.

Awọn kọmisanna Arẹgbẹṣọla bii Lani Baderinwa, Bọla Ilọri, Rafiu Usamọtu ati Tọpẹ Adejumọ ni wọn wa ni Ariwa Ifẹ, ti wọn n le awọn ti wọn ki i baa ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC sẹyin nibudo idibo, ẹni to ba ti de fila Ọmọluabi tabi ti wọn fi ọda buluu kun ori eekanna rẹ nikan lo lanfaani lati dibo.

Nitori naa, awa ẹgbẹ oṣelu PDP niha Iwọ-Oorun Guusu orilẹ-ede yii n sọ pe awa ko faramọ esi atundi ibo yẹn, a si n pe gbogbo awọn ọlọpọlọ pipe kaakiri agbaye lati dide daabobo ijọba awa-ara-wa ti a n ṣe lorilẹ-ede yii ko too di pe awọn ẹgbẹ oṣelu APC yoo ba nnkan jẹ jinna.

Bakan naa, ọrọ esi idibo gomina gan-an gan to waye lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ninu eyi ti wọn ti bu maaki to le ni ẹgbẹrun mẹrin ataabọ, 4,740 kuro ninu ti ẹgbẹ PDP fun APC gbọdọ jẹ apero, ki wọn si da maaki wa pada ni kikun.

Bello Adegboyega Basheer APC latilu Inisa

Inu mi dun fun aṣeyọri oludije latinu ẹgbẹ wa, Alhaji Gboyega Oyetọla, o ṣafihan pe awọn araalu ṣi ri ẹgbẹ wa gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu to yatọ lorilẹ-ede yii. Iṣẹ takuntakun ni Alhaji Oyetọla ṣe lati le gbegba oroke nitori pe o nigbagbọ ninu itẹsiwaju iṣejọba rere Gomina Arẹgbẹṣọla. Ẹni to ti nimọ kikun nipa iṣejọba ipinlẹ Ọṣun ni, mo si mọ pe ju eyi ti a ti n ri latẹyinwa lọ, idagbasoke ti ko lẹgbẹ yoo tun ba ipinlẹ wa. Mo kan fẹẹ rọ gomina ti a dibo yan lati ma ṣe gbagbe gbogbo awọn ti wọn ṣe wahala pẹlu ẹ lasiko to ba de ori aleefa.

Baba Ibeji niluu Ifọn

Emi o ti i ri iru idibo yii ri latigba ti mo ti gbọnju o, lati alẹ ọjọ Wẹsidee lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ti n yale wa kaakiri pe ẹni to ba fẹran ara rẹ ninu wa gbọdọ dibo fun awọn ninu atundi ibo yẹn, koda, wọn ni ki n mu kaadi idibo

mi wa, ṣe ni mo yari fun wọn, ki i ṣe inu ile ni mo sun mọju, sibẹ, wọn ko jẹ kemi atawọn ọrẹ mi kọja si wọọdu ta a ti fẹẹ dibo, a pariwo titi, awọn ọlọpaa ko ri nnkan ṣe si i.

Aṣiwaju Grassroot Foundation

Ẹgbẹ kan ti ki i ṣe tijọba, Aṣiwaju Grassroot Foundation (AGF), ti sọ pe ti a ba n sọ nipa pe eeyan kunju oṣunwọn lati di gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Oyetọla, yẹ fun aṣeyọri to ṣe ninu idibo naa.

Gẹgẹ bi alukooro ẹgbẹ naa, Ayọbami Agboọla ṣe wi, ko si oludije mi-in tawọn eeyan le dibo fun l’Ọṣun to le mọ nipa iṣejọba, paapaa, nibi ti Arẹgbẹṣọla ba nnkan de, daadaa. O ni awọn iriri Oyetọla yoo ran ipinlẹ Ọṣun lọwọ lọpọlọpọ. Ẹgbẹ naa waa rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu rẹ.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.